Àwọn Onídàájọ́ 18:1-31

  • Àwọn ọmọ Dánì ń wá ilẹ̀ (1-31)

    • Wọ́n kó àwọn ère Míkà, wọ́n sì mú àlùfáà rẹ̀ (14-20)

    • Wọ́n gba Láíṣì, wọ́n sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Dánì (27-29)

    • Wọ́n jọ́sìn ère ní Dánì (30, 31)

18  Nígbà yẹn, kò sí ọba ní Ísírẹ́lì.+ Ní àkókò yẹn, ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì+ ń wá ilẹ̀* tí wọ́n á máa gbé, torí pé wọn ò tíì rí ogún gbà láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+  Àwọn ọmọ Dánì rán ọkùnrin márùn-ún látinú ìdílé wọn, àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti Sórà àti Éṣítáólì+ pé kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.” Nígbà tí wọ́n dé agbègbè olókè Éfúrémù, ní ilé Míkà,+ wọ́n sun ibẹ̀ mọ́jú.  Nígbà tí wọ́n dé tòsí ilé Míkà, wọ́n dá ohùn* ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ ọmọ Léfì náà mọ̀, wọ́n wá lọ bá a, wọ́n sì bi í pé: “Ta ló mú ọ wá síbí? Kí lò ń ṣe níbí? Kí ló dá ọ dúró síbí?”  Ó dá wọn lóhùn pé: “Báyìí báyìí ni Míkà ṣe fún mi, ó sì gbà mí pé kí n máa ṣe àlùfáà òun.”+  Wọ́n wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, bá wa bi Ọlọ́run bóyá ìrìn àjò wa máa yọrí sí rere.”  Àlùfáà náà sọ fún wọn pé: “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Jèhófà wà pẹ̀lú yín lẹ́nu ìrìn àjò yín.”  Àwọn ọkùnrin márùn-ún náà wá ń bá ìrìn àjò wọn lọ, wọ́n sì dé Láíṣì.+ Wọ́n rí bí àwọn tó ń gbé ibẹ̀ kò ṣe gbára lé ẹnikẹ́ni bíi ti àwọn ọmọ Sídónì. Èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni wọ́n, wọn kì í fura,+ kò sì sí aninilára kankan tó wá jẹ gàba lé wọn lórí ní ilẹ̀ náà láti yọ wọ́n lẹ́nu. Wọ́n jìnnà gan-an sí àwọn ọmọ Sídónì, wọn kò sì bá àwọn míì da nǹkan pọ̀.  Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Sórà àti Éṣítáólì,+ àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n pé: “Báwo lọ̀hún?”  Wọ́n fèsì pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ gbógun jà wọ́n, torí a ti rí i pé ilẹ̀ náà dáa gan-an. Kí ló dé tí ẹ̀ ń lọ́ra? Ẹ má fi falẹ̀, ẹ lọ gba ilẹ̀ náà. 10  Tí ẹ bá dé ibẹ̀, ẹ máa rí àwọn èèyàn tí kì í fura,+ ilẹ̀ náà sì fẹ̀. Ọlọ́run ti fi lé yín lọ́wọ́, kò sóhun tí ẹ fẹ́ láyé yìí tí ẹ ò ní rí níbẹ̀.”+ 11  Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tó dira ogun látinú ìdílé àwọn ọmọ Dánì wá gbéra láti Sórà àti Éṣítáólì.+ 12  Wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Kiriati-jéárímù+ ní Júdà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibi tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Kiriati-jéárímù yẹn ní Mahane-dánì*+ títí dòní. 13  Wọ́n kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè olókè Éfúrémù, wọ́n sì dé ilé Míkà.+ 14  Àwọn ọkùnrin márùn-ún tó lọ ṣe amí ilẹ̀ Láíṣì+ wá sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé éfódì, àwọn ère tẹ́ráfímù,* ère gbígbẹ́ àti ère onírin*+ wà nínú àwọn ilé yìí? Ẹ ronú ohun tó yẹ kí ẹ ṣe.” 15  Wọ́n wá dúró níbẹ̀, wọ́n sì wá sí ilé ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ ọmọ Léfì+ náà ní ilé Míkà, wọ́n béèrè àlàáfíà rẹ̀. 16  Ní gbogbo ìgbà yẹn, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin látinú ẹ̀yà Dánì+ tó dira ogun dúró síbi àbáwọ ẹnubodè. 17  Àwọn ọkùnrin márùn-ún tó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà+ wá wọlé lọ kó ère gbígbẹ́, éfódì,+ àwọn ère tẹ́ráfímù*+ àti ère onírin*+ náà. (Àlùfáà náà+ dúró síbi àbáwọ ẹnubodè náà pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ọkùnrin tó dira ogun.) 18  Wọ́n wọnú ilé Míkà, wọ́n sì kó ère gbígbẹ́, éfódì, àwọn ère tẹ́ráfímù* àti ère onírin* náà. Àlùfáà náà bi wọ́n pé: “Kí lẹ̀ ń ṣe yìí?” 19  Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Dákẹ́. Fọwọ́ bo ẹnu rẹ, kí o sì tẹ̀ lé wa, kí o lè di bàbá* àti àlùfáà fún wa. Èwo ló dáa jù nínú kí o jẹ́ àlùfáà fún ilé ọkùnrin kan+ tàbí kí o di àlùfáà fún ẹ̀yà àti ìdílé kan ní Ísírẹ́lì?”+ 20  Ọ̀rọ̀ yẹn tẹ́ àlùfáà náà lọ́rùn, ó kó éfódì, àwọn ère tẹ́ráfímù* àti ère gbígbẹ́ náà,+ ó sì tẹ̀ lé àwọn èèyàn náà lọ. 21  Wọ́n wá ṣẹ́rí pa dà kí wọ́n lè máa lọ, wọ́n kó àwọn ọmọdé, àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn ohun tó ṣeyebíye síwájú. 22  Wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Míkà nígbà tí àwọn ọkùnrin tó ń gbé ní àwọn ilé tó wà nítòsí ilé Míkà kóra jọ, tí wọ́n sì lé àwọn ọmọ Dánì bá. 23  Nígbà tí wọ́n ké pe àwọn ọmọ Dánì, wọ́n yíjú pa dà, wọ́n sì sọ fún Míkà pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀? Kí ló dé tí ẹ lọ kóra yín jọ?” 24  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti kó àwọn ọlọ́run mi tí mo ṣe, ẹ tún mú àlùfáà lọ. Kí ló kù tí mo ní? Ṣé ó wá yẹ kí ẹ máa bi mí pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’” 25  Àwọn ọmọ Dánì sọ fún un pé: “Má pariwo mọ́ wa; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọkùnrin tínú ń bí* lè lù ọ́ bolẹ̀, ẹ̀mí* rẹ àti ti agbo ilé rẹ sì lè lọ sí i.” 26  Àwọn ọmọ Dánì wá ń bá tiwọn lọ; nígbà tí Míkà rí i pé wọ́n lágbára ju òun lọ, ó pa dà, ó sì lọ sí ilé rẹ̀. 27  Lẹ́yìn tí wọ́n kó àwọn ohun tí Míkà ṣe, títí kan àlùfáà rẹ̀, wọ́n lọ sí Láíṣì,+ lọ́dọ̀ àwọn èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, tí wọn kì í fura.+ Wọ́n fi idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n sì dáná sun ìlú náà. 28  Kò sẹ́ni tó lè gbà wọ́n sílẹ̀ torí pé ó jìnnà sí Sídónì, wọn kì í bá àwọn míì da nǹkan pọ̀, àfonífojì* tó jẹ́ ti Bẹti-réhóbù+ ni ìlú náà sì wà. Wọ́n wá tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. 29  Bákan náà, wọ́n sọ ìlú náà ní Dánì,+ ìyẹn Dánì orúkọ bàbá wọn, ẹni tí wọ́n bí fún Ísírẹ́lì.+ Àmọ́ Láíṣì ni ìlú náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.+ 30  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Dánì gbé ère gbígbẹ́ náà+ kalẹ̀ fún ara wọn, Jónátánì+ ọmọ Gẹ́ṣómù,+ ọmọ Mósè àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì di àlùfáà fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì títí di ọjọ́ tí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà fi lọ sí ìgbèkùn. 31  Wọ́n gbé ère gbígbẹ́ tí Míkà ṣe kalẹ̀, ó sì wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tí ilé Ọlọ́run tòótọ́ fi wà ní Ṣílò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ogún.”
Tàbí “ahọ́n.”
Ó túmọ̀ sí “Ibùdó Dánì.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “agbani-nímọ̀ràn.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “àwọn ọkùnrin tí ọkàn wọn gbọgbẹ́.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”