Àwọn Onídàájọ́ 20:1-48
-
Wọ́n gbógun ja àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì (1-48)
20 Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Dánì+ títí lọ dé Bíá-ṣébà àti ilẹ̀ Gílíádì,+ gbogbo àpéjọ náà sì kóra jọ sójú kan* níwájú Jèhófà ní Mísípà.+
2 Àwọn ìjòyè àwọn èèyàn náà àti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì dúró sí àyè wọn nínú ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn tó sì ń lo idà.+
3 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gbọ́ pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti lọ sí Mísípà.
Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì sọ pé: “Ẹ sọ fún wa, báwo ni nǹkan búburú yìí ṣe ṣẹlẹ̀?”+
4 Ọmọ Léfì,+ tó jẹ́ ọkọ obìnrin tí wọ́n pa náà wá dáhùn pé: “Èmi àti wáhàrí mi wá sun Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì mọ́jú.
5 Ni àwọn tó ń gbé* Gíbíà bá dìde sí mi, wọ́n sì yí ilé náà ká ní òru. Èmi ni wọ́n fẹ́ pa, àmọ́ dípò ìyẹn, wáhàrì* mi ni wọ́n fipá bá lò pọ̀, ó sì kú.+
6 Mo wá mú òkú wáhàrì mi, mo gé e sí wẹ́wẹ́, mo sì fi àwọn ègé náà ránṣẹ́ sí gbogbo ilẹ̀ tí Ísírẹ́lì jogún,+ torí ìwà burúkú àti ìwà tó ń dójú tini ni wọ́n hù ní Ísírẹ́lì.
7 Gbogbo ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ sọ ìmọ̀ràn+ yín àti ohun tí ẹ rò.”
8 Gbogbo àwọn èèyàn náà wá dìde, wọ́n fohùn ṣọ̀kan* pé: “Ìkankan nínú wa ò ní lọ sí àgọ́ rẹ̀, a ò sì ní pa dà sí ilé wa.
9 Ohun tí a máa ṣe sí Gíbíà nìyí: A máa ṣẹ́ kèké láti lọ bá a jà.+
10 A máa mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún (100) látinú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì. A sì máa mú ọgọ́rùn-ún (100) nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) àti ẹgbẹ̀rún (1,000) nínú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) pé kí wọ́n pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun náà, kí wọ́n lè gbógun ja Gíbíà ti Bẹ́ńjámínì, torí ìwà tó ń dójú tini tí wọ́n hù ní Ísírẹ́lì.”
11 Gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì bá kóra jọ, wọ́n fìmọ̀ ṣọ̀kan* bí ọmọ ẹgbẹ́ láti lọ gbógun ja ìlú náà.
12 Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo àwọn ọkùnrin ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì pé: “Irú ohun burúkú wo ló ṣẹlẹ̀ láàárín yín yìí?
13 Ó yá, ẹ fi àwọn ọkùnrin Gíbíà+ tí kò ní láárí yẹn lé wa lọ́wọ́, ká lè pa wọ́n, ká sì mú ohun tí kò dáa kúrò ní Ísírẹ́lì.”+ Àmọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kò fetí sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ arákùnrin wọn.
14 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì wá kóra jọ látinú àwọn ìlú sí Gíbíà, kí wọ́n lè lọ bá àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jà.
15 Lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26,000) ọkùnrin tó ń lo idà jọ látinú àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí ọgọ́rùn-ún méje (700) ọkùnrin tí wọ́n yàn láti Gíbíà.
16 Ọgọ́rùn-ún méje (700) ọkùnrin tí wọ́n yàn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́wọ́ òsì wà lára àwọn ọmọ ogun yìí. Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ló lè fi kànnàkànnà ju òkúta ba ìbú fọ́nrán irun, tí kò sì ní tàsé.
17 Yàtọ̀ sí Bẹ́ńjámínì, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin tó ń lo idà+ jọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì mọ ogun jà dáadáa.
18 Wọ́n gbéra, wọ́n sì lọ sí Bẹ́tẹ́lì láti wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wá sọ pé: “Ta ni kó ṣáájú nínú wa láti lọ bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jà?” Jèhófà fèsì pé: “Júdà ni kó ṣáájú.”
19 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dìde ní àárọ̀, wọ́n sì pàgọ́ ti Gíbíà.
20 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá jáde lọ gbógun ja Bẹ́ńjámínì; wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun jà wọ́n ní Gíbíà.
21 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì wá jáde láti Gíbíà, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin Ísírẹ́lì lọ́jọ́ yẹn.
22 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì fi hàn pé àwọn nígboyà, wọ́n bá tún tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun jà wọ́n ní ibì kan náà bíi ti ọjọ́ àkọ́kọ́.
23 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá gòkè lọ, wọ́n sì sunkún níwájú Jèhófà títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ṣé ká tún lọ bá àwọn arákùnrin wa, àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì jà?”+ Jèhófà fèsì pé: “Ẹ lọ bá wọn jà.”
24 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sún mọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ní ọjọ́ kejì.
25 Ni Bẹ́ńjámínì bá jáde wá bá wọn láti Gíbíà lọ́jọ́ kejì, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) míì tí gbogbo wọn ń lo idà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
26 Torí náà, gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n sunkún, wọ́n sì jókòó síbẹ̀ níwájú Jèhófà,+ wọ́n gbààwẹ̀+ lọ́jọ́ yẹn títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì rú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ níwájú Jèhófà.
27 Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ torí àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́ wà níbẹ̀ nígbà yẹn.
28 Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì, ọmọ Áárónì, ló ń ṣiṣẹ́* níwájú rẹ̀ nígbà yẹn. Wọ́n béèrè pé: “Ṣé ká tún lọ bá àwọn arákùnrin wa, àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì jà, àbí ká má lọ mọ́?”+ Jèhófà fèsì pé: “Ẹ lọ, torí ọ̀la ni màá fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”
29 Ísírẹ́lì wá ní kí àwọn ọkùnrin lọ lúgọ+ yí Gíbíà ká.
30 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jà ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun ja Gíbíà bíi ti tẹ́lẹ̀.+
31 Nígbà tí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jáde lọ bá àwọn ọmọ ogun náà, wọ́n tàn wọ́n jìnnà sí ìlú náà.+ Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun jà wọ́n bíi ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sì pa lára àwọn ọkùnrin náà láwọn ojú ọ̀nà, tí ọ̀kan lọ sí Bẹ́tẹ́lì tí èkejì sì lọ sí Gíbíà, nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọkùnrin Ísírẹ́lì ni wọ́n pa sínú pápá gbalasa.+
32 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì wá sọ pé: “A ti ń ṣẹ́gun wọn bíi ti tẹ́lẹ̀.”+ Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé: “A máa sá fún wọn, a sì máa tàn wọ́n jìnnà sí ìlú náà wá sí ojú ọ̀nà.”
33 Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá dìde láwọn ibi tí wọ́n wà, wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní Baali-támárì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lúgọ sì jáde láwọn ibi tí wọ́n wà nítòsí Gíbíà.
34 Bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin tí wọ́n yàn látinú gbogbo Ísírẹ́lì ṣe wá síwájú Gíbíà nìyẹn, ìjà náà sì le gan-an. Àmọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ò mọ̀ pé àjálù rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí àwọn.
35 Jèhófà ṣẹ́gun Bẹ́ńjámínì+ níwájú Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún kan (25,100) ọkùnrin Bẹ́ńjámínì tí wọ́n ń lo idà+ ni Ísírẹ́lì pa lọ́jọ́ yẹn.
36 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ti rò pé àwọn máa ṣẹ́gun àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń sá fún Bẹ́ńjámínì,+ àmọ́ ohun tó mú kí wọ́n sá ni pé ọkàn wọn balẹ̀ torí àwọn tó lúgọ láti gbógun ja Gíbíà.+
37 Àwọn tó lúgọ náà ò fi nǹkan falẹ̀ rárá, wọ́n yára sún mọ́ Gíbíà. Wọ́n wá pín ara wọn yí ká ìlú náà, wọ́n sì fi idà ṣá gbogbo ìlú náà balẹ̀.
38 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti ṣètò pé kí àwọn ọkùnrin tó lúgọ sí tòsí ìlú náà mú kí èéfín rú láti ibẹ̀, kó lè jẹ́ àmì fún wọn.
39 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́rí pa dà lójú ogun, àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun jà wọ́n, wọ́n sì pa nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọkùnrin Ísírẹ́lì,+ wọ́n wá sọ pé: “Ó dájú pé a tún ti ń ṣẹ́gun wọn bíi ti tẹ́lẹ̀.”+
40 Àmọ́ èéfín tí wọ́n fi ṣe àmì náà bẹ̀rẹ̀ sí í rú sókè látinú ìlú náà, ó rí bí òpó. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì yíjú pa dà, wọ́n rí i pé gbogbo ìlú náà ti ń jóná, èéfín rẹ̀ sì ń lọ sókè.
41 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá yíjú pa dà, jìnnìjìnnì sì bá àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì, torí wọ́n rí i pé àjálù ti dé bá àwọn.
42 Torí náà, wọ́n sá fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì gba ọ̀nà aginjù, àmọ́ Ísírẹ́lì gbógun tẹ̀ lé wọn; àwọn ọkùnrin tó jáde látinú àwọn ìlú náà dara pọ̀ mọ́ wọn láti bá wọn jà.
43 Wọ́n yí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ká. Wọ́n sì ń lé wọn, wọn ò dẹ̀yìn lẹ́yìn wọn. Wọ́n ṣẹ́gun wọn níwájú Gíbíà gangan, lápá ìlà oòrùn.
44 Níkẹyìn, ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) ọkùnrin Bẹ́ńjámínì ló kú, jagunjagun tó lákíkanjú+ ni gbogbo wọn.
45 Àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì ṣẹ́rí pa dà, wọ́n sì sá lọ sí aginjù, níbi àpáta Rímónì.+ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa* ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) nínú wọn lójú ọ̀nà, wọ́n sì ń lé wọn títí dé Gídómù; wọ́n wá pa ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọkùnrin sí i.
46 Gbogbo àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì tó kú lọ́jọ́ yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ọkùnrin tó ń lo idà,+ jagunjagun tó lákíkanjú ni gbogbo wọn.
47 Àmọ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) lára wọn sá lọ sí aginjù, níbi àpáta Rímónì, wọ́n sì dúró sórí àpáta Rímónì fún oṣù mẹ́rin.
48 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yíjú pa dà, wọ́n sì gbógun ja àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, wọ́n fi idà pa àwọn tó wà nínú ìlú, látorí èèyàn dórí ẹran ọ̀sìn, gbogbo ohun tó ṣẹ́ kù. Bákan náà, gbogbo ìlú tí wọ́n rí lójú ọ̀nà ni wọ́n dáná sun.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “bí ẹnì kan ṣoṣo.”
^ Tàbí kó jẹ́, “àwọn onílẹ̀.”
^ Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
^ Ní Héb., “dìde bí ẹnì kan ṣoṣo.”
^ Ní Héb., “bí ẹnì kan ṣoṣo.”
^ Ní Héb., “dúró.”
^ Ní Héb., “pèéṣẹ́.”