Àwọn Onídàájọ́ 21:1-25
-
Wọ́n gba ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sílẹ̀ (1-25)
21 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti búra ní Mísípà+ pé: “Ìkankan nínú wa ò ní fún ọkùnrin kankan tó jẹ́ ọmọ Bẹ́ńjámínì ní ọmọbìnrin rẹ̀ pé kó fi ṣe aya.”+
2 Torí náà, àwọn èèyàn náà wá sí Bẹ́tẹ́lì,+ wọ́n sì jókòó síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run tòótọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n ń ké, wọ́n sì ń sunkún gidigidi.
3 Wọ́n ń sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí ló dé tí èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì? Kí ló dé tí ẹ̀yà Ísírẹ́lì fi dín ọ̀kan lónìí?”
4 Lọ́jọ́ kejì, àwọn èèyàn náà dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, láti rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+
5 Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wá sọ pé: “Èwo nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni kò wá láti pé jọ síwájú Jèhófà?” torí wọ́n ti ṣe ìbúra tó lágbára pé ṣe ni wọ́n máa pa ẹnikẹ́ni tí kò bá wá sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà.
6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì banú jẹ́ torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bẹ́ńjámínì arákùnrin wọn. Wọ́n ní: “A ti gé ẹ̀yà kan kúrò ní Ísírẹ́lì lónìí.
7 Báwo la ṣe máa rí ìyàwó fún àwọn tó ṣẹ́ kù, torí a ti fi Jèhófà búra+ pé a ò ní fún wọn ní ìkankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa pé kí wọ́n fi ṣe aya?”+
8 Wọ́n béèrè pé: “Èwo nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni kò wá sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà?”+ Ó ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kankan ò wá láti Jabeṣi-gílíádì sínú ibùdó tí ìjọ náà wà.
9 Nígbà tí wọ́n ka àwọn èèyàn náà, wọ́n rí i pé ìkankan nínú àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì kò sí níbẹ̀.
10 Àpéjọ náà wá rán ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) lára àwọn ọkùnrin tó lágbára jù lọ síbẹ̀. Wọ́n pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ lọ fi idà pa àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì, títí kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.+
11 Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Kí ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tó ti bá ọkùnrin lò pọ̀ run.”
12 Láàárín àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì, wọ́n rí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọmọbìnrin tí wọ́n jẹ́ wúńdíá, tí wọn ò bá ọkùnrin lò pọ̀ rí. Wọ́n sì kó wọn wá sí ibùdó tó wà ní Ṣílò,+ èyí tó wà ní ilẹ̀ Kénáánì.
13 Gbogbo àpéjọ náà wá ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì tó wà lórí àpáta Rímónì,+ wọ́n sì bá wọn ṣàdéhùn àlàáfíà.
14 Ìgbà yẹn ni Bẹ́ńjámínì wá pa dà. Wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin tí wọ́n dá ẹ̀mí wọn sí nínú àwọn obìnrin Jabeṣi-gílíádì,+ àmọ́ iye tí wọ́n rí yẹn ò kárí wọn.
15 Àwọn èèyàn náà sì banú jẹ́ torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bẹ́ńjámínì,+ torí Jèhófà ti pín ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyà.
16 Àwọn àgbààgbà àpéjọ náà sọ pé: “Báwo la ṣe máa rí ìyàwó fún àwọn ọkùnrin yòókù, torí pé gbogbo obìnrin Bẹ́ńjámínì ló ti pa run?”
17 Wọ́n fèsì pé: “Ó yẹ kí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì tó yè bọ́ ní ogún, kí ẹ̀yà kan má bàa pa run ní Ísírẹ́lì.
18 Àmọ́, a ò ní lè fún wọn ní àwọn ọmọbìnrin wa pé kí wọ́n fi ṣe aya, torí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti búra pé: ‘Ègún ni fún ẹni tó bá fún Bẹ́ńjámínì níyàwó.’”+
19 Wọ́n wá sọ pé: “Ẹ wò ó! Àjọyọ̀ Jèhófà tí a máa ń ṣe lọ́dọọdún máa wáyé ní Ṣílò,+ èyí tó wà ní àríwá Bẹ́tẹ́lì, lápá ìlà oòrùn ọ̀nà tó lọ láti Bẹ́tẹ́lì sí Ṣékémù àti gúúsù Lẹ́bónà.”
20 Torí náà, wọ́n pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì pé: “Ẹ lọ lúgọ sínú àwọn ọgbà àjàrà.
21 Tí ẹ bá sì rí àwọn ọ̀dọ́bìnrin* Ṣílò tí wọ́n ń jáde wá bá àwọn yòókù jó ijó àjóyípo, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín jáde látinú àwọn ọgbà àjàrà, kí ẹ sì sáré gbé ìkọ̀ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́bìnrin Ṣílò láti fi ṣe aya. Kí ẹ wá pa dà sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì.
22 Tí àwọn bàbá wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn bá sì wá fi ẹjọ́ sùn wá, a máa sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣàánú wa torí tiwọn, torí pé a ò rí ìyàwó fún gbogbo wọn látojú ogun,+ ẹ̀yin náà ò sì lè fún wọn ní ìyàwó kí ẹ má jẹ̀bi.’”+
23 Torí náà, ohun tí àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gbé lára àwọn obìnrin tó ń jó lọ láti fi ṣe aya. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí ilẹ̀ tí wọ́n jogún, wọ́n tún àwọn ìlú wọn kọ́,+ wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
24 Nígbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tú ká látibẹ̀, kálukú pa dà sọ́dọ̀ ẹ̀yà rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀, wọ́n sì kúrò níbẹ̀, kálukú pa dà sí ilẹ̀ tó jogún.
25 Kò sí ọba kankan ní Ísírẹ́lì+ nígbà yẹn. Kálukú ń ṣe ohun tó tọ́ lójú ara rẹ̀.*