Àwọn Onídàájọ́ 4:1-24
4 Àmọ́ lẹ́yìn tí Éhúdù kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà.+
2 Torí náà, Jèhófà fi wọ́n lé ọwọ́ Jábínì ọba Kénáánì,+ tó jọba ní Hásórì. Sísérà ni olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ó sì ń gbé ní Háróṣétì+ ti àwọn orílẹ̀-èdè.*
3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà,+ torí pé Jábínì* ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin,*+ ogún (20) ọdún ló sì fi fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gidigidi.+
4 Nígbà yẹn, Dèbórà, wòlíì obìnrin+ tó jẹ́ ìyàwó Lápídótù ń ṣe ìdájọ́ ní Ísírẹ́lì.
5 Abẹ́ igi ọ̀pẹ Dèbórà ló máa ń jókòó sí, láàárín Rámà+ àti Bẹ́tẹ́lì,+ ní agbègbè olókè Éfúrémù; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kó ẹjọ́ wọn lọ bá a.
6 Ó ránṣẹ́ sí Bárákì+ ọmọ Ábínóámù láti Kedeṣi-náfútálì,+ ó sì sọ fún un pé: “Ṣebí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti pàṣẹ? ‘Lọ sí* Òkè Tábórì, kí o sì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin dání látinú àwọn ọmọ Náfútálì àti Sébúlúnì.
7 Màá mú Sísérà, olórí àwọn ọmọ ogun Jábínì wá bá ọ, tòun ti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá sí odò* Kíṣónì,+ màá sì fi lé ọ lọ́wọ́.’”+
8 Ni Bárákì bá sọ fún un pé: “Tí o bá máa tẹ̀ lé mi, màá lọ, àmọ́ tó ò bá tẹ̀ lé mi, mi ò ní lọ.”
9 Dèbórà fèsì pé: “Ó dájú pé màá bá ọ lọ. Àmọ́ o ò ní gba ògo nínú ogun tí o fẹ́ lọ jà yìí, torí obìnrin ni Jèhófà máa fi Sísérà+ lé lọ́wọ́.” Dèbórà wá gbéra, ó sì tẹ̀ lé Bárákì lọ sí Kédéṣì.+
10 Bárákì pe Sébúlúnì àti Náfútálì+ sí Kédéṣì, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin sì tẹ̀ lé e. Dèbórà náà bá a lọ.
11 Ó ṣẹlẹ̀ pé Hébà ará Kénì ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn Kénì,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Hóbábù, bàbá ìyàwó+ Mósè, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí igi ńlá ní Sáánánímù, tó wà ní Kédéṣì.
12 Sísérà wá gbọ́ pé Bárákì ọmọ Ábínóámù ti lọ sórí Òkè Tábórì.+
13 Ojú ẹsẹ̀ ni Sísérà ṣètò gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin* àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè lọ sí odò* Kíṣónì.+
14 Dèbórà wá sọ fún Bárákì pé: “Gbéra, torí òní yìí ni Jèhófà máa fi Sísérà lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí Jèhófà ń ṣáájú rẹ lọ?” Bárákì sì sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Tábórì pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin tó ń tẹ̀ lé e.
15 Jèhófà wá mú kí nǹkan dà rú mọ́ Sísérà lójú+ pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ níwájú idà Bárákì. Nígbà tó yá, Sísérà sọ̀ kalẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì sá lọ.
16 Bárákì lé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun náà àti àwọn ọmọ ogun títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀-èdè. Bí wọ́n ṣe fi idà pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Sísérà nìyẹn; ìkankan nínú wọn ò ṣẹ́ kù.+
17 Àmọ́ Sísérà sá lọ sí àgọ́ Jáẹ́lì+ ìyàwó Hébà+ ará Kénì, torí àlàáfíà wà láàárín Jábínì+ ọba Hásórì àti ìdílé Hébà ará Kénì.
18 Jáẹ́lì sì jáde wá pàdé Sísérà, ó sọ fún un pé: “Wọlé, olúwa mi, máa bọ̀ níbí. Má bẹ̀rù.” Ló bá wọlé sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ tó nípọn bò ó.
19 Ó wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní omi díẹ̀ mu, torí òùngbẹ ń gbẹ mí.” Ni Jáẹ́lì bá ṣí ìgò awọ kan tí wọ́n rọ wàrà sí, ó sì fún un mu,+ ó wá tún fi aṣọ bò ó.
20 Sísérà sọ fún Jáẹ́lì pé: “Dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́, tí ẹnikẹ́ni bá sì wá bi ọ́ pé, ‘Ṣé ọkùnrin kankan wà níbí?’ kí o sọ pé, ‘Rárá!’”
21 Àmọ́ Jáẹ́lì ìyàwó Hébà mú èèkàn àgọ́, ó sì mú òòlù dání. Nígbà tí ọkùnrin náà ti sùn lọ fọnfọn, tó sì ti rẹ̀ ẹ́, Jáẹ́lì yọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó gbá èèkàn àgọ́ náà wọnú ẹ̀bátí rẹ̀, ó gbá a wọlẹ̀, ọkùnrin náà sì kú.+
22 Bárákì wá Sísérà débẹ̀, Jáẹ́lì sì jáde wá pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Máa bọ̀, jẹ́ kí n fi ọkùnrin tí ò ń wá hàn ọ́.” Bárákì bá tẹ̀ lé e wọlé, ó sì rí òkú Sísérà nílẹ̀, pẹ̀lú èèkàn àgọ́ tí Jáẹ́lì gbá wọnú ẹ̀bátí rẹ̀.
23 Ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run mú kí apá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká+ Jábínì ọba Kénáánì.
24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ ń ran Jábínì ọba Kénáánì,+ títí wọ́n fi pa Jábínì ọba Kénáánì.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Haroṣeti-há-góímù.”
^ Ní Héb., “ó.”
^ Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”
^ Tàbí “Pín àwọn ọkùnrin rẹ sórí.”
^ Tàbí “àfonífojì.”
^ Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”
^ Tàbí “àfonífojì.”