Àwọn Onídàájọ́ 7:1-25

  • Gídíónì àti 300 ọkùnrin rẹ̀ (1-8)

  • Àwọn ọmọ ogun Gídíónì ṣẹ́gun Mídíánì (9-25)

    • “Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!” (20)

    • Ibùdó Mídíánì dà rú (21, 22)

7  Jerubáálì, ìyẹn Gídíónì+ àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n sì pàgọ́ síbi ìsun omi Háródù, ibùdó Mídíánì wà ní àríwá rẹ̀, níbi òkè Mórè, ní àfonífojì.*  Jèhófà wá sọ fún Gídíónì pé: “Àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ ti pọ̀ jù fún mi láti fi Mídíánì lé wọn lọ́wọ́.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Ísírẹ́lì máa gbé ara rẹ̀ ga sí mi, wọ́n á ní, ‘Ọwọ́ ara mi ló gbà mí là.’+  Jọ̀ọ́, kéde níṣojú gbogbo àwọn èèyàn náà báyìí, pé: ‘Kí ẹnikẹ́ni tó bá ń bẹ̀rù tí àyà rẹ̀ sì ń já pa dà sílé.’”+ Torí náà, Gídíónì dán wọn wò. Ìyẹn mú kí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn èèyàn náà pa dà sílé, ó sì ṣẹ́ ku ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000).  Síbẹ̀, Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: “Àwọn èèyàn yìí ṣì pọ̀ jù. Ní kí wọ́n lọ síbi omi kí n lè bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Tí mo bá sọ fún ọ pé, ‘Ẹni yìí máa bá ọ lọ,’ ó máa bá ọ lọ, àmọ́ tí mo bá sọ fún ọ pé, ‘Ẹni yìí ò ní bá ọ lọ,’ kò ní bá ọ lọ.”  Ó wá kó àwọn èèyàn náà lọ síbi omi. Jèhófà sì sọ fún Gídíónì pé: “Ya gbogbo àwọn tó ń fi ahọ́n lá omi bí ajá sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó kúnlẹ̀ láti mu omi.”  Iye àwọn tó ń lá omi, tí wọ́n ń fi ọwọ́ bu omi sẹ́nu jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin. Àwọn yòókù kúnlẹ̀ láti mu omi.  Jèhófà wá sọ fún Gídíónì pé: “Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó lá omi ni màá fi gbà yín là, mo sì máa fi Mídíánì lé ọ lọ́wọ́.+ Jẹ́ kí gbogbo àwọn yòókù pa dà sílé.”  Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n gba oúnjẹ àtàwọn ìwo lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà, ó ní kí gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì yòókù pa dà sílé, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin náà nìkan ló sì ní kó dúró. Ibùdó Mídíánì wà nísàlẹ̀ rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀.+  Jèhófà sọ fún un lálẹ́ ọjọ́ yẹn pé: “Dìde, lọ gbógun ja ibùdó náà, torí mo ti fi lé ọ lọ́wọ́.+ 10  Àmọ́ tí ẹ̀rù bá ń bà ọ́ láti gbéjà kò wọ́n, kí ìwọ àti Púrà ìránṣẹ́ rẹ lọ sí ibùdó náà. 11  Tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, wàá ní ìgboyà* láti gbógun ja ibùdó náà.” Torí náà, òun àti Púrà ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí etí ibi tí àwọn ọmọ ogun náà pàgọ́ sí. 12  Mídíánì, Ámálékì àti gbogbo àwọn Ará Ìlà Oòrùn+ kóra jọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, wọ́n pọ̀ bí eéṣú, àwọn ràkúnmí wọn kò sì níye,+ wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun. 13  Gídíónì wá dé, ọkùnrin kan sì ń rọ́ àlá fún ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Àlá tí mo lá nìyí. Búrẹ́dì ribiti kan tí wọ́n fi ọkà bálì ṣe ń yí gbiri bọ̀ wá sínú ibùdó Mídíánì. Ó dé àgọ́ kan, ó sì kọ lù ú débi pé àgọ́ náà ṣubú.+ Àní, ó dojú àgọ́ náà dé, ó sì wó o lulẹ̀.” 14  Ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá sọ fún un pé: “Idà Gídíónì+ ọmọ Jóáṣì, ọkùnrin Ísírẹ́lì nìkan ló lè jẹ́. Ọlọ́run ti fi Mídíánì àti gbogbo ibùdó náà lé e lọ́wọ́.”+ 15  Gbàrà tí Gídíónì gbọ́ tó rọ́ àlá náà, tó sì gbọ́ ìtumọ̀ rẹ̀,+ ó forí balẹ̀, ó sì jọ́sìn. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí ibùdó Ísírẹ́lì, ó sì sọ pé: “Ẹ dìde, torí Jèhófà ti fi ibùdó Mídíánì lé yín lọ́wọ́.” 16  Ó wá pín ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin náà sí àwùjọ mẹ́ta, ó fún gbogbo wọn ní ìwo+ àti ìṣà ńlá tó ṣófo, ògùṣọ̀ sì wà nínú àwọn ìṣà náà. 17  Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa wò mí, ohun tí mo bá sì ṣe gẹ́lẹ́ ni kí ẹ ṣe. Tí mo bá dé etí ibùdó náà, ohun tí mo bá ṣe gẹ́lẹ́ ni kí ẹ ṣe. 18  Tí èmi àti gbogbo àwọn tó wà lọ́dọ̀ mi bá fun ìwo, kí ẹ̀yin náà fun ìwo yí ká ibùdó náà, kí ẹ sì kígbe pé, ‘Ti Jèhófà àti ti Gídíónì!’” 19  Gídíónì àti ọgọ́rùn-ún (100) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá sí etí ibùdó ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣọ́ àárín òru,* gbàrà tí wọ́n yan àwọn ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ibùdó sí àyè wọn. Wọ́n fun ìwo,+ wọ́n sì fọ́ àwọn ìṣà omi ńlá tó wà lọ́wọ́ wọn+ túútúú. 20  Àwùjọ ọmọ ogun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wá fun ìwo, wọ́n sì fọ́ àwọn ìṣà ńlá náà túútúú. Wọ́n fi ọwọ́ òsì di ògùṣọ̀ mú, wọ́n fun ìwo tó wà lọ́wọ́ ọ̀tún wọn, wọ́n sì kígbe pé: “Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!” 21  Ní gbogbo àkókò yẹn, kálukú wọn dúró sí àyè rẹ̀ yí ibùdó náà ká, gbogbo àwọn ọmọ ogun sì sá lọ, wọ́n ń kígbe bí wọ́n ṣe ń sá lọ.+ 22  Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó ń fun ìwo náà ò dáwọ́ dúró, Jèhófà sì mú kí àwọn ọmọ ogun dojú idà kọra wọn ní gbogbo ibùdó náà;+ àwọn ọmọ ogun náà sì sá lọ títí dé Bẹti-ṣítà, wọ́n sá dé Sérérà, títí dé ẹ̀yìn ìlú Ebẹli-méhólà+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tábátì. 23  Wọ́n wá pe àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jọ láti Náfútálì, Áṣérì àti gbogbo Mánásè,+ wọ́n sì lé Mídíánì. 24  Gídíónì ránṣẹ́ sí gbogbo agbègbè olókè Éfúrémù pé: “Ẹ lọ gbógun ja Mídíánì, kí ẹ sì gba ọ̀nà tó dé ibi omi mọ́ wọn lọ́wọ́ títí dé Bẹti-bárà àti Jọ́dánì.” Gbogbo àwọn ọkùnrin Éfúrémù wá kóra jọ, wọ́n sì gba ibi omi náà títí dé Bẹti-bárà àti Jọ́dánì. 25  Wọ́n tún mú àwọn ìjòyè Mídíánì méjèèjì, ìyẹn Órébù àti Séébù; wọ́n pa Órébù lórí àpáta Órébù,+ wọ́n sì pa Séébù níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì Séébù. Wọn ò dẹ̀yìn lẹ́yìn Mídíánì,+ wọ́n sì gbé orí Órébù àti Séébù wá fún Gídíónì ní agbègbè Jọ́dánì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “ọwọ́ rẹ máa lágbára.”
Láti nǹkan bí aago mẹ́wàá alẹ́ sí nǹkan bí aago méjì òru.