Àwọn Onídàájọ́ 8:1-35

  • Àwọn èèyàn Éfúrémù bínú sí Gídíónì (1-3)

  • Wọ́n lé àwọn ọba Mídíánì mú, wọ́n sì pa wọ́n (4-21)

  • Gídíónì ò gbà kí wọ́n fi òun jọba (22-27)

  • Àkópọ̀ ìtàn ìgbésí ayé Gídíónì (28-35)

8  Àwọn ọkùnrin Éfúrémù wá sọ fún un pé: “Kí lo ṣe sí wa yìí? Kí ló dé tí o ò pè wá nígbà tí o lọ bá Mídíánì jà?”+ Wọ́n sì bínú sí i gidigidi.+  Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe wá tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiyín? Ṣé èéṣẹ́ Éfúrémù  + ò dáa ju ìkórè èso àjàrà Abi-ésérì lọ ni?+  Ẹ̀yin ni Ọlọ́run fi àwọn ìjòyè Mídíánì, ìyẹn Órébù àti Séébù+ lé lọ́wọ́, ṣé ohun tí mo ṣe wá tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiyín?” Nígbà tó sọ̀rọ̀ báyìí,* ara wọn balẹ̀.*  Lẹ́yìn náà, Gídíónì dé Jọ́dánì, ó sì sọdá. Ó ti rẹ òun àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀, àmọ́ wọn ò dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn tí wọ́n ń lé.  Ó wá sọ fún àwọn ọkùnrin Súkótù pé: “Ẹ jọ̀ọ́ ẹ fún àwọn èèyàn tó ń tẹ̀ lé mi yìí ní ìṣù búrẹ́dì, torí ó ti rẹ̀ wọ́n, mo sì ń lé Séébà àti Sálímúnà, àwọn ọba Mídíánì.”  Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Súkótù sọ fún un pé: “Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Séébà àti Sálímúnà* ni, tí a fi máa fún àwọn ọmọ ogun rẹ ní búrẹ́dì?”  Gídíónì wá fún wọn lésì pé: “Torí ìyẹn, tí Jèhófà bá fi Séébà àti Sálímúnà lé mi lọ́wọ́, màá fi ẹ̀gún àti òṣùṣú inú aginjù+ lù yín nílùkulù.”  Ó wá kúrò níbẹ̀ lọ sí Pénúélì, ó sì béèrè ohun kan náà lọ́wọ́ wọn, àmọ́ èsì tí àwọn ọkùnrin Súkótù fún un gẹ́lẹ́ ni àwọn ọkùnrin Pénúélì fún un.  Ló bá tún sọ fún àwọn ọkùnrin Pénúélì náà pé: “Tí mo bá pa dà ní àlàáfíà, màá wó ilé gogoro+ yìí.” 10  Séébà àti Sálímúnà wà ní Kákórì, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin. Àwọn tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ọmọ ogun àwọn Ará Ìlà Oòrùn+ nìyí, torí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tó ń fi idà jà ni wọ́n ti pa. 11  Gídíónì gòkè gba ọ̀nà àwọn tó ń gbé inú àgọ́ ní ìlà oòrùn Nóbà àti Jógíbéhà,+ ó sì gbógun ja ibùdó náà nígbà tí wọn ò fura. 12  Nígbà tí Séébà àti Sálímúnà sá, ó lé àwọn ọba Mídíánì méjèèjì bá, ó sì gbá wọn mú, ìyẹn Séébà àti Sálímúnà, jìnnìjìnnì sì bá gbogbo ibùdó náà. 13  Gídíónì ọmọ Jóáṣì wá gba ọ̀nà tó lọ sí Hérésì pa dà láti ojú ogun. 14  Ó mú ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Súkótù lójú ọ̀nà, ó sì béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin náà wá kọ orúkọ àwọn ìjòyè àti àwọn àgbààgbà Súkótù fún un, wọ́n jẹ́ ọkùnrin mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77). 15  Ó wá lọ bá àwọn ọkùnrin Súkótù, ó sì sọ fún wọn pé: “Séébà àti Sálímúnà tí ẹ tìtorí wọn ṣáátá mi rèé, tí ẹ sọ pé, ‘Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Séébà àti Sálímúnà* ni, tí a fi máa fún àwọn ọmọ ogun rẹ tó ti rẹ̀ ní búrẹ́dì?’”+ 16  Ló bá mú àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì fi àwọn ẹ̀gún àti òṣùṣú inú aginjù kọ́ àwọn ọkùnrin Súkótù lọ́gbọ́n.+ 17  Ó wó ilé gogoro Pénúélì,+ ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà. 18  Ó bi Séébà àti Sálímúnà pé: “Irú àwọn ọkùnrin wo lẹ pa ní Tábórì?” Wọ́n fún un lésì pé: “Bí o ṣe rí ni wọ́n rí, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn rí bí ọmọ ọba.” 19  Ló bá sọ fún wọn pé: “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Bí Jèhófà ti wà, ká ní ẹ dá ẹ̀mí wọn sí ni, mi ò ní pa yín.” 20  Ó wá sọ fún Jétà àkọ́bí rẹ̀ pé: “Dìde, kí o pa wọ́n.” Àmọ́ ọ̀dọ́kùnrin náà ò fa idà rẹ̀ yọ; ẹ̀rù ń bà á, torí ó ṣì kéré. 21  Torí náà, Séébà àti Sálímúnà sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ dìde, kí o sì pa wá, torí bí ẹnì kan bá ṣe lágbára tó la fi ń mọ̀ bóyá ọkùnrin ni.”* Gídíónì wá dìde, ó pa Séébà àti Sálímúnà,+ ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí òṣùpá tó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn. 22  Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún Gídíónì pé: “Máa jọba lórí wa, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú ọmọ ọmọ rẹ, torí o ti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ Mídíánì.”+ 23  Àmọ́ Gídíónì sọ fún wọn pé: “Mi ò ní jọba lé yín lórí, ọmọ mi náà ò sì ní jọba lé yín lórí. Jèhófà ló máa jọba lé yín lórí.”+ 24  Gídíónì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ jẹ́ kí n béèrè ohun kan lọ́wọ́ yín: kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín fún mi ní òrùka imú kan látinú ẹrù tó kó bọ̀ láti ogun.” (Wọ́n ní òrùka imú tí wọ́n fi wúrà ṣe, torí pé ọmọ Íṣímáẹ́lì+ ni wọ́n.) 25  Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ó dájú pé a máa fún ọ.” Ni wọ́n bá tẹ́ aṣọ kan, kálukú wọn sì ju òrùka imú sórí rẹ̀ látinú ẹrù tó kó bọ̀ láti ogun. 26  Ìwọ̀n òrùka imú tí wọ́n fi wúrà ṣe tó béèrè lọ́wọ́ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje (1,700) ṣékélì wúrà,* yàtọ̀ sí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí òṣùpá, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n máa ń so mọ́ ẹ̀gbà ọrùn, aṣọ aláwọ̀ pọ́pù tí àwọn ọba Mídíánì máa ń wọ̀ àtàwọn ẹ̀gbà ọrùn tí wọ́n yọ ní ọrùn àwọn ràkúnmí.+ 27  Gídíónì wá fi ṣe éfódì+ kan, ó sì gbé e sí gbangba ní Ọ́fírà+ ìlú rẹ̀; gbogbo Ísírẹ́lì sì bá a ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀,+ ó wá di ìdẹkùn fún Gídíónì àti agbo ilé rẹ̀.+ 28  Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun Mídíánì+ nìyẹn, wọn ò sì yọ wọ́n lẹ́nu* mọ́; àlàáfíà wá wà ní ilẹ̀ náà* fún ogójì (40) ọdún nígbà ayé Gídíónì.+ 29  Jerubáálì+ ọmọ Jóáṣì pa dà sí ilé rẹ̀, ó sì wà níbẹ̀. 30  Gídíónì bí àádọ́rin (70) ọmọkùnrin,* torí ó fẹ́ ìyàwó púpọ̀. 31  Wáhàrì* rẹ̀ tó wà ní Ṣékémù náà bí ọmọkùnrin kan fún un, ó sì sọ ọ́ ní Ábímélékì.+ 32  Gídíónì ọmọ Jóáṣì dàgbà darúgbó kó tó kú, wọ́n sì sin ín sínú ibojì Jóáṣì bàbá rẹ̀ ní Ọ́fírà ti àwọn ọmọ Abi-ésérì.+ 33  Àmọ́ gbàrà tí Gídíónì kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bá àwọn Báálì+ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, wọ́n sì fi Baali-bérítì ṣe ọlọ́run wọn.+ 34  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rántí Jèhófà Ọlọ́run wọn,+ ẹni tó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá tó yí wọn ká;+ 35  wọn ò sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí agbo ilé Jerubáálì, ìyẹn Gídíónì, pẹ̀lú gbogbo ohun rere tó ṣe fún Ísírẹ́lì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “sọ ọ̀rọ̀ yìí.”
Ní Héb., “ẹ̀mí wọn rọlẹ̀, wọn ò sì ta kò ó mọ́.”
Ní Héb., “àtẹ́lẹwọ́ Séébà àti Sálímúnà.”
Ní Héb., “àtẹ́lẹwọ́ Séébà àti Sálímúnà.”
Tàbí “bí ọkùnrin bá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ ṣe máa tó.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “gbé orí wọn sókè.”
Tàbí “ilẹ̀ náà wá sinmi.”
Ní Héb., “ní àádọ́rin ọmọkùnrin tó jáde wá láti itan rẹ̀.”
Tàbí “Ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”