Ẹ́kísódù 1:1-22
1 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n bá Jékọ́bù wá sí Íjíbítì nìyí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan tó mú agbo ilé rẹ̀ wá:+
2 Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà;+
3 Ísákà, Sébúlúnì àti Bẹ́ńjámínì;
4 Dánì àti Náfútálì; Gádì àti Áṣérì.+
5 Gbogbo ọmọ* tí wọ́n bí fún Jékọ́bù* jẹ́ àádọ́rin (70),* àmọ́ Jósẹ́fù ti wà ní Íjíbítì.+
6 Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù kú,+ gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran yẹn sì kú.
7 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* ń bímọ, wọ́n sì ń pọ̀ sí i, wọ́n ń bí sí i, wọ́n sì túbọ̀ ń lágbára gidigidi, débi pé wọ́n kún ilẹ̀ náà.+
8 Nígbà tó yá, ọba tuntun tí kò mọ Jósẹ́fù jẹ ní Íjíbítì.
9 Ó sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀ jù wá lọ, wọ́n sì tún lágbára jù wá lọ.+
10 Ẹ jẹ́ ká dọ́gbọ́n kan. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n á máa pọ̀ sí i. Tí ogun bá sì dé, wọ́n á dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti gbógun jà wá, wọ́n á sì kúrò nílùú.”
11 Wọ́n wá yan àwọn ọ̀gá* lé wọn lórí láti máa fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára.+ Wọ́n sì kọ́ àwọn ìlú tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí fún Fáráò. Orúkọ àwọn ìlú náà ni Pítómù àti Rámísésì.+
12 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ni wọ́n ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀rù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ń ba àwọn ará Íjíbítì gidigidi.+
13 Torí náà, àwọn ará Íjíbítì sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n gan-an.+
14 Wọ́n ni wọ́n lára gidigidi bí wọ́n ṣe ń mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekára, wọ́n ń fi àpòrọ́ alámọ̀ àti bíríkì ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń mú wọn ṣe onírúurú iṣẹ́ nínú oko bí ẹrú. Kódà, wọ́n lò wọ́n nílòkulò bí ẹrú láti ṣe onírúurú iṣẹ́ àṣekára.+
15 Lẹ́yìn náà, ọba Íjíbítì bá àwọn tó ń gbẹ̀bí àwọn Hébérù sọ̀rọ̀, orúkọ wọn ni Ṣífúrà àti Púà,
16 ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá ń gbẹ̀bí+ àwọn obìnrin Hébérù, tí wọ́n sì wà lórí àpótí ìbímọ, kí ẹ pa ọmọ náà tó bá jẹ́ ọkùnrin; àmọ́ kí ẹ dá ẹ̀mí rẹ̀ sí tó bá jẹ́ obìnrin.”
17 Àmọ́ àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, wọn ò sì ṣe ohun tí ọba Íjíbítì ní kí wọ́n ṣe. Ṣe ni wọ́n ń dá ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin sí.+
18 Nígbà tó yá, ọba Íjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó sì bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń dá ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin sí?”
19 Àwọn agbẹ̀bí náà sọ fún Fáráò pé: “Àwọn obìnrin Hébérù ò dà bí àwọn obìnrin Íjíbítì. Wọ́n lágbára, wọ́n sì ti máa ń bímọ kí agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”
20 Ọlọ́run wá ṣojúure sí àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn èèyàn náà ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń lágbára sí i.
21 Torí pé àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, ó fún wọn ní ìdílé tiwọn nígbà tó yá.
22 Fáráò wá pàṣẹ fún gbogbo èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ ju gbogbo ọmọkùnrin Hébérù tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sínú odò Náílì, àmọ́ kí ẹ dá ẹ̀mí gbogbo ọmọbìnrin sí.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “tó ti itan Jékọ́bù jáde.”
^ Tàbí “àádọ́rin ọkàn.”
^ Ní Héb., “Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
^ Tàbí “akóniṣiṣẹ́.”