Ẹ́kísódù 11:1-10
11 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ó ku ìyọnu kan tí màá mú wá sórí Fáráò àti Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, ó máa jẹ́ kí ẹ kúrò níbí.+ Ṣe ló máa lé yín kúrò níbí nígbà tó bá gbà pé kí ẹ máa lọ.+
2 Torí náà, sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí gbogbo ọkùnrin àti obìnrin béèrè àwọn nǹkan tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe lọ́wọ́ ọmọnìkejì wọn.”+
3 Jèhófà sì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà rí ojúure àwọn ará Íjíbítì. Mósè fúnra rẹ̀ ti wá di ẹni ńlá nílẹ̀ Íjíbítì lójú àwọn ìránṣẹ́ Fáráò àti àwọn èèyàn náà.
4 Mósè wá sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Tó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀gànjọ́ òru, màá lọ sí àárín Íjíbítì,+
5 gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì yóò sì kú,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹrúbìnrin tó ń lọ nǹkan lórí ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn.+
6 Igbe ẹkún máa pọ̀ gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí, irú ẹ̀ ò sì ní ṣẹlẹ̀ mọ́.+
7 Àmọ́, ajá ò tiẹ̀ ní gbó* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àti ẹran ọ̀sìn wọn, kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà lè fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’+
8 Ó dájú pé gbogbo ìránṣẹ́ rẹ yóò wá bá mi, wọ́n á wólẹ̀ fún mi, wọ́n á sì sọ pé, ‘Máa lọ, ìwọ àti gbogbo èèyàn tó ń tẹ̀ lé ọ.’+ Lẹ́yìn náà, èmi yóò lọ.” Ló bá fi ìbínú kúrò níwájú Fáráò.
9 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Fáráò ò ní fetí sí yín,+ kí iṣẹ́ ìyanu mi lè pọ̀ sí i nílẹ̀ Íjíbítì.”+
10 Mósè àti Áárónì ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu yìí níwájú Fáráò,+ àmọ́ Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “yọ ahọ́n sí.”