Ẹ́kísódù 20:1-26
20 Ọlọ́run wá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ó ní:+
2 “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+
3 O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.*+
4 “O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ tàbí kí o ṣe ohun* kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀.+
5 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n tàn ọ́ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,
6 àmọ́ tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi títí dé ẹgbẹ̀rún ìran wọn, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+
7 “O ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò tọ́,+ torí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tó bá lo orúkọ Rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́.+
8 “Máa rántí ọjọ́ Sábáàtì, kí o lè yà á sí mímọ́.+
9 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi ṣiṣẹ́, kí o sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,+
10 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.*+
11 Torí ọjọ́ mẹ́fà ni Jèhófà fi dá ọ̀run àti ayé, òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi ní ọjọ́ keje.+ Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bù kún ọjọ́ Sábáàtì, tó sì yà á sí mímọ́.
12 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,+ kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.+
13 “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.+
14 “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.+
15 “O ò gbọ́dọ̀ jalè.+
16 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ.+
17 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ilé ọmọnìkejì rẹ wọ̀ ọ́ lójú. Ojú rẹ ò sì gbọ́dọ̀ wọ ìyàwó ọmọnìkejì rẹ+ tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.”+
18 Gbogbo àwọn èèyàn náà ń rí ààrá tó ń sán àti mànàmáná tó ń kọ yẹ̀rì, wọ́n ń gbọ́ ìró ìwo, wọ́n sì ń rí òkè tó ń yọ èéfín; àwọn ohun tí wọ́n rí yìí bà wọ́n lẹ́rù, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n wá dúró ní òkèèrè.+
19 Torí náà, wọ́n sọ fún Mósè pé: “Ìwọ ni kí o máa bá wa sọ̀rọ̀, a ó sì fetí sílẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run bá wa sọ̀rọ̀ ká má bàa kú.”+
20 Mósè wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù, torí ṣe ni Ọlọ́run tòótọ́ wá dán yín wò,+ kí ẹ lè máa bẹ̀rù rẹ̀ kí ẹ má bàa ṣẹ̀.”+
21 Àwọn èèyàn náà ò kúrò ní ọ̀ọ́kán níbi tí wọ́n dúró sí, àmọ́ Mósè sún mọ́ ìkùukùu* tó ṣú dùdù náà níbi tí Ọlọ́run tòótọ́ wà.+
22 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, ‘Ẹ̀yin fúnra yín rí i pé láti ọ̀run ni mo ti bá yín sọ̀rọ̀.+
23 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run fàdákà láti máa sìn wọ́n pẹ̀lú mi, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run wúrà fún ara yín.+
24 Fi erùpẹ̀ mọ pẹpẹ fún mi, kí o sì rú àwọn ẹbọ sísun rẹ lórí rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀* rẹ, agbo ẹran rẹ àti ọ̀wọ́ ẹran rẹ. Gbogbo ibi tí mo bá ti mú kí wọ́n rántí orúkọ mi+ ni màá ti wá bá ọ, tí màá sì bù kún ọ.
25 Tí o bá fi òkúta ṣe pẹpẹ fún mi, o ò gbọ́dọ̀ lo òkúta tí o fi irinṣẹ́ gbẹ́.*+ Torí tí o bá lo irinṣẹ́* rẹ lára rẹ̀, wàá sọ ọ́ di aláìmọ́.
26 O ò sì gbọ́dọ̀ fi àtẹ̀gùn gun pẹpẹ mi, kí abẹ́* rẹ má bàa hàn lórí rẹ̀.’
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “láti fojú di mí.” Ní Héb., “níṣojú mi.”
^ Tàbí “àwòrán.”
^ Ní Héb., “tó wà ní ẹnubodè rẹ.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”
^ Tàbí “ẹbọ àlàáfíà.”
^ Tàbí “òkúta gbígbẹ́.”
^ Tàbí “ohun èlò tí a fi ń gbẹ́ igi tàbí òkúta.”
^ Ní Héb., “ìhòòhò.”