Ẹ́kísódù 24:1-18

  • Àwọn èèyàn gbà láti pa májẹ̀mú mọ́ (1-11)

  • Mósè lọ sórí Òkè Sínáì (12-18)

24  Ó wá sọ fún Mósè pé: “Kí ìwọ àti Áárónì gòkè lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, pẹ̀lú Nádábù àti Ábíhù+ àti àádọ́rin (70) nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì, kí ẹ sì tẹrí ba láti òkèèrè.  Mósè nìkan ni kó sún mọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà; kí àwọn tó kù má ṣe sún mọ́ ibẹ̀, kí àwọn èèyàn náà má sì bá a gòkè.”+  Lẹ́yìn náà, Mósè wá, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà àti gbogbo ìdájọ́ náà+ fún àwọn èèyàn, gbogbo àwọn èèyàn náà sì fohùn ṣọ̀kan, wọ́n fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe.”+  Mósè wá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà sílẹ̀.+ Ó dìde ní àárọ̀ kùtù, ó sì mọ pẹpẹ kan sísàlẹ̀ òkè náà àti òpó méjìlá (12) tó dúró fún ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.  Lẹ́yìn náà, ó rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì fi àwọn akọ màlúù rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ sí Jèhófà.  Mósè wá mú ìdajì lára ẹ̀jẹ̀ náà, ó dà á sínú àwọn abọ́, ó sì wọ́n ìdajì sórí pẹpẹ.  Lẹ́yìn náà, ó mú ìwé májẹ̀mú, ó kà á sókè fún àwọn èèyàn náà.+ Wọ́n sì sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe, a ó sì máa ṣègbọràn.”+  Mósè wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sára àwọn èèyàn náà,+ ó sì sọ pé: “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Jèhófà bá yín dá pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ yìí.”+  Mósè àti Áárónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin (70) nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá gòkè lọ, 10  wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ Ohun tó dà bíi pèpéle òkúta sàfáyà wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì mọ́ nigínnigín bí ọ̀run.+ 11  Kò pa àwọn èèyàn pàtàkì yìí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára,+ wọ́n sì rí ìran Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. 12  Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wá bá mi lórí òkè, kí o sì dúró síbẹ̀. Màá fún ọ ní àwọn wàláà òkúta tí èmi yóò kọ òfin àti àṣẹ sí láti fún àwọn èèyàn náà ní ìtọ́ni.”+ 13  Mósè gbéra pẹ̀lú Jóṣúà ìránṣẹ́ rẹ̀,+ Mósè sì lọ sórí òkè Ọlọ́run tòótọ́.+ 14  Àmọ́ ó ti sọ fún àwọn àgbààgbà náà pé: “Ẹ dúró dè wá níbí títí a ó fi pa dà wá bá yín.+ Áárónì àti Húrì+ wà pẹ̀lú yín. Tí ẹnikẹ́ni bá ní ẹjọ́, kó lọ bá wọn.”+ 15  Mósè wá lọ sórí òkè náà nígbà tí ìkùukùu* ṣì bo òkè náà.+ 16  Ògo Jèhófà+ ò kúrò lórí Òkè Sínáì,+ ìkùukùu náà sì bò ó fún ọjọ́ mẹ́fà. Ní ọjọ́ keje, ó pe Mósè látinú ìkùukùu náà. 17  Lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ògo Jèhófà rí bí iná tó ń jẹ nǹkan run lórí òkè náà. 18  Mósè wá wọ inú ìkùukùu náà, ó sì lọ sórí òkè náà.+ Mósè sì dúró lórí òkè náà fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọsánmà.”