Ẹ́kísódù 31:1-18

  • Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ kún inú àwọn oníṣẹ́ ọnà (1-11)

  • Sábáàtì jẹ́ àmì láàárín Ọlọ́run àti Ísírẹ́lì (12-17)

  • Wàláà òkúta méjì (18)

31  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé:  “Wò ó, mo ti yan* Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà.+  Màá fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀, màá fún un ní ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ọnà,  kó lè ṣe iṣẹ́ ọnà ayàwòrán, kó lè fi wúrà, fàdákà àti bàbà ṣiṣẹ́,  kó lè gé òkúta, kó sì tò ó,+ kó sì lè fi igi ṣe onírúurú nǹkan.+  Bákan náà, mo ti yan Òhólíábù  + ọmọ Áhísámákì látinú ẹ̀yà Dánì kó lè ràn án lọ́wọ́, màá sì fi ọgbọ́n sínú ọkàn gbogbo àwọn tó mọṣẹ́,* kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ:+  àgọ́ ìpàdé,+ àpótí Ẹ̀rí+ àti ìbòrí rẹ̀,+ gbogbo ohun èlò àgọ́ náà,  tábìlì+ àti àwọn ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,+ pẹpẹ tùràrí,+  pẹpẹ ẹbọ sísun+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀,+ 10  àwọn aṣọ tí wọ́n hun dáadáa, aṣọ mímọ́ ti àlùfáà Áárónì, aṣọ tí àwọn ọmọ rẹ̀ máa fi ṣiṣẹ́ àlùfáà,+ 11  òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà fún ibi mímọ́.+ Kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.” 12  Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 13  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ pa àwọn sábáàtì mi mọ́,+ torí ó jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin ní ìrandíran yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń sọ yín di mímọ́. 14  Kí ẹ pa Sábáàtì mọ́, torí ohun mímọ́ ló jẹ́ fún yín.+ Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá sọ ọ́ di aláìmọ́. Tí ẹnikẹ́ni bá ṣiṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà, kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò nínú àwọn èèyàn rẹ̀.+ 15  Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá.+ Ohun mímọ́ ló jẹ́ fún Jèhófà. Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ Sábáàtì. 16  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ pa Sábáàtì mọ́; wọ́n gbọ́dọ̀ máa pa Sábáàtì mọ́ jálẹ̀ gbogbo ìran wọn. Májẹ̀mú tó máa wà títí lọ ni. 17  Ó jẹ́ àmì tó máa wà pẹ́ títí láàárín èmi àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ torí ọjọ́ mẹ́fà ni Jèhófà fi dá ọ̀run àti ayé, ó wá sinmi ní ọjọ́ keje, ara sì tù ú.’”+ 18  Gbàrà tó bá a sọ̀rọ̀ tán lórí Òkè Sínáì, ó fún Mósè ní wàláà Ẹ̀rí méjì,+ àwọn wàláà òkúta tí ìka Ọlọ́run+ kọ̀wé sí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “fi orúkọ pe.”
Ní Héb., “jẹ́ ọlọgbọ́n ní ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”