Ẹ́kísódù 35:1-35

  • Àwọn ìtọ́ni Sábáàtì (1-3)

  • Ọrẹ àgọ́ ìjọsìn (4-29)

  • Ọlọ́run fi ẹ̀mí kún inú Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù (30-35)

35  Lẹ́yìn náà, Mósè pe gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa pọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé ká ṣe nìyí:+  Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ọjọ́ keje jẹ́ mímọ́ fún yín. Kí ọjọ́ náà jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá.+ Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ náà.+  Ní ọjọ́ Sábáàtì, ẹ ò gbọ́dọ̀ dá iná ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé.”  Mósè tún sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nìyí,  ‘Kí ẹ gba ọrẹ fún Jèhófà láàárín ara yín.+ Kí gbogbo ẹni tó bá wù látọkàn wá+ mú ọrẹ wá fún Jèhófà: wúrà, fàdákà, bàbà,  fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, irun ewúrẹ́,+  awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa, awọ séálì, igi bọn-ọ̀n-ní,  òróró fìtílà, òróró básámù tí wọ́n á fi ṣe òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà,+  àwọn òkúta ónísì àti àwọn òkúta míì tí wọ́n máa tò sára éfódì+ àti aṣọ ìgbàyà.+ 10  “‘Kí gbogbo àwọn tó mọṣẹ́*+ láàárín yín wá ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ, 11  ìyẹn, àgọ́ ìjọsìn pẹ̀lú àgọ́ rẹ̀ àti ìbòrí rẹ̀, àwọn ìkọ́ àti àwọn férémù rẹ̀, àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀; 12  Àpótí náà+ àti àwọn ọ̀pá rẹ̀,+ ìbòrí+ àti aṣọ+ tí wọ́n á ta síbẹ̀; 13  tábìlì+ àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti búrẹ́dì àfihàn;+ 14  ọ̀pá fìtílà+ tí wọ́n á máa fi tan iná àti àwọn ohun èlò rẹ̀ àti àwọn fìtílà rẹ̀ àti òróró láti máa fi tan iná;+ 15  pẹpẹ tùràrí+ àti àwọn ọ̀pá rẹ̀; òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà;+ aṣọ* tó máa wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn; 16  pẹpẹ ẹbọ sísun+ àti àgbàyan* tí ẹ ó fi bàbà ṣe, àwọn ọ̀pá rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀;+ 17  àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí àgbàlá,+ àwọn òpó rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀; aṣọ* tó máa wà ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá; 18  àwọn èèkàn àgọ́ ìjọsìn àtàwọn èèkàn àgbàlá pẹ̀lú àwọn okùn wọn;+ 19  àwọn aṣọ tí wọ́n hun dáadáa+ láti máa fi ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ ti àlùfáà Áárónì+ àti aṣọ tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa fi ṣiṣẹ́ àlùfáà.’” 20  Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kúrò níwájú Mósè. 21  Gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ sún un+ tó sì tinú rẹ̀ wá láti ṣe ọrẹ mú ọrẹ wá fún Jèhófà, ọrẹ tí wọ́n á fi ṣe àgọ́ ìpàdé, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn aṣọ mímọ́ náà. 22  Wọ́n ń wá ṣáá, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kálukú ń wá láti ṣe ọrẹ látọkàn wá, wọ́n mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n ń so mọ́ aṣọ wá, pẹ̀lú yẹtí, òrùka àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ míì, pẹ̀lú onírúurú ohun èlò wúrà. Gbogbo wọn mú ọrẹ* wúrà wá fún Jèhófà.+ 23  Gbogbo àwọn tó ní fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò sì mú wọn wá, pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa, irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa àti awọ séálì. 24  Gbogbo àwọn tó ń fi fàdákà àti bàbà ṣe ọrẹ mú un wá fún Jèhófà, gbogbo àwọn tó sì ní igi bọn-ọ̀n-ní tó ṣeé lò fún èyíkéyìí nínú iṣẹ́ náà mú un wá. 25  Gbogbo àwọn obìnrin tó mọṣẹ́+ fi ọwọ́ wọn rànwú, wọ́n sì mú àwọn ohun tí wọ́n ṣe wá: fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa. 26  Gbogbo obìnrin tó mọṣẹ́, tí ọkàn wọn sún wọn sì ran irun ewúrẹ́. 27  Àwọn ìjòyè náà mú àwọn òkúta ónísì wá àti àwọn òkúta míì tí wọ́n máa tò sára éfódì àti aṣọ ìgbàyà,+ 28  pẹ̀lú òróró básámù àti òróró tí wọ́n á máa fi tan iná, òróró tí wọ́n á fi ṣe òróró àfiyanni+ àti tùràrí onílọ́fínńdà.+ 29  Gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí ọkàn wọn sún wọn mú ohun kan wá fún iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọ́n ṣe; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọrẹ àtinúwá wá fún Jèhófà.+ 30  Mósè wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ wò ó, Jèhófà ti yan Bẹ́sálẹ́lì ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà.+ 31  Ó ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀, ó fún un ní ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ọnà, 32  kó lè ṣe iṣẹ́ ọnà ayàwòrán, kó lè fi wúrà, fàdákà àti bàbà ṣiṣẹ́, 33  kó lè gé òkúta, kó sì tò ó, kó sì lè fi igi ṣe onírúurú iṣẹ́ ọnà. 34  Ó sì ti fi sínú ọkàn rẹ̀ láti máa kọ́ni, òun àti Òhólíábù+ ọmọ Áhísámákì látinú ẹ̀yà Dánì. 35  Ó ti mú kí wọ́n ní ìmọ̀*+ láti ṣe gbogbo iṣẹ́ ọnà, láti kó iṣẹ́ sára aṣọ, láti fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe iṣẹ́ ọnà sí aṣọ, kí wọ́n sì máa hun aṣọ. Àwọn ọkùnrin yìí máa ṣe onírúurú iṣẹ́, wọ́n á sì ṣètò onírúurú iṣẹ́ ọnà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ní Héb., “jẹ́ ọlọgbọ́n ní ọkàn.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “ayanran.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “ọrẹ fífì.”
Ní Héb., “gbọ́n ní ọkàn.”