Ẹ́kísódù 7:1-25
7 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Wò ó, mo ti mú kí o dà bí Ọlọ́run* fún Fáráò, Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ yóò sì di wòlíì rẹ.+
2 Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ, Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ ló máa bá Fáráò sọ̀rọ̀, á sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.
3 Ní tèmi, màá jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ màá sì ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
4 Àmọ́ Fáráò ò ní fetí sí yín. Ọwọ́ mi yóò tẹ Íjíbítì, màá sì fi ìdájọ́ tó rinlẹ̀ mú ogunlọ́gọ̀ mi,* ìyẹn àwọn èèyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní ilẹ̀ náà.+
5 Ó sì dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nígbà tí mo bá na ọwọ́ mi láti bá Íjíbítì jà, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò láàárín wọn.”
6 Mósè àti Áárónì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
7 Ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni Mósè, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83) sì ni Áárónì nígbà tí wọ́n bá Fáráò sọ̀rọ̀.+
8 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé:
9 “Tí Fáráò bá sọ fún yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu,’ kí o sọ fún Áárónì pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ, kí o sì jù ú sílẹ̀ níwájú Fáráò.’ Ọ̀pá náà yóò di ejò ńlá.”+
10 Mósè àti Áárónì wọlé lọ bá Fáráò, wọ́n sì ṣe ohun tí Jèhófà pàṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. Áárónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò ńlá.
11 Ni Fáráò bá ránṣẹ́ pe àwọn amòye àti àwọn oníṣẹ́ oṣó. Àwọn àlùfáà onídán ní Íjíbítì+ pẹ̀lú sì fi agbára* wọn ṣe ohun kan náà.+
12 Kálukú wọn ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, àwọn ọ̀pá náà sì di ejò ńlá; àmọ́ ọ̀pá Áárónì gbé àwọn ọ̀pá wọn mì.
13 Síbẹ̀, ọkàn Fáráò le,+ kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.
14 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Fáráò ò yí ọkàn rẹ̀ pa dà.+ Kò gbà kí àwọn èèyàn náà lọ.
15 Lọ bá Fáráò ní àárọ̀. Wò ó! Ó ń lọ sí odò! Kí o lọ dúró sétí odò Náílì láti pàdé rẹ̀, kí o sì mú ọ̀pá tó di ejò náà dání.+
16 Kí o sọ fún un pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù rán mi sí ọ,+ ó ní: “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ kí wọ́n lè lọ sìn mí ní aginjù,” àmọ́ o ò gbọ́ tèmi títí di báyìí.
17 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun tí wàá fi mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nìyí. Màá fi ọ̀pá ọwọ́ mi lu omi odò Náílì, á sì di ẹ̀jẹ̀.
18 Àwọn ẹja inú odò Náílì yóò kú, odò Náílì yóò máa rùn, àwọn ará Íjíbítì ò sì ní lè mu omi odò Náílì rárá.”’”
19 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ, kí o sì na ọwọ́ rẹ sórí omi Íjíbítì,+ sórí àwọn odò rẹ̀, àwọn omi tó ń ṣàn láti ibẹ̀,* àwọn irà rẹ̀+ àti gbogbo adágún omi rẹ̀, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀.’ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, títí kan inú àwọn ọpọ́n onígi àtèyí tí wọ́n fi òkúta ṣe.”
20 Lójú ẹsẹ̀, Mósè àti Áárónì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ gẹ́lẹ́. Ó na ọ̀pá náà sókè, ó sì fi lu omi odò Náílì níṣojú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, gbogbo omi odò náà sì di ẹ̀jẹ̀.+
21 Àwọn ẹja inú odò náà kú,+ odò náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rùn, àwọn ará Íjíbítì kò wá lè mu omi odò Náílì,+ ẹ̀jẹ̀ sì wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.
22 Síbẹ̀, àwọn àlùfáà onídán ní Íjíbítì fi agbára òkùnkùn wọn ṣe ohun kan náà,+ ìyẹn sì mú kí ọkàn Fáráò túbọ̀ le, kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.+
23 Fáráò wá pa dà sí ilé rẹ̀, kò sì ka ọ̀rọ̀ yìí sí pẹ̀lú.
24 Gbogbo àwọn ará Íjíbítì wá ń gbẹ́lẹ̀ kiri yí odò Náílì ká kí wọ́n lè rí omi mu, torí wọn ò lè mu omi odò Náílì rárá.
25 Ọjọ́ méje gbáko sì kọjá lẹ́yìn tí Jèhófà lu odò Náílì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “fi ọ́ ṣe Ọlọ́run.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun mi.”
^ Tàbí “agbára idán.”
^ Ìyẹn, omi tó ń ṣàn láti odò Náílì.