Ẹ́sírà 9:1-15

  • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ ilẹ̀ míì ń fẹ́ ara wọn (1-4)

  • Àdúrà ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí Ẹ́sírà gbà (5-15)

9  Gbàrà tí a parí àwọn nǹkan yìí, àwọn olórí wá bá mi, wọ́n sì sọ pé: “Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn àwọn ilẹ̀ tó yí wọn ká àti àwọn ohun ìríra wọn,+ ìyẹn àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì, àwọn ọmọ Ámónì, àwọn ọmọ Móábù, àwọn ará Íjíbítì+ àti àwọn Ámórì. +  Wọ́n ti fi lára àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya, wọ́n sì tún fẹ́ wọn fún àwọn ọmọkùnrin wọn.+ Ní báyìí, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ* mímọ́+ ti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn àwọn ilẹ̀ tó yí wọn ká.+ Àwọn olórí àti àwọn alábòójútó sì ni òléwájú nínú ìwà àìṣòótọ́ yìí.”  Bí mo ṣe gbọ́ nípa nǹkan yìí, mo fa ẹ̀wù mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá ya, mo fa lára irun orí mi àti irùngbọ̀n mi tu, mo jókòó, kàyéfì ńlá sì ń ṣe mí.  Nígbà náà, gbogbo àwọn tó ní ọ̀wọ̀ fún* ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì kóra jọ sọ́dọ̀ mi nítorí ìwà àìṣòótọ́ àwọn tó dé láti ìgbèkùn, mo wà ní ìjókòó, kàyéfì ńlá sì ń ṣe mí títí di ìgbà ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́.+  Nígbà tí àkókò ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́+ tó, mo dìde nínú ìtìjú tó bá mi, tèmi ti ẹ̀wù mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá tó ti ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run mi.  Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an lórí wa, ẹ̀bi wa sì ti ga dé ọ̀run.+  Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá wa ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ gan-an títí di òní yìí;+ tìtorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ni o ṣe fi àwa, àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa lé àwọn ọba ilẹ̀ míì lọ́wọ́, tí wọ́n fi idà pa wá,+ tí wọ́n kó wa lọ sóko ẹrú,+ tí wọ́n kó ohun ìní wa,+ tí wọ́n sì dójú tì wá bó ṣe rí lónìí yìí.+  Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa ti ṣojú rere sí wa fún ìgbà díẹ̀, o ti jẹ́ kí àwọn tó ṣẹ́ kù sá àsálà, o sì ti fún wa ní ibi ààbò* nínú ibi mímọ́ rẹ,+ láti mú kí ojú wa máa dán àti láti gbé wa dìde díẹ̀ nínú ipò ẹrú tí a wà, ìwọ Ọlọ́run wa.  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹrú ni wá,+ Ọlọ́run wa kò fi wá sílẹ̀ nínú ipò ẹrú tí a wà; àmọ́ ó ti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa níwájú àwọn ọba Páṣíà,+ láti gbé wa dìde kí a lè kọ́ ilé Ọlọ́run wa,+ kí a sì tún àwọn ibi tó ti di àwókù ṣe, kí ó sì fún wa ní odi ààbò* ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù. 10  “Lẹ́yìn gbogbo èyí, kí la tún fẹ́ sọ, ìwọ Ọlọ́run wa? Nítorí a ti pa àwọn àṣẹ rẹ tì, 11  èyí tí o fún wa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wòlíì pé: ‘Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà jẹ́ ilẹ̀ àìmọ́ nítorí ìwà àìmọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n fi kún ilẹ̀ náà láti ìpẹ̀kun kan dé èkejì nípasẹ̀ ìwà àìmọ́ wọn.+ 12  Torí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn, ẹ má sì gba àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín;+ ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun láti wá àlàáfíà tàbí aásìkí fún wọn,+ kí ẹ lè di alágbára, kí ẹ sì máa gbádùn àwọn ohun rere ilẹ̀ náà àti pé kí ẹ lè gbà á fún àwọn ọmọ yín títí láé.’ 13  Lẹ́yìn gbogbo ohun tó dé bá wa nítorí ìwà burúkú wa àti ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí a dá, ìwọ Ọlọ́run wa kò fi ìyà tó tọ́ sí wa jẹ wá nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ o sì ti jẹ́ kí àwa tí a wà níbí sá àsálà,+ 14  ǹjẹ́ ó yẹ ká tún máa tẹ àwọn àṣẹ rẹ lójú, ká sì máa bá àwọn èèyàn tó ń ṣe ohun ìríra dána?*+ Ṣé o kò ní bínú sí wa tí wàá fi pa wá run pátápátá tí ẹnì kankan kò fi ní ṣẹ́ kù tàbí yè bọ́? 15  Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, olódodo ni ọ́,+ nítorí àwa tí a yè bọ́ ti ṣẹ́ kù títí di òní yìí. Àwa rèé níwájú rẹ nínú ẹ̀bi wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tó ẹni tó lè dúró níwájú rẹ nítorí èyí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “tó bẹ̀rù.”
Ní Héb., “èèkàn kan.”
Ní Héb., “ògiri olókùúta.”
Tàbí “kí àwa àti àwọn tó ń ṣe ohun ìríra máa fẹ́ ara wa.”