Ẹ́sítà 10:1-3

  • Módékáì di ẹni ńlá (1-3)

10  Ọba Ahasuérúsì gbé iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún àwọn èèyàn tó ń gbé ilẹ̀ náà àti àwọn erékùṣù òkun.  Ní ti gbogbo ohun tó fi agbára àti okun rẹ̀ gbé ṣe, títí kan kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ipò gíga tí ọba gbé Módékáì+ sí,+ ǹjẹ́ wọn kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn àkókò+ àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà?+  Módékáì tó jẹ́ Júù ni igbá kejì Ọba Ahasuérúsì. Ẹni ńlá ni* láàárín àwọn Júù, gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ ló sì ń bọ̀wọ̀ fún un, ó ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń jà fún ire* gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ó gbayì gan-an.”
Ní Héb., “ó ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún.”