Émọ́sì 1:1-15

  • Émọ́sì gba iṣẹ́ kan látọ̀dọ̀ Jèhófà (1, 2)

  • Ìdájọ́ lórí ìdìtẹ̀ tó ń wáyé (3-15)

1  Ọ̀rọ̀ Émọ́sì,* ọ̀kan lára àwọn tó ń sin àgùntàn láti Tékóà,+ èyí tó gbọ́ nínú ìran nípa Ísírẹ́lì nígbà ayé Ùsáyà+ ọba Júdà àti nígbà ayé Jèróbóámù+ ọmọ Jóáṣì,+ ọba Ísírẹ́lì, ní ọdún méjì ṣáájú ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé.+  Ó sọ pé: “Jèhófà yóò ké ramúramù láti Síónì,Yóò sì gbé ohùn rẹ̀ sókè láti Jerúsálẹ́mù. Ibi ìjẹko àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ṣọ̀fọ̀,Ewéko orí òkè Kámẹ́lì á sì gbẹ dà nù.”+   “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,‘“Nítorí ìdìtẹ̀* mẹ́ta Damásíkù àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,Nítorí wọ́n fi ohun èlò ìpakà onírin pa Gílíádì bí ọkà.+   Torí náà, màá rán iná sí ilé Hásáẹ́lì,+Á sì jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ti Bẹni-hádádì run.+   Màá ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè Damásíkù;+Màá sì pa àwọn tó ń gbé Bikati-áfénì runÀti àwọn tó ń ṣàkóso* ní Bẹti-édẹ́nì;Àwọn èèyàn Síríà sì máa lọ sí ìgbèkùn ní Kírì,”+ ni Jèhófà wí.’   Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,‘“Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Gásà+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,Nítorí wọ́n kó gbogbo àwọn èèyàn nígbèkùn,+ wọ́n sì fà wọ́n lé Édómù lọ́wọ́.   Torí náà, màá rán iná sí ògiri Gásà,+Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.   Màá pa àwọn tó ń gbé Áṣídódì run,+Àti àwọn tó ń ṣàkóso* ní Áṣíkẹ́lónì;+Màá fìyà jẹ Ẹ́kírónì,+Àwọn Filísínì tó ṣẹ́ kù yóò sì ṣègbé,”+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’   Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Tírè+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,Nítorí wọ́n kó gbogbo àwọn tí wọ́n mú nígbèkùn, wọ́n sì fà wọ́n lé Édómù lọ́wọ́,Àti nítorí pé wọn kò rántí májẹ̀mú àwọn arákùnrin.+ 10  Torí náà, màá rán iná sí ògiri Tírè,Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.’+ 11  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Édómù+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,Nítorí ó fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,+Àti nítorí pé ó kọ̀ láti ṣàánú rẹ̀;Ó ń fi ìbínú rẹ̀ fà wọ́n ya láìdáwọ́ dúró,Kò sì yéé bínú sí wọn.+ 12  Torí náà, màá rán iná sí Témánì,+Á sì jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ti Bósírà run.’+ 13  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,‘“Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta àwọn ọmọ Ámónì+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,Nítorí wọ́n la inú àwọn aboyún Gílíádì kí wọ́n lè mú agbègbè tiwọn fẹ̀ sí i.+ 14  Torí náà, màá sọ iná sí ògiri Rábà,+Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run,Ariwo á sọ ní ọjọ́ ogun,Àti ìjì líle ní ọjọ́ ẹ̀fúùfù. 15  Ọba wọn á sì lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.’

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Ẹrù” tàbí “Gbé Ẹrù.”
Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”
Ní Héb., “àwọn tó ń di ọ̀pá àṣẹ mú.”
Ní Héb., “àwọn tó ń di ọ̀pá àṣẹ mú.”