Émọ́sì 5:1-27
5 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí màá fi orin arò* sọ fún yín, ilé Ísírẹ́lì:
2 ‘Wúńdíá náà, Ísírẹ́lì, ti ṣubú;Kò lè dìde mọ́.
Wọ́n ti pa á tì sórí ilẹ̀ rẹ̀;Kò sí ẹnì kankan tó máa gbé e dìde.’
3 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Ìlú tó ń jáde lọ sí ogun pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún (1,000) máa ṣẹ́ ku ọgọ́rùn-ún (100);Èyí tó sì ń jáde lọ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún (100) máa ṣẹ́ ku mẹ́wàá fún ilé Ísírẹ́lì.’+
4 “Ohun tí Jèhófà sọ fún ilé Ísírẹ́lì nìyí:
‘Wá mi, kí o lè máa wà láàyè.+
5 Ẹ má ṣe wá Bẹ́tẹ́lì kiri,+Ẹ má lọ sí Gílígálì,+ ẹ má sì kọjá sí Bíá-ṣébà,+Torí ó dájú pé Gílígálì máa lọ sí ìgbèkùn,+Bẹ́tẹ́lì á sì di asán.*
6 Wá Jèhófà, kí o lè máa wà láàyè,+Kó má bàa bú jáde bí iná sórí ilé Jósẹ́fù,Kó má bàa jó Bẹ́tẹ́lì run láìsí ẹni tó máa pa iná náà.
7 Ẹ sọ ìdájọ́ òdodo di iwọ,*Ẹ sì tẹ òdodo mọ́lẹ̀.+
8 Ẹni tó dá àgbájọ ìràwọ̀ Kímà* àti àgbájọ ìràwọ̀ Késílì,*+Ẹni tó ń sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,Ẹni tó ń mú kí ọ̀sán ṣókùnkùn bí òru,+Ẹni tó ń wọ́ omi jọ látinú òkunKí ó lè dà á sórí ilẹ̀,+Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.
9 Á mú kí ìparun dé bá alágbára lójijì,Á sì mú kí àwọn ibi olódi pa run.
10 Wọ́n kórìíra àwọn tó ń báni wí ní ẹnubodè ìlú,Wọ́n sì kórìíra àwọn tó ń sọ òtítọ́.+
11 Nítorí pé ẹ̀ ń gba owó oko* lọ́wọ́ àwọn aláìní tí ẹ gbé oko fúnẸ sì ń gba ọkà lọ́wọ́ wọn bí ìṣákọ́lẹ̀,*+Ẹ kò ní máa gbé inú àwọn ilé tí ẹ fi òkúta gbígbẹ́ kọ́+Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní máa mu wáìnì àwọn ọgbà àjàrà dáradára tí ẹ gbìn.+
12 Nítorí mo mọ bí ìdìtẹ̀* yín ṣe pọ̀ tóÀti bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ṣe pọ̀ tóẸ̀ ń dààmú àwọn olódodo,Ẹ̀ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,*Ẹ sì ń fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n ní ẹnubodè.+
13 Torí náà, àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò yẹn,Nítorí ó máa jẹ́ àkókò àjálù.+
14 Ẹ máa wá ohun rere, ẹ má ṣe wá ohun búburú,+Kí ẹ lè máa wà láàyè.+
Nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun á lè wà pẹ̀lú yín,Bí ẹ ti sọ pé ó wà pẹ̀lú yín.+
15 Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere,+Ẹ jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ ní ẹnubodè ìlú.+
Bóyá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogunMáa fi ojúure hàn sí àwọn tó ṣẹ́ kù lára Jósẹ́fù.’+
16 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, àní Jèhófà sọ nìyí:
‘Ìpohùnréré ẹkún máa wà ní gbogbo ojúde ìlú,Àti ní gbogbo ojú ọ̀nà, àwọn èèyàn á máa sọ pé, “Áà, ó mà ṣe o!”
Wọ́n á pe àwọn àgbẹ̀ pé kí wọ́n wá ṣọ̀fọ̀Àti àwọn tó ń fi ẹkún sísun ṣiṣẹ́ ṣe láti pohùn réré ẹkún.’
17 ‘Ìpohùnréré ẹkún máa wà ní gbogbo ọgbà àjàrà;+Nítorí màá la àárín rẹ kọjá,’ ni Jèhófà wí.
18 ‘Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ kí ọjọ́ Jèhófà dé, ẹ gbé!+
Àǹfààní wo wá ni ọjọ́ Jèhófà máa ṣe yín?+
Òkùnkùn ló máa jẹ́, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀.+
19 Ńṣe ló máa dà bí ọkùnrin kan tó ń sá fún kìnnìún, tó wá pàdé bíárì,Nígbà tó wọ ilé rẹ̀, tó fi ọwọ́ ti ògiri, ejò bù ú ṣán.
20 Ọjọ́ Jèhófà máa jẹ́ òkùnkùn, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀;Ó máa jẹ́ ìṣúdùdù, kì í ṣe ìtànyòò.
21 Mo kórìíra àwọn àjọyọ̀ yín, mo sì kọ̀ wọ́n,+Inú mi ò dùn sí òórùn àwọn àpéjọ ọlọ́wọ̀ yín.
22 Kódà bí ẹ tiẹ̀ rú odindi ẹbọ sísun, tí ẹ sì fún mi ní ẹ̀bùn,Inú mi ò ní dùn sí ọrẹ wọ̀nyẹn;+Mi ò sì ní fi ojúure wo àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tí ẹ fi ẹran àbọ́sanra rú.+
23 Gbé ariwo orin rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi;Má sì jẹ́ kí n gbọ́ ìró ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín rẹ.+
24 Jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣàn wálẹ̀ bí omi,+Àti òdodo bí odò tó ń ṣàn nígbà gbogbo.
25 Ǹjẹ́ ẹ mú ẹbọ àti ọrẹ wá fún miNí gbogbo ogójì (40) ọdún tí ẹ fi wà ní aginjù, ilé Ísírẹ́lì?+
26 Ní báyìí, ẹ ó gbé Sákútì ọba yín àti Káíwánì kúrò,*Àwọn ère yín, ìràwọ̀ ọlọ́run yín, tí ẹ ṣe fún ara yín,
27 Màá sì rán yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damásíkù,’+ ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ohun abàmì.”
^ Tàbí “ìkorò.”
^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Óríónì.
^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ìràwọ̀ Píláédì tó wà nínú àgbájọ ìràwọ̀ Tọ́rọ́sì.
^ Tàbí “owó ilẹ̀.”
^ Tàbí “owó òde.”
^ Tàbí “owó mẹ́numọ́.”
^ Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”
^ Ó ṣeé ṣe kí àwọn òrìṣà méjèèjì yìí máa tọ́ka sí pílánẹ́ẹ̀tì Sátọ̀n tí wọ́n ń sìn bí ọlọ́run.