Émọ́sì 9:1-15
9 Mo rí i tí Jèhófà+ dúró lókè pẹpẹ, ó sì sọ pé: “Lu orí òpó, àwọn ibi àbáwọlé á sì mì jìgìjìgì. Gé orí wọn kúrò, màá sì fi idà pa èyí tó gbẹ̀yìn lára wọn. Kò sí ẹnì kankan lára wọn tó máa lè sá lọ tàbí tó máa sá àsálà.+
2 Bí wọ́n bá walẹ̀ lọ sínú Isà Òkú,*Ibẹ̀ ni ọwọ́ mi á ti tẹ̀ wọ́n;Bí wọ́n bá sì gòkè lọ sí ọ̀run,Ibẹ̀ ni màá ti fà wọ́n sọ̀ kalẹ̀.
3 Bí wọ́n bá fara pa mọ́ sórí òkè Kámẹ́lì,Ibẹ̀ ni màá ti wá wọn kàn, màá sì mú wọn.+
Bí wọ́n bá sì fara pa mọ́ kúrò ní ojú mi ní ìsàlẹ̀ òkun,Ibẹ̀ ni màá ti pàṣẹ fún ejò, á sì bù wọ́n ṣán.
4 Bí àwọn ọ̀tá bá kó wọn lọ sí oko ẹrú,Ibẹ̀ ni màá ti pàṣẹ fún idà, yóò sì pa wọ́n;+Màá dájú sọ wọ́n, kì í ṣe fún ire, bí kò ṣe fún ibi.+
5 Nítorí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni tó fọwọ́ kan ilẹ̀ náà,*Kí ó lè yọ́,+ kí gbogbo àwọn tó ń gbé lórí rẹ̀ sì ṣọ̀fọ̀;+Gbogbo rẹ̀ á ru sókè bí odò Náílì,Á sì rọlẹ̀ bí odò Náílì Íjíbítì.+
6 ‘Ẹni tó ṣe àwọn àtẹ̀gùn Rẹ̀ lọ sí ọ̀run,Tó sì dá àwọn nǹkan sí òkè ayé;Ẹni tó ń wọ́ omi jọ látinú òkun,Kí ó lè dà á sórí ilẹ̀,+Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.’+
7 ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe bí àwọn ọmọ Kúṣì lẹ jẹ́ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì?’ ni Jèhófà wí.
‘Ṣé mi ò mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì+Àti àwọn Filísínì kúrò ní Kírétè+ àti Síríà kúrò ní Kírì?’+
8 ‘Wò ó! Ojú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára ìjọba tó ń dẹ́ṣẹ̀,Á sì pa á rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀.+
Ṣùgbọ́n, mi ò ní pa gbogbo ilé Jékọ́bù rẹ́,’+ ni Jèhófà wí.
9 ‘Wò ó! Mò ń pàṣẹ,Màá mi ilé Ísírẹ́lì jìgìjìgì láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè,+Bí èèyàn ṣe ń mi ajọ̀ jìgìjìgì,Tí òkúta róbótó kankan kò sì ní bọ́ sílẹ̀.
10 Idà ni yóò pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó wà nínú àwọn èèyàn mi,Àwọn tó ń sọ pé, “Àjálù kò ní sún mọ́ wa tàbí kó dé ọ̀dọ̀ wa.”’
11 ‘Ní ọjọ́ yẹn, màá gbé àtíbàbà* Dáfídì+ tó ti wó dìde,Màá sì tún àwọn àlàfo rẹ̀* ṣe,Màá tún àwókù rẹ̀ kọ́;Màá tún un kọ́, á sì rí bíi ti tẹ́lẹ̀,+
12 Kí wọ́n lè gba ohun tó ṣẹ́ kù nínú Édómù,+Àti ohun tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a fi orúkọ mi pè,’ ni Jèhófà, ẹni tó ń ṣe nǹkan yìí wí.
13 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí,‘Nígbà tí atúlẹ̀ máa lé olùkórè bá,Tí ẹni tó ń fẹsẹ̀ tẹ èso àjàrà á sì lé ẹni tó gbé irúgbìn bá;+Tí wáìnì dídùn á máa kán tótó láti ara àwọn òkè ńlá,+Tí á sì máa ṣàn jáde* lára gbogbo àwọn òkè kéékèèké.+
14 Màá kó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì tó wà ní ìgbèkùn pa dà,+Wọ́n á tún àwọn ìlú tó ti di ahoro kọ́, wọ́n á sì máa gbé inú wọn;+Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n á sì mu wáìnì wọn,+Wọ́n á ṣe ọgbà, wọ́n á sì jẹ èso wọn.’+
15 ‘Màá gbìn wọ́n sórí ilẹ̀ wọn,A kò sì ní fà wọ́n tu mọ́Kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ wí.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ayé.”
^ Tàbí “àgọ́; ahéré.”
^ Tàbí “wọn.”
^ Ní Héb., “máa yọ́.”