Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 20:1-38
20 Nígbà tí rúkèrúdò náà rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, lẹ́yìn tó fún wọn ní ìṣírí, tó sì dágbére fún wọn, ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Makedóníà.
2 Lẹ́yìn tó gba àwọn agbègbè náà kọjá, tó sì ń fún àwọn tó wà níbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìṣírí, ó dé ilẹ̀ Gíríìsì.
3 Ó lo oṣù mẹ́ta níbẹ̀, àmọ́ torí pé àwọn Júù+ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á nígbà tó fẹ́ wọkọ̀ lọ sí Síríà, ó pinnu pé òun á gba Makedóníà pa dà.
4 Àwọn tó bá a lọ ni Sópátérì ọmọ Párù ará Bèróà, Àrísítákọ́sì+ àti Sẹ́kúńdù láti Tẹsalóníkà, Gáyọ́sì ará Déébè, Tímótì+ pẹ̀lú Tíkíkù+ àti Tírófímù+ láti ìpínlẹ̀ Éṣíà.
5 Àwọn ọkùnrin yìí lọ ṣáájú wa, wọ́n sì dúró dè wá ní Tíróásì;
6 àmọ́ a wọkọ̀ òkun láti ìlú Fílípì lẹ́yìn àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ láàárín ọjọ́ márùn-ún, a dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróásì, a sì lo ọjọ́ méje níbẹ̀.
7 Ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, nígbà tí a kóra jọ láti jẹun, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀, torí pé ọjọ́ kejì ló máa kúrò níbẹ̀; ó sì sọ̀rọ̀ títí di ọ̀gànjọ́ òru.
8 Àwọn fìtílà mélòó kan wà ní yàrá òkè tí a kóra jọ sí.
9 Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì jókòó sójú fèrèsé,* ó sùn lọ fọnfọn nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, oorun ti gbé e lọ, ló bá ṣubú láti àjà kẹta, ó sì ti kú nígbà tí wọ́n fi máa gbé e.
10 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù lọ sísàlẹ̀, ó dùbúlẹ̀ lé e, ó sì gbá a mọ́ra,+ ó sọ pé: “Ẹ dákẹ́ ariwo, torí ó ti jí.”*+
11 Lẹ́yìn náà, ó gòkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì lọ, ó bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ,* ó sì ń jẹun. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí ilẹ̀ fi mọ́, lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀.
12 Torí náà, wọ́n mú ọmọkùnrin náà lọ láàyè, ìtùnú tí wọ́n rí gbà sì kọjá sísọ.
13 A wá tẹ̀ síwájú lọ sídìí ọkọ̀ òkun, a sì wọkọ̀ lọ sí Ásò, níbi tí a ní i lọ́kàn pé a ti máa fi ọkọ̀ gbé Pọ́ọ̀lù, torí lẹ́yìn tó ti sọ ohun tí a máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, òun fúnra rẹ̀ ní i lọ́kàn láti fi ẹsẹ̀ rìn lọ síbẹ̀.
14 Torí náà, nígbà tó bá wa ní Ásò, a fi ọkọ̀ gbé e, a sì lọ sí Mítílénè.
15 Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, a wọkọ̀ kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì Kíósì, àmọ́ ní ọjọ́ kejì, a fẹsẹ̀ kan dé Sámósì, a sì dé Mílétù ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e.
16 Pọ́ọ̀lù ti pinnu láti wọkọ̀ òkun kọjá Éfésù,+ kó má bàa lo àkókò kankan ní ìpínlẹ̀ Éṣíà, torí ó fẹ́ tètè dé Jerúsálẹ́mù+ ní ọjọ́ Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì, bí ó bá ṣeé ṣe fún un.
17 Àmọ́ láti Mílétù, ó ránṣẹ́ sí Éfésù, ó ní kí wọ́n pe àwọn alàgbà ìjọ wá.
18 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ̀ dáadáa bí mo ṣe ń ṣe láàárín yín láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo ti dé sí ìpínlẹ̀ Éṣíà,+
19 tí mò ń sìn bí ẹrú fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀*+ àti omijé àti àwọn àdánwò tó ṣẹlẹ̀ sí mi nítorí ọ̀tẹ̀ àwọn Júù,
20 bí mi ò ṣe fà sẹ́yìn nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tó lérè fún yín* tàbí nínú kíkọ́ yín ní gbangba+ àti láti ilé dé ilé.+
21 Àmọ́ mo jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà+ sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.+
22 Ní báyìí, ẹ wò ó! ẹ̀mí ti sọ ọ́ di dandan fún mi,* mò ń rin ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi níbẹ̀,
23 kìkì pé ẹ̀mí mímọ́ ń jẹ́rìí fún mi léraléra láti ìlú dé ìlú pé ẹ̀wọ̀n àti ìpọ́njú ń dúró dè mí.+
24 Síbẹ̀, mi ò ka ẹ̀mí* mi sí ohun tó ṣe pàtàkì* sí mi, tí mo bá ṣáà ti lè parí eré ìje mi+ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.
25 “Ní báyìí, ẹ wò ó! Mo mọ̀ pé kò sí ìkankan nínú ẹ̀yin tí mo wàásù Ìjọba náà fún tó máa tún rí ojú mi mọ́.
26 Torí náà, mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo èèyàn,+
27 nítorí mi ò fà sẹ́yìn nínú sísọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run* fún yín.+
28 Ẹ kíyè sí ara yín+ àti sí gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ ti yàn yín ṣe alábòójútó,+ láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run,+ èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.+
29 Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn aninilára ìkookò máa wọlé sáàárín yín,+ wọn ò sì ní fọwọ́ pẹ̀lẹ́ mú agbo,
30 àwọn kan máa dìde láàárín yín, wọ́n á sọ àwọn ọ̀rọ̀ békebèke láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn sẹ́yìn ara wọn.+
31 “Nítorí náà, ẹ máa wà lójúfò, kí ẹ sì fi sọ́kàn pé fún ọdún mẹ́ta,+ mi ò ṣíwọ́ gbígba ẹnì kọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹ̀lú omijé tọ̀sántòru.
32 Ní báyìí, mo fà yín lé ọwọ́ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé yín ró, kí ó sì fún yín ní ogún náà láàárín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́.+
33 Fàdákà tàbí wúrà tàbí aṣọ èèyàn kankan ò wọ̀ mí lójú.+
34 Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé àwọn ọwọ́ yìí ti pèsè àwọn ohun tí mo nílò+ àti àwọn ohun tí àwọn tó wà pẹ̀lú mi nílò.
35 Mo ti fi hàn yín nínú ohun gbogbo nípa ṣíṣe iṣẹ́ kára lọ́nà yìí+ pé, ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ sọ pé: ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni+ ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.’”
36 Nígbà tó sọ àwọn nǹkan yìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹ̀lú gbogbo wọn, ó sì gbàdúrà.
37 Ní tòótọ́, gbogbo wọn bú sẹ́kún, wọ́n gbá Pọ́ọ̀lù mọ́ra,* wọ́n sì fẹnu kò ó lẹ́nu tìfẹ́tìfẹ́,*
38 torí ọ̀rọ̀ tó sọ, pé wọn ò ní rí ojú òun mọ́,+ dùn wọ́n wọra. Lẹ́yìn náà, wọ́n sìn ín dé ìdí ọkọ̀ òkun.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “wíńdò.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ̀ wà nínú rẹ̀.”
^ Ní Grk., “ó bu búrẹ́dì.”
^ Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
^ Tàbí “ohun tó máa ṣe yín láǹfààní.”
^ Ní Grk., “ẹ̀mí ti dè mí.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “tó ṣeyebíye.”
^ Tàbí “gbogbo ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn.”
^ Ní Grk., “rọ̀ mọ́ ọrùn Pọ́ọ̀lù.”
^ Tàbí “lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.”