Ìdárò 1:1-22

  • A fi Jerúsálẹ́mù wé obìnrin opó

    • Ó dá jókòó, a sì ti pa á tì (1)

    • Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí Síónì dá (8, 9)

    • Ọlọ́run kọ Síónì sílẹ̀ (12-15)

    • Kò sí ẹni tó máa tu Síónì nínú (17)

א [Áléfì]* 1  Ẹ wo bí Jerúsálẹ́mù tí àwọn èèyàn kún inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe wá dá páropáro!+ Ẹ wo bó ṣe dà bí opó, ìlú tó ti jẹ́ eléèyàn púpọ̀ rí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!+ Ẹ wo bí ẹni tó jẹ́ ọbabìnrin láàárín àwọn ìpínlẹ̀* ṣe wá di ẹrú!+ ב [Bétì]   Ó ń sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ ní òru,+ omijé sì ń dà ní ojú rẹ̀. Kò sí ìkankan nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tó máa tù ú nínú.+ Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á;+ wọ́n ti di ọ̀tá rẹ̀. ג [Gímélì]   Júdà ti lọ sí ìgbèkùn+ nínú ìpọ́njú, ó sì ń ṣe ẹrú nínú ìnira.+ Ó gbọ́dọ̀ máa gbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;+ kò rí ibi ìsinmi kankan. Ọwọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí i ti tẹ̀ ẹ́ nínú ìdààmú rẹ̀. ד [Dálétì]   Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Síónì ń ṣọ̀fọ̀, nítorí kò sí ẹni tó ń bọ̀ wá sí àjọyọ̀.+ Gbogbo ẹnubodè rẹ̀ di ahoro;+ àwọn àlùfáà rẹ̀ ń kẹ́dùn. Ẹ̀dùn ọkàn ti bá àwọn wúńdíá* rẹ̀, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá. ה [Híì]   Àwọn elénìní rẹ̀ ti wá di ọ̀gá* rẹ̀; àwọn ọ̀tá rẹ̀ kò sì ṣàníyàn.+ Jèhófà ti mú ẹ̀dùn ọkàn bá a nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó pọ̀.+ Àwọn ọmọ rẹ̀ ti lọ sí oko ẹrú níwájú àwọn elénìní.+ ו [Wọ́ọ̀]   Gbogbo ògo ọmọbìnrin Síónì ti kúrò lára rẹ̀.+ Àwọn olórí rẹ̀ dà bí àwọn akọ àgbọ̀nrín tí kò rí ibi ìjẹko,Àárẹ̀ ti mú wọn bí wọ́n ṣe ń rìn lọ níwájú ẹni tó ń lépa wọn. ז [Sáyìn]   Ní ọjọ́ ìdààmú Jerúsálẹ́mù àti nígbà tí kò rílé gbé, ó rántíGbogbo ohun iyebíye tó ní látijọ́.+ Nígbà tí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, tí kò sì ní olùrànlọ́wọ́ kankan,+Àwọn ọ̀tá rí i, wọ́n sì bú sẹ́rìn-ín* nítorí ìṣubú rẹ̀.+ ח [Hétì]   Jerúsálẹ́mù ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀.+ Ìdí nìyẹn tó fi di ohun ìríra. Gbogbo àwọn tó ń bọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti wá ń fojú ẹ̀gàn wò ó, nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀.+ Òun fúnra rẹ̀ kérora,+ ó sì yíjú pa dà pẹ̀lú ìtìjú. ט [Tétì]   Àìmọ́ rẹ̀ wà lára aṣọ rẹ̀. Kò ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ̀.+ Ìṣubú rẹ̀ yani lẹ́nu; kò sì ní ẹni tó máa tù ú nínú. Jèhófà, wo ìpọ́njú mi, nítorí ọ̀tá ti gbé ara rẹ̀ ga.+ י [Yódì] 10  Elénìní ti kó gbogbo ìṣúra rẹ̀.+ Nítorí ìṣojú rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú ibi mímọ́ rẹ̀,+Àwọn tí o pàṣẹ pé kí wọ́n má ṣe wá sínú ìjọ rẹ. כ [Káfì] 11  Gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ ń kẹ́dùn; wọ́n ń wá oúnjẹ.*+ Wọ́n ti fi ohun iyebíye wọn pààrọ̀ oúnjẹ, kí wọ́n lè máa wà láàyè.* Wò ó Jèhófà, wo bí mo ṣe dà bí obìnrin tí kò ní láárí.* ל [Lámédì] 12  Ṣé kò já mọ́ nǹkan kan lójú gbogbo ẹ̀yin tó ń kọjá lójú ọ̀nà ni? Ẹ wò ó, kí ẹ sì rí i! Ǹjẹ́ ìrora kankan wà tó dà bí ìrora tí a mú kí ó dé bá mi,Èyí tí Jèhófà mú kí n jìyà rẹ̀ ní ọjọ́ tí ìbínú rẹ̀ ń jó bí iná?+ מ [Mémì] 13  Láti ibi gíga ló ti rán iná sínú egungun mi,+ ó sì jó ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ó ti ta àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi; ó mú kí n pa dà sẹ́yìn. Ó ti sọ mí di obìnrin tí a pa tì. Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ṣàìsàn. נ [Núnì] 14  Ó fi ọwọ́ rẹ̀ so àwọn ìṣìnà mi pọ̀ bí àjàgà. Ó fi wọ́n kọ́ ọrùn mi, mi ò sì lókun mọ́. Jèhófà ti fi mí lé ọwọ́ àwọn tí mi ò lè dojú kọ.+ ס [Sámékì] 15  Jèhófà ti ti gbogbo àwọn alágbára tó wà láàárín mi sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.+ Ó ti pe àwọn èèyàn jọ sí mi kí wọ́n lè pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi.+ Jèhófà ti tẹ wúńdíá ọmọbìnrin Júdà bí àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.+ ע [Áyìn] 16  Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ṣe ń sunkún;+ omijé sì ń dà lójú mi. Nítorí ẹni tó lè tù mí nínú tàbí tó lè tù mí* lára ti jìnnà réré sí mi. Àwọn ọmọ mi kò nírètí, nítorí ọ̀tá ti borí. פ [Péè] 17  Síónì ti tẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+ kò ní ẹni tó máa tù ú nínú. Gbogbo àwọn tó yí Jékọ́bù ká ni Jèhófà ti pàṣẹ fún pé kí wọ́n máa bá a ṣọ̀tá.+ Jerúsálẹ́mù ti di ohun ìríra sí wọn.+ צ [Sádì] 18  Jèhófà jẹ́ olódodo,+ èmi ni mo ṣàìgbọràn sí àṣẹ* rẹ̀.+ Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin èèyàn, kí ẹ sì rí ìrora tí mò ń jẹ. Àwọn wúńdíá* mi àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ti lọ sí oko ẹrú.+ ק [Kófì] 19  Mo pe àwọn olólùfẹ́ mi, àmọ́ wọ́n pa mí tì.+ Àwọn àlùfáà mi àti àwọn àgbààgbà mi ti ṣègbé nínú ìlú,Níbi tí wọ́n ti ń wá oúnjẹ kiri kí wọ́n lè máa wà láàyè.*+ ר [Réṣì] 20  Wò ó, Jèhófà, mo wà nínú ìdààmú ńlá. Inú* mi ń dà rú. Ọkàn mi gbọgbẹ́, nítorí mo ti ya ọlọ̀tẹ̀ paraku.+ Idà ń pani ní ìta;+ ikú ń pani nínú ilé. ש [Ṣínì] 21  Àwọn èèyàn ti gbọ́ bí mo ṣe ń kẹ́dùn; kò sí ẹnì kankan tó máa tù mí nínú. Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa àjálù tó dé bá mi. Inú wọn dùn, nítorí o mú kí ó ṣẹlẹ̀.+ Àmọ́, o máa mú ọjọ́ tí o kéde wá,+ tí wọ́n á dà bí mo ṣe dà.+ ת [Tọ́ọ̀] 22  Kí gbogbo ìwà búburú wọn wá síwájú rẹ, kí o sì fìyà jẹ wọ́n,+Bí o ṣe fìyà jẹ mí nítorí gbogbo àṣìṣe mi. Nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi pọ̀, ọkàn mi sì ń ṣàárẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Orí 1 sí 4 jẹ́ orin arò tí wọ́n fi álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù tàbí ọ̀rọ̀ ewì tò.
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “àwọn ọ̀dọ́bìnrin.”
Ní Héb., “olórí.”
Tàbí “wọ́n yọ̀ ọ́.”
Tàbí “dá ọkàn wọn pa dà.”
Àkànlò èdè fífi nǹkan wé èèyàn, èyí tó ń tọ́ka sí Jerúsálẹ́mù.
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Tàbí “tu ọkàn mi.”
Tàbí “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin.”
Ní Héb., “ẹnu.”
Tàbí “dá ọkàn wọn pa dà.”
Ní Héb., “Ìfun.”