Ìdárò 2:1-22
א [Áléfì]
2 wo bí Jèhófà ṣe fi ìkùukùu* ìbínú rẹ̀ bo ọmọbìnrin Síónì!
Ó ti ju ẹwà Ísírẹ́lì láti òkè ọ̀run sí ilẹ̀ ayé.+
Kò sì rántí àpótí ìtìsẹ̀+ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
ב [Bétì]
2 Jèhófà ti gbé gbogbo ibùgbé Jékọ́bù mì, kò sì ṣàánú rẹ̀ rárá.
Ó ti ya àwọn ibi olódi ọmọbìnrin Júdà lulẹ̀ nínú ìbínú rẹ̀.+
Ó ti rẹ ìjọba + náà àti àwọn olórí+ rẹ̀ wálẹ̀, ó sì ti sọ wọ́n di aláìmọ́.
ג [Gímélì]
3 Ó ti gba agbára* Ísírẹ́lì, nínú ìbínú tó gbóná.
Ó fa ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sẹ́yìn nígbà tí ọ̀tá dé,+Ó sì ń jó nínú Jékọ́bù bí iná tó ń run gbogbo ohun tó wà ní àyíká rẹ̀.+
ד [Dálétì]
4 Ó ti tẹ* ọrun rẹ̀ bí ọ̀tá; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti múra tán láti jà bí elénìní;+Ó ń pa gbogbo àwọn tó jojú ní gbèsè.+
Ó da ìrunú rẹ̀ jáde bí iná+ sínú àgọ́ ọmọbìnrin Síónì.+
ה [Híì]
5 Jèhófà ṣe bí ọ̀tá;+Ó ti gbé Ísírẹ́lì mì.
Ó ti gbé gbogbo ilé gogoro rẹ̀ mì;Ó ti run gbogbo ibi olódi rẹ̀.
Ó sì sọ ọ̀fọ̀ àti ìdárò ọmọbìnrin Júdà di púpọ̀.
ו [Wọ́ọ̀]
6 Ó ṣe àtíbàbà rẹ̀ ṣúkaṣùka+ bí ahéré tó wà nínú oko.
Ó ti fòpin sí* àjọyọ̀ rẹ̀.+
Jèhófà ti mú kí a gbàgbé àjọyọ̀ àti sábáàtì ní Síónì,Kò sì ka ọba àti àlùfáà sí nígbà tí inú ń bí i gan-an.+
ז [Sáyìn]
7 Jèhófà ti pa pẹpẹ rẹ̀ tì;Ó ti ta ibi mímọ́ rẹ̀ nù.+
Ó ti fi ògiri àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò lé ọ̀tá lọ́wọ́.+
Wọ́n ti gbé ohùn wọn sókè ní ilé Jèhófà,+ bíi ti ọjọ́ àjọyọ̀.
ח [Hétì]
8 Jèhófà ti pinnu láti run ògiri ọmọbìnrin Síónì.+
Ó ti na okùn ìdíwọ̀n.+
Kò fa ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn láti mú ìparun wá.*
Ó ń mú kí odi ààbò àti ògiri máa ṣọ̀fọ̀.
Gbogbo wọn sì ti di aláìlágbára.
ט [Tétì]
9 Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì wọlẹ̀.+
Ọlọ́run ti ba ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣẹ́ ẹ.
Ọba rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+
Kò sí òfin;* kódà àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+
י [Yódì]
10 Àwọn àgbààgbà ọmọbìnrin Síónì jókòó sórí ilẹ̀ láìsọ̀rọ̀.+
Wọ́n da iyẹ̀pẹ̀ sí orí ara wọn, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.*+
Àwọn wúńdíá Jerúsálẹ́mù ti tẹrí ba mọ́lẹ̀.
כ [Káfì]
11 Ojú mi ti di bàìbàì nítorí omijé.+
Inú* mi ń dà rú.
A ti tú ẹ̀dọ̀ mi jáde sí ilẹ̀, nítorí ìṣubú ọmọbìnrin* àwọn èèyàn mi,+Nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ jòjòló ń dá kú ní àwọn ojúde ìlú.+
ל [Lámédì]
12 Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ìyá wọn pé: “Ọkà àti wáìnì dà?”+
Bí wọ́n ti ń kú lọ bí ẹni tó fara gbọgbẹ́ ní àwọn gbàgede ìlú,Tí ẹ̀mí* wọn sì ń kú lọ lọ́wọ́ ìyá wọn.
מ [Mémì]
13 Kí ni màá fi ṣe ẹ̀rí,Àbí kí ni màá fi ọ́ wé, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù?
Kí ni màá fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Síónì?
Nítorí ọgbẹ́ rẹ pọ̀ gan-an, ó fẹ̀ bí omi òkun.+ Ta ló lè wò ọ́ sàn?+
נ [Núnì]
14 Ìran tí àwọn wòlíì rẹ rí fún ọ jẹ́ èké àti asán,+Wọn kò fi àṣìṣe rẹ hàn ọ́ láti gbà ọ́ lọ́wọ́ oko ẹrú,+Ṣùgbọ́n ìran tí wọ́n ń rí, tí wọ́n sì ń kéde fún ọ jẹ́ èké àti ìṣìnà.+
ס [Sámékì]
15 Gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ lójú ọ̀nà ń fi ọ́ ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń pàtẹ́wọ́.+
Wọ́n ń súfèé nítorí ìyàlẹ́nu,+ wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, pé:
“Ṣé ìlú yìí ni wọ́n máa ń sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹwà rẹ̀ pé, ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé’?”+
פ [Péè]
16 Gbogbo ọ̀tá rẹ ti la ẹnu wọn sí ọ.
Wọ́n ń súfèé, wọ́n sì wa eyín pọ̀, wọ́n ń sọ pé: “A ti gbé e mì.+
Ọjọ́ tí à ń retí nìyí! + Ó ti dé, a sì ti rí i!”+
ע [Áyìn]
17 Jèhófà ti ṣe ohun tó ní lọ́kàn;+ ó ti ṣe ohun tó sọ,+Ohun tó ti pa láṣẹ tipẹ́tipẹ́.+
Ó ti ya ọ́ lulẹ̀, kò sì ṣàánú rẹ.+
Ó ti mú kí ọ̀tá yọ̀ lórí rẹ; ó ti mú kí agbára* àwọn elénìní rẹ borí.
צ [Sádì]
18 Ọkàn wọn ké jáde sí Jèhófà, ìwọ ògiri ọmọbìnrin Síónì.
Kí omijé máa ṣàn wálẹ̀ bí ọ̀gbàrá lọ́sàn-án àti lóru.
Má sinmi, má sì jẹ́ kí ojú* rẹ ṣíwọ́ ẹkún.
ק [Kófì]
19 Dìde! Bú sẹ́kún ní òru, ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò ìṣọ́.
Tú ọkàn rẹ jáde bí omi níwájú Jèhófà.
Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí Ọlọ́run nítorí ẹ̀mí* àwọn ọmọ rẹ,Tó ń kú lọ nítorí ìyàn ní gbogbo oríta* ojú ọ̀nà.+
ר [Réṣì]
20 Wò ó Jèhófà, wo ẹni tí o fìyà jẹ.
Ṣé ó yẹ kí àwọn obìnrin máa jẹ ọmọ* tiwọn fúnra wọn, àwọn ọmọ tí wọ́n bí láìní àbùkù,+Àbí, ṣé ó yẹ kí wọ́n pa àwọn àlùfáà àti wòlíì nínú ibi mímọ́ Jèhófà?+
ש [Ṣínì]
21 Òkú ọmọdékùnrin àti àgbà ọkùnrin wà nílẹ̀ ní àwọn ojú ọ̀nà.+
Àwọn wúńdíá* mi àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ni idà sì ti pa sílẹ̀.+
O ti pa wọ́n ní ọjọ́ ìbínú rẹ; o sì ti pa wọ́n láìṣàánú wọn.+
ת [Tọ́ọ̀]
22 O ránṣẹ́ pe ohun ẹ̀rù láti ibi gbogbo wá, bí ìgbà tí à ń peni sí ọjọ́ àjọyọ̀.+
Ní ọjọ́ ìrunú Jèhófà, kò sí ẹni tó sá àsálà, kò sì sí ẹni tó là á já;+Àwọn tí mo bí,* tí mo sì tọ́ dàgbà ni ọ̀tá mi ti pa run.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àwọsánmà.”
^ Ní Héb., “ṣẹ́ ìwo.”
^ Ní Héb., “fi ẹsẹ̀ tẹ.”
^ Tàbí “run.”
^ Ní Héb., “láti gbé mì.”
^ Tàbí “ìtọ́ni.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Ọ̀rọ̀ ewì tó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka si àánú tàbí ìgbatẹnirò bíi pé èèyàn ni wọ́n.
^ Ní Héb., “Ìfun.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ìwo.”
^ Ní Héb., “ọmọbìnrin ojú.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ìkóríta.”
^ Tàbí “èso.”
^ Tàbí “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin.”
^ Tàbí “Àwọn tí mo bí láìní àbùkù.”