Ìdárò 4:1-22
א [Áléfì]
4 Ẹ wo bí wúrà tó ń dán ṣe di bàìbàì, wúrà tó dára gan-an!+
Ẹ wo bí àwọn òkúta mímọ́+ ṣe fọ́n ká sílẹ̀ ní gbogbo oríta ojú ọ̀nà!*+
ב [Bétì]
2 Ní ti àwọn ọmọ ọ̀wọ́n Síónì, tí wọ́n fìgbà kan rí ṣeyebíye bíi wúrà tí a yọ́ mọ́,Ẹ wo bí a ti kà wọ́n sí ìkòkò amọ̀,Iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!
ג [Gímélì]
3 Àwọn ajáko* pàápàá máa ń fún ọmọ wọn lọ́mú,Àmọ́ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi ti ya ìkà,+ bí àwọn ògòǹgò aginjù.+
ד [Dálétì]
4 Ahọ́n ọmọ ẹnu ọmú lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ̀ nítorí òùngbẹ.
Àwọn ọmọ tọrọ oúnjẹ,*+ àmọ́ kò sí ẹni tó fún wọn.+
ה [Híì]
5 Àwọn tó ti ń jẹ oúnjẹ aládùn tẹ́lẹ̀ ni ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa kú* ní àwọn ojú ọ̀nà.+
Àwọn tí a fi aṣọ rírẹ̀dòdò tọ́ dàgbà+ ti wá ń lọ sínú òkìtì eérú.
ו [Wọ́ọ̀]
6 Ìyà tí a fi jẹ* ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi pọ̀ ju ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí a fi jẹ* Sódómù lọ,+Tí a ṣẹ́gun ní ìṣẹ́jú kan, láìsí ẹnì kankan tó ràn án lọ́wọ́.+
ז [Sáyìn]
7 Àwọn Násírì+ rẹ̀ mọ́ ju yìnyín lọ, wọ́n funfun ju wàrà lọ.
Wọ́n pọ́n ju iyùn lọ; wọ́n ń dán bí òkúta sàfáyà.
ח [Hétì]
8 Àwọ̀ wọn ti wá dúdú ju èédú lọ;A kò dá wọn mọ̀ ní ojú ọ̀nà.
Wọ́n ti rù kan egungun;+ awọ ara wọn ti gbẹ bí igi.
ט [Tétì]
9 Àwọn tí idà pa sàn ju àwọn tí ìyàn pa,+Àwọn tó ń kú lọ, tí ìyàn mú débi pé ìrora wọn dà bí ìgbà tí idà gúnni.
י [Yódì]
10 Àwọn obìnrin aláàánú ti fọwọ́ ara wọn se àwọn ọmọ wọn. +
Wọ́n ti di oúnjẹ ọ̀fọ̀ fún wọn nígbà tí ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi wó lulẹ̀.+
כ [Káfì]
11 Jèhófà ti fi ìrunú rẹ̀ hàn;Ó ti da ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná jáde.+
Ó sì ti dá iná kan ní Síónì tó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.+
ל [Lámédì]
12 Àwọn ọba ayé àti gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tó ń mú èso jáde kò gbà gbọ́Pé elénìní àti ọ̀tá máa wọ àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+
מ [Mémì]
13 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ àti àṣìṣe àwọn àlùfáà rẹ̀,+Tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàárín rẹ̀.+
נ [Núnì]
14 Wọ́n ti rìn kiri bí afọ́jú+ ní àwọn ojú ọ̀nà.
Ẹ̀jẹ̀ ti sọ wọ́n di aláìmọ́,+Tí kò fi sí ẹnikẹ́ni tó lè fọwọ́ kan ẹ̀wù wọn.
ס [Sámékì]
15 Àwọn èèyàn ń ké jáde sí wọn pé, “Ẹ kúrò! Ẹ̀yin aláìmọ́! Ẹ kúrò! Ẹ kúrò! Ẹ má fọwọ́ kàn wá!”
Nítorí wọn ò rí ilé gbé, wọ́n sì ń rìn kiri.
Àwọn èèyàn ń sọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Wọn ò lè gbé ibí yìí pẹ̀lú wa.*+
פ [Péè]
16 Ojú Jèhófà ti fọ́n wọn ká;+Kò ní ṣojú rere sí wọn mọ́.
Àwọn èèyàn kò ní bọ̀wọ̀ fún àwọn àlùfáà,+ wọn kò sì ní ṣàánú àwọn àgbààgbà.”+
ע [Áyìn]
17 Kódà ní báyìí, ojú wa ti di bàìbàì bí a ṣe ń retí ìrànwọ́ tí kò sì dé.+
A wá ìrànwọ́ títí lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò lè gbà wá.+
צ [Sádì]
18 Àwọn ọ̀tá wa ń dọdẹ wa kiri+ débi pé a ò lè rìn mọ́ ní àwọn ojúde ìlú wa.
Òpin wa ti sún mọ́lé; ọjọ́ wa ti pé, nítorí òpin wa ti dé.
ק [Kófì]
19 Àwọn tó ń lé wa yára ju ẹyẹ idì ojú ọ̀run lọ.+
Wọ́n lépa wa lórí àwọn òkè; wọ́n lúgọ dè wá nínú aginjù.
ר [Réṣì]
20 Èémí wa, ẹni àmì òróró Jèhófà,+ ni wọ́n ti mú nínú kòtò ńlá wọn,+Ẹni tí a sọ nípa rẹ̀ pé: “Abẹ́ òjìji rẹ̀ la ó máa gbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”
ש [Sínì]
21 Máa yọ̀ kí inú rẹ sì máa dùn, ìwọ ọmọbìnrin Édómù,+ bí o ṣe ń gbé ní ilẹ̀ Úsì.
Àmọ́ wọ́n á gbé ife náà fún ìwọ pẹ̀lú,+ wàá mu àmupara, wàá sì tú ara rẹ sí ìhòòhò.+
ת [Tọ́ọ̀]
22 Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti dòpin, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.
Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ọ lọ sí ìgbèkùn mọ́.+
Àmọ́ Ọlọ́run yóò fiyè sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Édómù.
Yóò tú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ síta.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ìkóríta.”
^ Tàbí “akátá.”
^ Ní Héb., “búrẹ́dì.”
^ Ní Héb., “ni ó ti di ahoro.”
^ Ní Héb., “ẹ̀ṣẹ̀.”
^ Ní Héb., “Àṣìṣe.”
^ Tàbí “ṣe àjèjì níbí yìí.”