Ìdárò 5:1-22
5 Jèhófà, rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa.
Wò wá, kí o sì rí ìtìjú wa.+
2 Ogún wa ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn ilé wa sì ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè.+
3 A ti di ọmọ aláìlóbìí, a kò ní bàbá; àwọn ìyá wa dà bí opó.+
4 Ńṣe là ń sanwó ká tó lè rí omi wa mu,+ wọ́n sì ń ta igi wa fún wa.
5 Àwọn tó ń lé wa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bá wa;
Ó ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, síbẹ̀ wọn ò fún wa ní ìsinmi.+
6 A ti tẹ́ ọwọ́ wa sí Íjíbítì+ àti Ásíríà,+ ká lè rí oúnjẹ tí ó tó jẹ.
7 Àwọn baba ńlá wa tó dẹ́ṣẹ̀ kò sí mọ́, àmọ́ àwa là ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8 Àwọn ìránṣẹ́ ló wá ń ṣàkóso lé wa lórí; kò sí ẹni tó máa gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9 À ń fi ẹ̀mí* wa wewu ká tó lè kó oúnjẹ wa wọlé,+ nítorí idà tó wà ní aginjù.
10 Awọ ara wa ti gbóná bí iná ìléru, nítorí ebi tó ń hanni léèmọ̀.+
11 Àwọn aya tó wà ní Síónì àti àwọn wúńdíá tó wà ní àwọn ìlú Júdà ni wọ́n ti kó ẹ̀gàn bá.*+
12 Wọ́n so àwọn ìjòyè rọ̀ ní ọwọ́ wọn,+ wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà.+
13 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin gbé ọlọ, àwọn ọmọdékùnrin sì kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ru igi tó wúwo.
14 Àwọn àgbààgbà kò jókòó sí ẹnubodè ìlú mọ́;+ àwọn ọ̀dọ́kùnrin kò sì fi ohun èlò kọ orin mọ́.+
15 Ọkàn wa kò láyọ̀ mọ́; ijó wa ti di ọ̀fọ̀.+
16 Adé ti já bọ́ lórí wa. A gbé, nítorí a ti dẹ́ṣẹ̀!
17 Nítorí èyí, ọkàn wa ń ṣàárẹ̀,+Ojú wa sì ti di bàìbàì nítorí àwọn nǹkan yìí,+
18 Nítorí Òkè Síónì ti di ahoro,+ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ti wá ń rìn káàkiri lórí rẹ̀.
19 Ní tìrẹ, Jèhófà, o jókòó lórí ìtẹ́ títí láé.
Ìtẹ́ rẹ jẹ́ láti ìran dé ìran.+
20 Kí nìdí tí o fi gbàgbé wa pátápátá, tí o sì pa wá tì títí di àkókò yìí?+
21 Mú wa pa dà sọ́dọ̀ rẹ, Jèhófà, a ó sì tètè pa dà sọ́dọ̀ rẹ.+
Sọ ọjọ́ wa di ọ̀tun bíi ti àtijọ́.+
22 Ńṣe lo kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá.
O ṣì ń bínú sí wa gidigidi.+