Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 10:1-11
10 Mo rí áńgẹ́lì alágbára míì tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, tí a fi ìkùukùu* ṣe ní ọ̀ṣọ́,* òṣùmàrè wà ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ dà bí oòrùn,+ ẹsẹ̀* rẹ̀ dà bí ọwọ̀n iná,
2 àkájọ ìwé kékeré kan tí a ṣí sílẹ̀ sì wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún sórí òkun, àmọ́ ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ òsì sórí ilẹ̀,
3 ó sì ké jáde bí ìgbà tí kìnnìún bá ké ramúramù.+ Nígbà tó ké jáde, ààrá méje+ sọ̀rọ̀.
4 Nígbà tí ààrá méje náà sọ̀rọ̀, mo fẹ́ kọ̀wé, àmọ́ mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run+ tó sọ pé: “Gbé èdìdì lé àwọn ohun tí ààrá méje náà sọ, má sì kọ wọ́n sílẹ̀.”
5 Áńgẹ́lì tí mo rí tó dúró sórí òkun àti ilẹ̀ na ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún sókè ọ̀run,
6 ó sì fi Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé+ búra, ẹni tó dá ọ̀run àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, ayé àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú òkun àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀,+ ó sọ pé: “A ò ní fi falẹ̀ mọ́.
7 Àmọ́ ní àwọn ọjọ́ tí áńgẹ́lì keje+ ti fẹ́ fun kàkàkí rẹ̀,+ àṣírí mímọ́ + tí Ọlọ́run kéde pé ó jẹ́ ìròyìn ayọ̀ fún àwọn ẹrú rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ wòlíì+ wá sí òpin ní tòótọ́.”
8 Mo sì gbọ́ ohùn láti ọ̀run+ tó tún ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Lọ, kí o gba àkájọ ìwé tí a ṣí sílẹ̀ tó wà ní ọwọ́ áńgẹ́lì tó dúró lórí òkun àti ilẹ̀.”+
9 Mo lọ bá áńgẹ́lì náà, mo sì sọ fún un pé kó fún mi ní àkájọ ìwé kékeré náà. Ó sọ fún mi pé: “Gbà, kí o jẹ ẹ́ tán,+ ó máa mú kí ikùn rẹ korò, àmọ́ ó máa dùn bí oyin ní ẹnu rẹ.”
10 Mo gba àkájọ ìwé kékeré náà ní ọwọ́ áńgẹ́lì náà, mo sì jẹ ẹ́,+ ó dùn bí oyin ní ẹnu mi,+ àmọ́ nígbà tí mo jẹ ẹ́ tán, ó mú kí ikùn mi korò.
11 Wọ́n sì sọ fún mi pé: “O gbọ́dọ̀ tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ahọ́n* àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àwọsánmà.”
^ Tàbí “fi ìkùukùu bò.”
^ Ní Grk., “àtẹ́lẹsẹ̀.”
^ Tàbí “àwọn èdè.”