Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 12:1-17
12 Lẹ́yìn náà, mo rí àmì ńlá kan ní ọ̀run: Wọ́n fi oòrùn ṣe obìnrin kan+ lọ́ṣọ̀ọ́,* òṣùpá wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá (12) sì wà ní orí rẹ̀,
2 ó lóyún. Ìrora àti ìnira sì mú kó máa ké jáde bó ṣe ń rọbí.
3 Mo rí àmì míì ní ọ̀run. Wò ó! Dírágónì ńlá+ aláwọ̀ iná, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, adé dáyádémà* méje sì wà ní àwọn orí rẹ̀;
4 ìrù rẹ̀ wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀+ ojú ọ̀run, ó sì jù wọ́n sí ayé.+ Dírágónì náà dúró pa síwájú obìnrin+ tó fẹ́ bímọ náà, kó lè pa ọmọ tó bá bí jẹ.
5 Obìnrin náà sì bí ọmọ kan,+ ọkùnrin ni, ẹni tó máa fi ọ̀pá irin+ ṣe olùṣọ́ àgùntàn gbogbo orílẹ̀-èdè. A sì já ọmọ náà gbà lọ* sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀.
6 Obìnrin náà sá lọ sí aginjù, níbi tí Ọlọ́run pèsè àyè sílẹ̀ sí fún un, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa bọ́ ọ fún ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà (1,260) ọjọ́.+
7 Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì*+ àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jà, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jà,
8 àmọ́ wọn ò borí,* kò sì sí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run.
9 A wá ju dírágónì ńlá+ náà sísàlẹ̀, ejò àtijọ́ náà,+ ẹni tí à ń pè ní Èṣù+ àti Sátánì,+ tó ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà;+ a jù ú sí ayé,+ a sì ju àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
10 Mo gbọ́ tí ohùn kan ké jáde ní ọ̀run pé:
“Ní báyìí, ìgbàlà+ àti agbára dé àti Ìjọba Ọlọ́run wa+ pẹ̀lú àṣẹ Kristi rẹ̀, torí pé a ti ju ẹni tó ń fẹ̀sùn kan àwọn ará wa sísàlẹ̀, ẹni tó ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sántòru níwájú Ọlọ́run wa!+
11 Wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀ + nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà àti nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn,+ wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ ọkàn* wọn,+ kódà lójú ikú.
12 Torí èyí, ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tó ń gbé inú wọn! Ayé àti òkun gbé,+ torí pé Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ń bínú gidigidi, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun.”+
13 Nígbà tí dírágónì náà rí i pé a ti ju òun sí ayé,+ ó ṣe inúnibíni sí obìnrin+ tó bí ọmọkùnrin náà.
14 Àmọ́ a fún obìnrin náà ní ìyẹ́ méjèèjì ẹyẹ idì ńlá,+ kó lè fò lọ sí àyè rẹ̀ nínú aginjù, níbi tí wọ́n á ti máa bọ́ ọ fún àkókò kan àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò*+ níbi tí ojú ejò náà+ ò tó.
15 Ejò náà sì pọ omi bí odò jáde látẹnu rẹ̀ tẹ̀ lé obìnrin náà, kí odò náà lè gbé e lọ.
16 Àmọ́ ilẹ̀ ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ̀ la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé odò tí dírágónì náà pọ̀ látẹnu rẹ̀ mì.
17 Dírágónì náà wá bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọmọ* rẹ̀ jagun,+ àwọn tó ń pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí iṣẹ́ wọn sì jẹ́ láti jẹ́rìí Jésù.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Obìnrin kan wọ oòrùn bí aṣọ.”
^ Tàbí “àwọn ìwérí ọba.”
^ Tàbí “mú ọmọ náà lọ.”
^ Ó túmọ̀ sí “Ta Ló Dà Bí Ọlọ́run?”
^ Tàbí kó jẹ́, “àmọ́ wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀ [ìyẹn, dírágónì náà].”
^ Tàbí “ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ìyẹn, àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀.
^ Ní Grk., “èso.”