Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 15:1-8

  • Áńgẹ́lì méje ní ìyọnu méje (1-8)

    • Orin Mósè àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn (3, 4)

15  Mo rí àmì míì ní ọ̀run, ó kàmàmà, ó sì yani lẹ́nu, áńgẹ́lì méje+ tí wọ́n ní ìyọnu méje. Àwọn yìí ló kẹ́yìn, torí a máa tipasẹ̀ wọn mú ìbínú Ọlọ́run wá sí òpin.+  Mo sì rí ohun kan tó rí bí òkun tó ń dán bíi gíláàsì+ tó dà pọ̀ mọ́ iná, àwọn tó ṣẹ́gun+ ẹranko náà àti ère rẹ̀+ àti nọ́ńbà orúkọ rẹ̀+ dúró níbi òkun tó ń dán bíi gíláàsì náà, wọ́n sì mú háàpù Ọlọ́run dání.  Wọ́n ń kọ orin Mósè+ ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà, pé: “Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àwọn iṣẹ́ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.+ Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ,+ Ọba ayérayé.+  Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ Jèhófà,* tí kò ní yin orúkọ rẹ lógo, torí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin?+ Torí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa wá jọ́sìn níwájú rẹ,+ torí a ti fi àwọn àṣẹ òdodo rẹ hàn kedere.”  Lẹ́yìn èyí, mo rí i, wọ́n ṣí ibi mímọ́ àgọ́ ẹ̀rí+ ní ọ̀run,+  àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní ìyọnu méje + náà sì jáde látinú ibi mímọ́ náà, wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀* tó mọ́, tó ń tàn yòò, wọ́n sì de ọ̀já wúrà mọ́ àyà wọn.  Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fún àwọn áńgẹ́lì méje náà ní abọ́ méje tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìbínú Ọlọ́run,+ ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé kún inú rẹ̀.  Èéfín sì kún ibi mímọ́ torí ògo Ọlọ́run+ àti agbára rẹ̀, ẹnì kankan ò sì lè wọnú ibi mímọ́ náà títí tí ìyọnu méje+ àwọn áńgẹ́lì méje náà fi parí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aṣọ àtàtà.”