Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 19:1-21

  • Ẹ yin Jáà, torí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ (1-10)

    • Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn (7-9)

  • Ẹni tó gun ẹṣin funfun (11-16)

  • Oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run (17, 18)

  • A ṣẹ́gun ẹranko náà (19-21)

19  Lẹ́yìn èyí, mo gbọ́ ohun kan ní ọ̀run tó dún bí ohùn àwọn tó pọ̀ gan-an. Wọ́n sọ pé: “Ẹ yin Jáà!*+ Ti Ọlọ́run wa ni ìgbàlà àti ògo àti agbára,  torí òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́ rẹ̀.+ Torí ó ti ṣèdájọ́ aṣẹ́wó ńlá tó fi ìṣekúṣe* rẹ̀ ba ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹrú rẹ̀ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀.”*+  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n tún sọ lẹ́ẹ̀kejì pé: “Ẹ yin Jáà!*+ Èéfín rẹ̀ ń lọ sókè títí láé àti láéláé.”+  Àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún+ (24) àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà  + wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run tó jókòó lórí ìtẹ́, wọ́n sọ pé: “Àmín! Ẹ yin Jáà!”*+  Bákan náà, ohùn kan dún láti ibi ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, gbogbo ẹ̀yin ẹrú rẹ̀,+ tó bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin ẹni kékeré àti ẹni ńlá.”+  Mo sì gbọ́ ohun tó dún bí ohùn àwọn tó pọ̀ gan-an àti bí ìró omi tó pọ̀ àti bí ìró àwọn ààrá tó rinlẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Ẹ yin Jáà,*+ torí Jèhófà* Ọlọ́run wa, Olódùmarè,+ ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba!+  Ẹ jẹ́ ká yọ̀, kí inú wa dùn gan-an, ká sì yìn ín lógo, torí àkókò ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti tó, ìyàwó rẹ̀ sì ti múra sílẹ̀.  Àní, a ti jẹ́ kó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* tó ń tàn yòò, tó sì mọ́ tónítóní, aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa náà dúró fún àwọn iṣẹ́ òdodo àwọn ẹni mímọ́.”+  Ó wá sọ fún mi pé, “Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni àwọn tí a pè wá síbi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”+ Bákan náà, ó sọ fún mi pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tòótọ́ tí Ọlọ́run sọ nìyí.” 10  Ni mo bá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ láti jọ́sìn rẹ̀. Àmọ́ ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀!+ Ẹrú bíi tìẹ ni mí àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí iṣẹ́ wọn jẹ́ láti jẹ́rìí nípa Jésù.+ Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn!+ Torí ìjẹ́rìí nípa Jésù ló ń mí sí àsọtẹ́lẹ̀.”+ 11  Mo rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, wò ó! ẹṣin funfun kan.+ A pe ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ ní Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé+ àti Olóòótọ́,+ ó ń ṣèdájọ́, ó sì ń fi òdodo+ jagun lọ. 12  Ojú rẹ̀ jẹ́ ọwọ́ iná tó ń jó fòfò,+ adé dáyádémà* tó pọ̀ sì wà ní orí rẹ̀. Ó ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnì kankan ò mọ̀ àfi òun fúnra rẹ̀, 13  ó wọ aṣọ àwọ̀lékè tí ẹ̀jẹ̀ wà lára rẹ̀,* orúkọ tí a sì ń pè é ni Ọ̀rọ̀+ Ọlọ́run. 14  Bákan náà, àwọn ọmọ ogun ọ̀run ń tẹ̀ lé e lórí àwọn ẹṣin funfun, wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* tó funfun, tó sì mọ́ tónítóní. 15  Idà tó mú, tó sì gùn jáde láti ẹnu rẹ̀,+ kó lè fi pa àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn.+ Bákan náà, ó ń tẹ ìbínú àti ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè níbi tí a ti ń fún wáìnì.+ 16  Orúkọ kan wà tí a kọ sára aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, àní sórí itan rẹ̀, ìyẹn Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.+ 17  Mo tún rí áńgẹ́lì kan tó dúró sínú oòrùn, ó fi ohùn tó dún ketekete sọ̀rọ̀, ó sọ fún gbogbo ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run* pé: “Ẹ wá síbí, ẹ kóra jọ síbi oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run,+ 18  kí ẹ lè jẹ ẹran ara àwọn ọba àti ẹran ara àwọn ọ̀gágun àti ẹran ara àwọn ọkùnrin alágbára+ àti ẹran ara àwọn ẹṣin àti ti àwọn tó jókòó sórí wọn+ àti ẹran ara gbogbo èèyàn, ti ẹni tó wà lómìnira àti ti ẹrú, ti àwọn ẹni kékeré àti ẹni ńlá.” 19  Mo sì rí i tí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn kóra jọ láti bá ẹni tó jókòó sórí ẹṣin àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jagun.+ 20  A sì mú ẹranko náà pẹ̀lú wòlíì èké+ tó ṣe àwọn iṣẹ́ àmì níwájú rẹ̀, èyí tó fi ṣi àwọn tó gba àmì ẹranko náà+ lọ́nà àti àwọn tó jọ́sìn ère rẹ̀.+ A ju àwọn méjèèjì láàyè sínú adágún iná tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí.+ 21  Àmọ́ a fi idà tó gùn, tó jáde láti ẹnu ẹni tó jókòó sórí ẹṣin pa àwọn yòókù.+ Gbogbo àwọn ẹyẹ sì jẹ ẹran ara wọn yó.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “láti ọwọ́ rẹ̀.”
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “àwọn ìwérí ọba.”
Tàbí kó jẹ́, “tí ẹ̀jẹ̀ ti ta sí.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ní agbedeméjì ọ̀run; ní òkè.”