Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 21:1-27
21 Mo rí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun;+ torí ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀ àti ayé tó wà tẹ́lẹ̀ ti kọjá lọ,+ kò sì sí òkun mọ́.+
2 Bákan náà mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun, ó ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.+
3 Ni mo bá gbọ́ ohùn kan tó dún ketekete látorí ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, á máa bá wọn gbé, wọ́n á sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa wà pẹ̀lú wọn.+
4 Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn,+ ikú ò ní sí mọ́,+ kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.+ Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”
5 Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́+ sọ pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”+ Ó tún sọ pé: “Kọ ọ́ sílẹ̀, torí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé,* òótọ́ sì ni.”
6 Ó sọ fún mi pé: “Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀! Èmi ni Ááfà àti Ómégà,* ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.+ Màá fún ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ ní omi látinú ìsun* omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.*+
7 Ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣẹ́gun máa jogún àwọn nǹkan yìí, màá jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, ó sì máa jẹ́ ọmọ mi.
8 Àmọ́ ní ti àwọn ojo àti àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́+ àti àwọn tí èérí wọn ń ríni lára àti àwọn apààyàn+ àti àwọn oníṣekúṣe*+ àti àwọn tó ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo òpùrọ́,+ ìpín wọn máa wà nínú adágún tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí.+ Èyí túmọ̀ sí ikú kejì.”+
9 Ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì méje tó gbé abọ́ méje dání tí ìyọnu méje tó kẹ́yìn+ kún inú rẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi, ó sọ fún mi pé: “Wá, màá sì fi ìyàwó hàn ọ́, aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”+
10 Lẹ́yìn náà, ó gbé mi nínú agbára ẹ̀mí lọ sí òkè ńlá kan tó ga fíofío, ó fi Jerúsálẹ́mù ìlú mímọ́ náà hàn mí, tó ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+
11 ó sì ní ògo Ọlọ́run.+ Ó ń tàn yanran bí òkúta tó ṣeyebíye jù lọ, bí òkúta jásípérì tó ń dán gbinrin bíi kírísítálì.+
12 Ó ní ògiri ńlá tó ga fíofío, ó sì ní ẹnubodè méjìlá (12), àwọn áńgẹ́lì méjìlá (12) wà ní àwọn ẹnubodè náà, a sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá (12) àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí àwọn ẹnubodè náà.
13 Ẹnubodè mẹ́ta wà ní ìlà oòrùn, mẹ́ta ní àríwá, mẹ́ta ní gúúsù àti mẹ́ta ní ìwọ̀ oòrùn.+
14 Ògiri ìlú náà tún ní òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá (12), orúkọ méjìlá (12) àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12)+ ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì wà lára wọn.
15 Ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá esùsú tí a fi wúrà ṣe dání kó lè fi ṣe ìwọ̀n, láti wọn ìlú náà àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ àti ògiri rẹ̀.+
16 Ìlú náà ní igun mẹ́rin tó dọ́gba, gígùn rẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀ tóbi lọ́gbọọgba. Ó fi ọ̀pá esùsú náà wọn ìlú náà, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ìwọ̀n Sítédíọ̀mù;* gígùn àti fífẹ̀ àti gíga rẹ̀ jẹ́ ọgbọọgba.
17 Bákan náà, ó wọn ògiri rẹ̀, ó jẹ́ ogóje ó lé mẹ́rin (144) ìgbọ̀nwọ́,* bí èèyàn ṣe ń wọn nǹkan àti bí àwọn áńgẹ́lì ṣe ń wọn nǹkan.
18 Òkúta jásípérì+ ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀, ìlú náà sì jẹ́ ògidì wúrà bíi gíláàsì tó mọ́ kedere.
19 A fi oríṣiríṣi òkúta iyebíye ṣe àwọn ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́: ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ jásípérì, ìkejì jẹ́ sàfáyà, ìkẹta jẹ́ kásídónì, ìkẹrin jẹ́ ẹ́mírádì,
20 ìkarùn-ún jẹ́ sádónísì, ìkẹfà jẹ́ sádíọ́sì, ìkeje jẹ́ kírísóláítì, ìkẹjọ jẹ́ bérílì, ìkẹsàn-án jẹ́ tópásì, ìkẹwàá jẹ́ kírísópírásì, ìkọkànlá jẹ́ háyásíǹtì, ìkejìlá jẹ́ ámétísì.
21 Bákan náà, ẹnubodè méjìlá (12) náà jẹ́ péálì méjìlá (12); péálì kan la fi ṣe ẹnubodè kọ̀ọ̀kan. Ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba ní ìlú náà jẹ́ ògidì wúrà, bíi gíláàsì tí a lè rí òdìkejì rẹ̀ kedere.
22 Mi ò rí tẹ́ńpìlì kankan nínú rẹ̀, torí Jèhófà* Ọlọ́run Olódùmarè+ ni tẹ́ńpìlì rẹ̀ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.
23 Ìlú náà ò nílò kí oòrùn tàbí òṣùpá tàn sórí rẹ̀, torí ògo Ọlọ́run mú kó mọ́lẹ̀ rekete,+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì ni fìtílà rẹ̀.+
24 Àwọn orílẹ̀-èdè máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀,+ àwọn ọba ayé sì máa mú ògo wọn wá sínú rẹ̀.
25 A ò ní ti ẹnubodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán, torí pé ilẹ̀ ò ní ṣú níbẹ̀.+
26 Wọ́n sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀.+
27 Àmọ́ ohunkóhun tó ní àbààwọ́n àti ẹnikẹ́ni tó ń hùwà tó ń ríni lára, tó sì ń tanni jẹ kò ní wọnú rẹ̀ rárá;+ àwọn tí a kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà nìkan ló máa wọnú rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ṣeé gbọ́kàn lé.”
^ Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, Ómégà sì ni lẹ́tà tó gbẹ̀yìn.
^ Tàbí “orísun.”
^ Tàbí “láìsan ohunkóhun.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
^ Nǹkan bíi kìlómítà 2,220 (máìlì 1,379). Sítédíọ̀mù kan jẹ́ mítà 185 (606.95 ẹsẹ̀ bàtà). Wo Àfikún B14.
^ Nǹkan bíi mítà 64 (ẹsẹ̀ bàtà 210). Wo Àfikún B14.