Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 3:1-22
3 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Sádísì pé: Àwọn ohun tí ẹni tó ní ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run+ àti ìràwọ̀ méje+ sọ nìyí: ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé o kàn ní orúkọ pé o wà láàyè* ni, àmọ́ o ti kú.+
2 Máa ṣọ́ra,+ kí o sì fún àwọn ohun tó ṣẹ́ kù tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú lókun, torí mi ò tíì rí i kí o parí àwọn iṣẹ́ rẹ* níwájú Ọlọ́run mi.
3 Torí náà, máa fi bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́ sọ́kàn,* kí o máa pa á mọ́, kí o sì ronú pìwà dà.+ Bí o ò bá jí, ó dájú pé màá wá bí olè,+ o ò sì ní mọ wákàtí tí màá dé bá ọ rárá.+
4 “‘Síbẹ̀, àwọn èèyàn díẹ̀ kan* wà ní Sádísì tí wọn ò sọ aṣọ wọn di ẹlẹ́gbin,+ a sì jọ máa rìn nínú aṣọ funfun,+ torí wọ́n yẹ.
5 Torí náà, ẹni tó bá ṣẹ́gun+ máa wọ aṣọ funfun,+ mi ò ní yọ orúkọ rẹ̀ kúrò* nínú ìwé ìyè,+ màá sì fi hàn pé mo mọ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.+
6 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.’
7 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Filadéfíà pé: Àwọn ohun tí ẹni tó jẹ́ mímọ́+ sọ nìyí, ẹni tó jẹ́ òótọ́,+ tó ní kọ́kọ́rọ́ Dáfídì,+ ẹni tó ń ṣí, tí ẹnì kankan ò sì lè tì, tó sì ń tì, tí ẹnì kankan ò sì lè ṣí:
8 ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ—wò ó! mo ti ṣí ilẹ̀kùn sílẹ̀ níwájú rẹ,+ èyí tí ẹnì kankan ò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára díẹ̀ lo ní, síbẹ̀ o pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, o ò sì sẹ́ orúkọ mi.
9 Wò ó! Màá mú kí àwọn tó wá láti sínágọ́gù Sátánì, tí wọ́n ń pe ara wọn ní Júù, síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe Júù,+ àmọ́ tí wọ́n ń parọ́—wò ó! màá mú kí wọ́n wá, kí wọ́n sì tẹrí ba* níwájú ẹsẹ̀ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.
10 Torí o pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́,*+ màá pa ìwọ náà mọ́ nígbà wákàtí ìdánwò,+ èyí tó máa dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, láti dán àwọn tó ń gbé ayé wò.
11 Mò ń bọ̀ kíákíá.+ Di ohun tí o ní mú ṣinṣin, kí ẹnì kankan má bàa gba adé rẹ.+
12 “‘Màá fi ẹni tó bá ṣẹ́gun ṣe òpó nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run mi, kò ní jáde kúrò nínú rẹ̀ mọ́, màá sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sára rẹ̀ + àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, Jerúsálẹ́mù Tuntun+ tó ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run látọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi àti orúkọ mi tuntun.+
13 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.’
14 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Laodíkíà+ pé: Àwọn ohun tí Àmín+ sọ nìyí, ẹlẹ́rìí+ olóòótọ́ tó sì ṣeé gbára lé,+ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá:+
15 ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé o ò tutù, o ò sì gbóná. Ì bá wù mí kí o tutù tàbí kí o gbóná.
16 Àmọ́ torí pé ṣe lo lọ́wọ́ọ́wọ́, tí o ò gbóná,+ tí o ò sì tutù,+ màá pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi.
17 Torí o sọ pé, “Ọlọ́rọ̀ ni mí,+ mo ti kó ọrọ̀ jọ, mi ò sì nílò nǹkan kan,” àmọ́ o ò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ ni ọ́, ẹni téèyàn ń káàánú, òtòṣì, afọ́jú àti ẹni tó wà ní ìhòòhò,
18 mo gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n fi iná yọ́ mọ́ lọ́dọ̀ mi, kí o lè di ọlọ́rọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o lè rí aṣọ wọ̀, kí ìtìjú má bàa bá ọ torí pé o wà ní ìhòòhò,+ kí o sì ra oògùn ojú láti fi pa ojú rẹ,+ kí o lè ríran.+
19 “‘Gbogbo àwọn tí mo fẹ́ràn ni mò ń bá wí, tí mo sì ń tọ́ sọ́nà.+ Torí náà, jẹ́ onítara, kí o sì ronú pìwà dà.+
20 Wò ó! Mo dúró lẹ́nu ọ̀nà, mo sì ń kan ilẹ̀kùn. Tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi tó sì ṣí ilẹ̀kùn, màá wọ ilé rẹ̀, màá bá a jẹun alẹ́, òun náà á sì bá mi jẹun.
21 Màá jẹ́ kí ẹni tó bá ṣẹ́gun+ jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi,+ bí èmi náà ṣe ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó+ pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.
22 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “wọ́n kàn mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó wà láàyè.”
^ Tàbí “ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ láṣepé.”
^ Tàbí “máa rántí bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́.”
^ Ní Grk., “àwọn orúkọ díẹ̀ kan.”
^ Tàbí “pa orúkọ rẹ̀ rẹ́.”
^ Tàbí “forí balẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfaradà mi.”