Ìsíkíẹ́lì 19:1-14
-
Orin arò torí àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì (1-14)
19 “Kí o kọ orin arò* nípa àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì,
2 kí o sì sọ pé,‘Ta ni ìyá rẹ? Abo kìnnìún láàárín àwọn kìnnìún.
Ó dùbúlẹ̀ sáàárín àwọn ọmọ kìnnìún tó lágbára,* ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
3 Ó tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di ọmọ kìnnìún tó lágbára.+
Ọmọ náà kọ́ bí wọ́n ṣe ń pa ẹran jẹ,Ó tún ń pa èèyàn jẹ.
4 Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n mú un nínú ihò wọn,Wọ́n sì fi ìkọ́ fà á wá sí ilẹ̀ Íjíbítì.+
5 Ìyá rẹ̀ dúró dè é, nígbà tó yá, ó rí i pé kò sírètí pé ó máa pa dà.
Torí náà, ó mú òmíràn nínú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì rán an jáde bí ọmọ kìnnìún tó lágbára.
6 Òun náà rìn káàkiri láàárín àwọn kìnnìún, ó sì di ọmọ kìnnìún tó lágbára.
Ó kọ́ bí wọ́n ṣe ń pa ẹran jẹ, ó sì tún ń pa èèyàn jẹ.+
7 Ó ń rìn kiri láàárín àwọn ilé gogoro wọn tó láàbò, ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro,Débi pé ìró bó ṣe ń ké ramúramù gba ilẹ̀ tó ti di ahoro náà kan.+
8 Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láwọn agbègbè tó yí i ká wá a wá kí wọ́n lè fi àwọ̀n mú un,Wọ́n sì mú un nínú ihò wọn.
9 Wọ́n fi ìkọ́ gbé e sínú àhámọ́, wọ́n sì gbé e wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì.
Ibẹ̀ ni wọ́n sé e mọ́, kí wọ́n má bàa gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì.
10 Ìyá rẹ dà bí àjàrà+ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ,* èyí tí wọ́n gbìn sétí omi.
Ọ̀pọ̀ omi náà mú kó so èso, kó sì pẹ̀ka rẹpẹtẹ.
11 Ó wá ní àwọn ẹ̀ka* tó lágbára, tó ṣeé fi ṣe ọ̀pá àṣẹ àwọn alákòóso.
Ó dàgbà, ó sì ga ju àwọn igi yòókù,Wọ́n sì wá rí i, torí pé ó ga, ewé rẹ̀ sì pọ̀ yanturu.
12 Àmọ́ a fà á tu tìbínútìbínú,+ a sì jù ú sórí ilẹ̀,Atẹ́gùn ìlà oòrùn sì mú kí èso rẹ̀ gbẹ.
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó lágbára ya dà nù, wọ́n gbẹ,+ iná sì jó wọn run.+
13 Inú aginjù ni wọ́n wá gbìn ín sí,Ní ilẹ̀ tó gbẹ, tí kò lómi.+
14 Iná ràn látorí àwọn ẹ̀ka rẹ, ó sì jó àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ àti àwọn èso rẹ̀,Kò sì wá sí ẹ̀ka tó lágbára mọ́ lórí rẹ̀, kò sí ọ̀pá àṣẹ fún àwọn alákòóso.+
“‘Orin arò nìyẹn, yóò sì máa jẹ́ orin arò.’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
^ Tàbí “láàárín àwọn ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Tàbí kó jẹ́, “bí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ.”
^ Tàbí “àwọn ọ̀pá.”