Ìsíkíẹ́lì 2:1-10
2 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn,* dìde dúró kí n lè bá ọ sọ̀rọ̀.”+
2 Nígbà tó bá mi sọ̀rọ̀, ẹ̀mí wọ inú mi, ó sì mú kí n dìde dúró+ kí n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ Ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀.
3 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, màá rán ọ sí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ Àwọn àti àwọn baba ńlá wọn ti ṣẹ̀ mí títí di òní yìí.+
4 Màá rán ọ sí àwọn aláìgbọràn* ọmọ àti ọlọ́kàn líle,+ kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.’
5 Ní tiwọn, bóyá wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, torí ọlọ̀tẹ̀ ilé+ ni wọ́n, ó dájú pé wọ́n á mọ̀ pé wòlíì kan wà láàárín wọn.+
6 “Àmọ́ ìwọ, ọmọ èèyàn, má bẹ̀rù wọn;+ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn dẹ́rù bà ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún àti òṣùṣú+ yí ọ ká,* tí o sì ń gbé láàárín àwọn àkekèé. Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn dẹ́rù bà ọ́,+ má sì jẹ́ kí ojú wọn bà ọ́ lẹ́rù,+ torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.
7 O gbọ́dọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bóyá wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, torí ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.+
8 “Àmọ́ ìwọ, ọmọ èèyàn, gbọ́ ohun tí mò ń sọ fún ọ. Má ṣọ̀tẹ̀ bí ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí. La ẹnu rẹ, kí o sì jẹ ohun tí mo fẹ́ fún ọ.”+
9 Ni mo bá wò, mo sì rí ọwọ́ tí ẹnì kan nà sí mi,+ mo rí àkájọ ìwé tí wọ́n kọ nǹkan sí ní ọwọ́ náà.+
10 Nígbà tó tẹ́ ẹ síwájú mi, mo rí i pé wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí i níwájú àti lẹ́yìn.+ Orin arò,* ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ àti ìpohùnréré ẹkún ló wà nínú rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ “Ọmọ èèyàn”; èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbà 93 tí ọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì.
^ Tàbí “olórí kunkun.”
^ Tàbí kó jẹ́, “bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágídí làwọn èèyàn náà tí wọ́n sì dà bí ohun tó ń gún ọ.”
^ Tàbí “Orin ọ̀fọ̀.”