Ìsíkíẹ́lì 22:1-31
22 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ṣé o ṣe tán láti kéde ìdájọ́ sórí* ìlú tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀,+ ṣé o sì máa jẹ́ kó mọ gbogbo ohun ìríra tó ṣe?+
3 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ìwọ ìlú tí ò ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀+ nínú ara rẹ, tí àkókò rẹ ń bọ̀,+ tó ń ṣe àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* láti fi sọ ara rẹ di ẹlẹ́gbin,+
4 ẹ̀jẹ̀ tí o ta sílẹ̀ ti mú kí o jẹ̀bi,+ àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́.+ O ti mú kí òpin àwọn ọjọ́ rẹ yára sún mọ́lé, àwọn ọdún rẹ sì ti dópin. Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀gàn rẹ, kí gbogbo ilẹ̀ sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.+
5 Àwọn ilẹ̀ tó wà nítòsí rẹ àti àwọn tó wà lọ́nà jíjìn yóò fi ọ́ ṣẹlẹ́yà,+ ìwọ tí orúkọ rẹ jẹ́ aláìmọ́, tí rúkèrúdò kún inú rẹ.
6 Wò ó! Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú yín ń lo agbára tó wà níkàáwọ́ wọn láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+
7 Inú rẹ ni wọ́n ti ń tàbùkù sí bàbá àti ìyá wọn.+ Wọ́n lu àjèjì ní jìbìtì, wọ́n sì ni ọmọ aláìníbaba* àti opó lára.”’”+
8 “‘Ẹ tàbùkù sí àwọn ibi mímọ́ mi, ẹ sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́.+
9 Inú rẹ ni àwọn abanijẹ́ tó pinnu láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ wà.+ Wọ́n ń jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè nínú rẹ, wọ́n sì ń hùwà àìnítìjú láàárín rẹ.+
10 Inú rẹ ni wọ́n ti tàbùkù sí ibùsùn bàbá wọn,*+ wọ́n sì bá obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù lò pọ̀ nígbà tó ṣì jẹ́ aláìmọ́.+
11 Inú rẹ ni ọkùnrin kan ti bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ ṣe ohun ìríra,+ ẹlòmíì hùwà àìnítìjú ní ti pé ó bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ sùn, ẹlòmíì sì bá arábìnrin rẹ̀,+ tó jẹ́ ọmọ bàbá rẹ̀ lò pọ̀.+
12 Inú rẹ ni wọ́n ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ò ń yáni lówó èlé,+ ò ń jẹ èrè* lórí owó tí o yáni, o sì ń fipá gba owó lọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ.+ Àní, o ti gbàgbé mi pátápátá,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
13 “‘Wò ó! Mo pàtẹ́wọ́ tẹ̀gàntẹ̀gàn nítorí èrè tí kò tọ́ tí o jẹ àti nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ nínú rẹ.
14 Ṣé wàá ṣì ní ìgboyà,* ṣé ọwọ́ rẹ ṣì máa lágbára ní ọjọ́ tí mo bá fìyà jẹ ọ́?+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, màá sì ṣe é.
15 Èmi yóò fọ́n ọ ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò tú ọ ká sí àwọn ilẹ̀,+ màá sì fòpin sí ìwà àìmọ́ rẹ.+
16 Ìwọ kò ní níyì lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+
17 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
18 “Ọmọ èèyàn, ilé Ísírẹ́lì ti dà bí ìdàrọ́ tí kò wúlò lójú mi. Bàbà, tánganran, irin àti òjé tó wà nínú iná ìléru ni gbogbo wọn. Wọ́n ti di ìdàrọ́ fàdákà.+
19 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Torí pé gbogbo yín ti dà bí ìdàrọ́ tí kò wúlò,+ èmi yóò kó yín jọ sí Jerúsálẹ́mù.
20 Bí ìgbà tí wọ́n bá kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti tánganran jọ sínú iná ìléru, kí wọ́n lè koná mọ́ ọn kí wọ́n sì yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni màá fi ìbínú àti ìrunú kó yín jọ, màá koná mọ́ yín, màá sì yọ́ yín.+
21 Èmi yóò kó yín jọ, èmi yóò koná ìbínú mi mọ́ yín,+ ẹ ó sì yọ́ nínú rẹ̀.+
22 Bí fàdákà ṣe ń yọ́ nínú iná ìléru, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ́ nínú rẹ̀; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti bínú sí yín gan-an.’”
23 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
24 “Ọmọ èèyàn, sọ fún un pé, ‘Ilẹ̀ tí wọn ò ní fọ̀ mọ́ ni ọ́, tí òjò kò sì ní rọ̀ sí ní ọjọ́ ìbínú.
25 Àwọn wòlíì rẹ̀ ti gbìmọ̀ pọ̀ ní àárín rẹ̀,+ bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù tó ń fa ẹran ya.+ Wọ́n ń jẹ àwọn èèyàn* run. Wọ́n ń fipá gba ìṣúra àti àwọn ohun iyebíye. Wọ́n ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di opó ní àárín rẹ̀.
26 Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti rú òfin mi,+ wọ́n sì ń sọ àwọn ibi mímọ́ mi di aláìmọ́.+ Wọn ò fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó mọ́ àti ohun yẹpẹrẹ,+ wọn ò jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́,+ wọ́n sì kọ̀ láti pa àwọn sábáàtì mi mọ́, wọ́n sì ń pẹ̀gàn mi láàárín wọn.
27 Àwọn olórí tó wà láàárín rẹ̀ dà bí ìkookò tó ń fa ẹran ya; wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn èèyàn* láti jẹ èrè tí kò tọ́.+
28 Àmọ́ àwọn wòlíì rẹ̀ ti fi ẹfun kun ohun tí wọ́n ṣe. Wọ́n ń rí ìran èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,” tó sì jẹ́ pé Jèhófà ò sọ̀rọ̀.
29 Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ti lu jìbìtì, wọ́n sì ti jalè,+ wọ́n ti ni aláìní àti tálákà lára, wọ́n ti lu àjèjì ní jìbìtì, wọ́n sì ti fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú.’
30 “‘Mò ń wá ẹnì kan nínú wọn tí yóò tún ògiri olókùúta náà ṣe tàbí tó máa dúró níwájú mi síbi àlàfo náà torí ilẹ̀ náà, kó má bàa pa run,+ àmọ́ mi ò rí ẹnì kankan.
31 Torí náà, màá bínú sí wọn gidigidi, màá sì fi ìbínú mi tó ń jó bí iná pa wọ́n run. Màá fi ìwà wọn san wọ́n lẹ́san,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ṣé o máa ṣèdájọ́, ṣé o máa ṣèdájọ́.”
^ Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
^ Tàbí “ọmọ aláìlóbìí.”
^ Ní Héb., “tú ìhòòhò bàbá wọn síta.”
^ Tàbí “ń gba èlé gọbọi.”
^ Ní Héb., “ọkàn.”
^ Tàbí “àwọn ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”