Ìsíkíẹ́lì 3:1-27

  • Ọlọ́run ní kí Ìsíkíẹ́lì jẹ àkájọ ìwé tó fún un (1-15)

  • Ìsíkíẹ́lì máa ṣe olùṣọ́ (16-27)

    • Tí kò bá kìlọ̀, yóò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ (18-21)

3  Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ ohun tó wà níwájú rẹ.* Jẹ àkájọ ìwé yìí, kí o sì lọ bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.”+  Torí náà, mo la ẹnu mi, ó sì fún mi ní àkájọ ìwé náà pé kí n jẹ ẹ́.  Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ àkájọ ìwé tí mo fún ọ yìí, kí o sì jẹ ẹ́ yó.” Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi.+  Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, lọ sí ilé Ísírẹ́lì, kí o sì jíṣẹ́ mi fún wọn.  Torí kì í ṣe àwọn èèyàn tó ń sọ èdè tó ṣòroó lóye tàbí tí èdè wọn ṣàjèjì ni mò ń rán ọ sí, bí kò ṣe ilé Ísírẹ́lì.  Kì í ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń sọ èdè tó ṣòroó lóye tàbí tí èdè wọn ṣàjèjì ni mò ń rán ọ sí. Ká ní àwọn ni mo rán ọ sí ni, wọ́n á gbọ́.+  Àmọ́ ilé Ísírẹ́lì ò ní tẹ́tí sí ọ torí wọn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.+ Olórí kunkun àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì.+  Wò ó! Mo ti mú kí ojú rẹ le bí ojú wọn, mo sì mú kí iwájú orí rẹ le bí iwájú orí wọn.+  Mo ti mú kí iwájú orí rẹ dà bíi dáyámọ́ǹdì, ó le ju akọ òkúta lọ.+ Má bẹ̀rù wọn, má sì jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́,+ torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.” 10  Ó ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ, ó ní: “Ọmọ èèyàn, fetí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fún ọ, kí o sì fi í sọ́kàn. 11  Lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ* tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn,+ kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀. Yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.’”+ 12  Ẹ̀mí kan wá ń gbé mi lọ,+ mo sì gbọ́ ìró ohùn kan tó ń rọ́ gììrì lẹ́yìn mi pé: “Ẹ yin Jèhófà lógo láti àyè rẹ̀.” 13  Mo sì gbọ́ ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà bí wọ́n ṣe ń kanra wọn+ àti ìró àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn+ àti ìró ìrọ́gìrì tó rinlẹ̀. 14  Ẹ̀mí náà gbé mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú mi lọ. Inú mi bà jẹ́, inú sì ń bí mi bí mo ṣe ń lọ, ọwọ́ Jèhófà wà lára mi lọ́nà tó lágbára. 15  Mo wá lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Tẹli-ábíbù, tí wọ́n ń gbé lẹ́bàá odò Kébárì,+ mo sì dúró síbi tí wọ́n ń gbé; mò ń wò su u,+ mo wà lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ méje. 16  Lẹ́yìn ọjọ́ keje, Jèhófà sọ fún mi pé: 17  “Ọmọ èèyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì,+ nígbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kí o bá mi kìlọ̀ fún wọn.+ 18  Tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Ó dájú pé wàá kú,’ àmọ́ tí ìwọ kò kìlọ̀ fún un, tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kó jáwọ́ nínú ìwà burúkú rẹ̀ kó lè wà láàyè,+ yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ torí pé ó jẹ́ ẹni burúkú,+ àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.*+ 19  Àmọ́ tí o bá kìlọ̀ fún ẹni burúkú tí kò sì jáwọ́ nínú iṣẹ́ ibi àti ìwà burúkú rẹ̀, yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dájú pé ìwọ yóò gba ẹ̀mí* rẹ là.+ 20  Àmọ́ tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa,* èmi yóò fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀, yóò sì kú.+ Tí ìwọ kò bá kìlọ̀ fún un, yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, mi ò sì ní rántí iṣẹ́ òdodo tó ti ṣe, àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.*+ 21  Àmọ́ tí o bá ti kìlọ̀ fún olódodo náà pé kó má ṣe dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, ó dájú pé ó máa wà láàyè torí o ti kìlọ̀ fún un,+ ìwọ náà yóò sì gba ẹ̀mí* rẹ là.” 22  Ọwọ́ Jèhófà wá sára mi níbẹ̀, ó sì sọ fún mi pé: “Dìde, lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀.” 23  Torí náà mo dìde, mo sì lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Wò ó! ògo Jèhófà wà níbẹ̀,+ bí ògo tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì,+ mo sì dojú bolẹ̀. 24  Ẹ̀mí wá wọ inú mi, ó sì mú mi dìde dúró,+ ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sì sọ fún mi pé: “Lọ ti ara rẹ mọ́ inú ilé rẹ. 25  Ní ti ìwọ, ọmọ èèyàn, wọn yóò fi okùn dè ọ́, kí o má bàa kúrò láàárín wọn. 26  Màá sì mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ, o ò ní lè sọ̀rọ̀, o ò sì ní lè bá wọn wí, torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 27  Àmọ́ tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, màá mú kí o sọ̀rọ̀, o sì gbọ́dọ̀ sọ fún wọn pé,+ ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.’ Kí ẹni tó ń gbọ́ máa gbọ́,+ kí ẹni tí kò bá fẹ́ gbọ́ má sì gbọ́, nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “jẹ ohun tí o rí.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ èèyàn rẹ.”
Tàbí “ọrùn rẹ ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “tí kò sì ṣe òdodo mọ́.”
Tàbí “ọrùn rẹ ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”
Tàbí “ọkàn.”