Ìsíkíẹ́lì 41:1-26
41 Ó wá mú mi wọ ibi mímọ́ ìta,* ó sì wọn àwọn òpó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì; fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* mẹ́fà ní ẹ̀gbẹ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ẹ̀gbẹ́ kejì.
2 Fífẹ̀ ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, ògiri tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ẹ̀gbẹ́ kan àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ẹ̀gbẹ́ kejì. Ó wọn gígùn rẹ̀, ó jẹ́ ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́.
3 Ó wá wọlé,* ó sì wọn òpó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà, ìnípọn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, fífẹ̀ ẹnu ọ̀nà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. Àwọn ògiri tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà náà jẹ́* ìgbọ̀nwọ́ méje.
4 Lẹ́yìn ìyẹn, ó wọn yàrá tó kọjú sí ibi mímọ́ ìta, gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́.+ Ó sì sọ fún mi pé: “Ibi Mímọ́ Jù Lọ nìyí.”+
5 Ó wá wọn ògiri tẹ́ńpìlì náà, ìnípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. Fífẹ̀ àwọn yàrá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tẹ́ńpìlì náà yí ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin.+
6 Àwọn yàrá náà ní àjà mẹ́ta, ọ̀kan wà lórí èkejì, ọgbọ̀n (30) yàrá ló sì wà nínú àjà kọ̀ọ̀kan. Ògiri tẹ́ńpìlì náà ní igun yí ká, èyí tó gbé àwọn yàrá náà dúró tó fi jẹ́ pé ohun tó gbé àwọn yàrá náà dúró kò wọnú ògiri tẹ́ńpìlì.+
7 Àtẹ̀gùn* kan wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì tẹ́ńpìlì náà tó ń fẹ̀ sí i láti ìsàlẹ̀ lọ sókè.+ Bí èèyàn bá ṣe ń gùn ún láti àjà kan sí òmíràn ló ń fẹ̀ sí i, ó ń fẹ̀ sí i láti àjà ìsàlẹ̀ dé àjà àárín lọ sí àjà òkè.
8 Mo rí pèpéle kan, tó yí tẹ́ńpìlì náà ká, ìpìlẹ̀ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà sì jẹ́ ọ̀pá esùsú kan tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà dé igun.
9 Ògiri ìta àwọn yàrá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fẹ̀ ní ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Àyè* kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ tó wà lára tẹ́ńpìlì náà.
10 Àyè kan wà láàárín tẹ́ńpìlì náà àti àwọn yàrá ìjẹun,*+ fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan.
11 Ẹnu ọ̀nà kan wà láàárín àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ àti àyè tó wà ní apá àríwá, ẹnu ọ̀nà mìíràn sì wà ní apá gúúsù. Fífẹ̀ àyè náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yí ká.
12 Ilé tó wà ní ìwọ̀ oòrùn tó dojú kọ àyè fífẹ̀ náà jẹ́ àádọ́rin (70) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́rùn-ún (90) ìgbọ̀nwọ́; ìnípọn ògiri ilé náà yí ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.
13 Ó wọn tẹ́ńpìlì náà, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́. Àyè fífẹ̀ náà, ilé náà* àti ògiri rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn.
14 Iwájú tẹ́ńpìlì náà tó dojú kọ ìlà oòrùn àti àyè fífẹ̀ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀.
15 Ó wọn ilé tó kọjú sí ẹ̀yìn àyè fífẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́.
Ó tún wọn ibi mímọ́ ìta, ibi mímọ́ inú+ àti àwọn ibi àbáwọlé* ní àgbàlá náà,
16 pẹ̀lú àwọn ẹnu ọ̀nà, àwọn fèrèsé* tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì*+ àti àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ tó wà ní àwọn ibi mẹ́ta yẹn. Igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ+ ni wọ́n fi ṣe ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà náà láti ilẹ̀ dé ibi fèrèsé; wọ́n sì bo àwọn fèrèsé náà.
17 Ó wọn òkè ẹnu ọ̀nà náà, inú tẹ́ńpìlì, ìta àti gbogbo ògiri yí ká.
18 Wọ́n gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù+ àti igi ọ̀pẹ+ sára rẹ̀, àwòrán igi ọ̀pẹ kan wà láàárín kérúbù méjì, kérúbù kọ̀ọ̀kan sì ní ojú méjì.
19 Ojú èèyàn kọjú sí àwòrán igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kan, ojú kìnnìún* sì kọjú sí àwòrán igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kejì.+ Bí wọ́n ṣe gbẹ́ ẹ sí ara tẹ́ńpìlì náà yí ká nìyẹn.
20 Wọ́n gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ sára ògiri ibi mímọ́ láti ilẹ̀ dé ibi òkè ẹnu ọ̀nà.
21 Igun mẹ́rin ni àwọn férémù* ibi mímọ́ náà ní.+ Ohun kan wà níwájú ibi mímọ́* náà tó dà bíi
22 pẹpẹ onígi+ tí gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta, tí gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Ó ní igun, igi ni wọ́n sì fi ṣe ìsàlẹ̀* rẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ó wá sọ fún mi pé: “Tábìlì tó wà níwájú Jèhófà nìyí.”+
23 Ibi mímọ́ ìta àti ibi mímọ́ jù lọ ní ilẹ̀kùn méjì-méjì.+
24 Ẹnu ọ̀nà náà ní ilẹ̀kùn méjì tó ṣeé ṣí síbí sọ́hùn-ún, ilẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan sì ní awẹ́ méjì.
25 Wọ́n gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ sára àwọn ilẹ̀kùn ibi mímọ́, bíi ti èyí tó wà lára àwọn ògiri.+ Ìbòrí kan tí wọ́n fi pákó ṣe wà níwájú ibi àbáwọlé* níta.
26 Àwọn fèrèsé tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì*+ àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ tún wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ibi àbáwọlé* náà àti àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ inú tẹ́ńpìlì àti àwọn ìbòrí náà.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “tẹ́ńpìlì náà.” Ní orí 41 àti 42, ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ibi mímọ́ ìta (Ibi Mímọ́) tàbí gbogbo ibi mímọ́ (tẹ́ńpìlì náà, Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ).
^ Èyí ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.
^ Ìyẹn, sínú ibi mímọ́ inú tàbí Ibi Mímọ́ Jù Lọ.
^ Ní Héb., “Ẹnu ọ̀nà náà fẹ̀ tó.”
^ Ó jọ pé àtẹ̀gùn ẹlẹ́lọ̀ọ́ ló ń sọ.
^ Ó jọ pé ọ̀nà tóóró kan tó yí tẹ́ńpìlì náà ká ni.
^ Tàbí “àwọn yàrá.”
^ Ìyẹn, ilé tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn ibi mímọ́.
^ Tàbí “gọ̀bì.”
^ Tàbí “àwọn fèrèsé tó kéré lápá kan tó sì fẹ̀ lódìkejì.”
^ Tàbí “wíńdò.”
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Ní Héb., “ni férémù.” Ó jọ pé ẹnu ọ̀nà Ibi Mímọ́ ló ń sọ.
^ Ó jọ pé Ibi Mímọ́ Jù Lọ ló ń sọ.
^ Ní Héb., “gígùn.”
^ Tàbí “gọ̀bì.”
^ Tàbí “Àwọn fèrèsé tó kéré lápá kan tó sì fẹ̀ lódìkejì.”
^ Tàbí “gọ̀bì.”