Òwe 12:1-28
12 Ẹni tó bá fẹ́ràn ẹ̀kọ́ fẹ́ràn ìmọ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìnírònú.*+
2 Ẹni rere ń rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà,Àmọ́ Ó ń dá ẹni tó ń gbèrò ìkà lẹ́bi.+
3 Ìwà burúkú kì í jẹ́ kéèyàn fìdí múlẹ̀,+Àmọ́ kò sí ohun tó lè fa olódodo tu.
4 Aya tó dáńgájíá jẹ́ adé fún ọkọ rẹ̀,+Àmọ́ adójútini aya dà bí ìjẹrà nínú egungun ọkọ rẹ̀.+
5 Ìrònú àwọn olódodo máa ń tọ́,Àmọ́ ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú.
6 Ọ̀rọ̀ àwọn ẹni burúkú dà bíi lílúgọ láti ṣekú pani,*+Àmọ́ ẹnu àwọn adúróṣinṣin ń gbà wọ́n sílẹ̀.+
7 Nígbà tí a bá bi àwọn ẹni burúkú ṣubú, wọn ò ní sí mọ́,Àmọ́ ilé àwọn olódodo yóò dúró digbí.+
8 Èèyàn á gba ìyìn nítorí ọgbọ́n tó ń jáde lẹ́nu rẹ̀,+Àmọ́ ẹ̀gàn ló máa bá ọlọ́kàn ẹ̀tàn.+
9 Ó sàn kí a gbéni ga díẹ̀, kéèyàn sì ní ìránṣẹ́Ju kí èèyàn máa yin ara rẹ̀, kó má sì ní oúnjẹ.*+
10 Olódodo ń tọ́jú ẹran* ọ̀sìn rẹ̀,+Àmọ́ tí ẹni burúkú bá tiẹ̀ ṣàánú, ìkà ló máa já sí.
11 Ẹni tó ń ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò jẹun tẹ́rùn,+Àmọ́ ẹni tó ń lépa àwọn ohun tí kò ní láárí kò ní làákàyè.*
12 Ẹni burúkú ń jowú ohun tí àwọn ẹni burúkú míì dẹkùn mú,Àmọ́ àwọn olódodo dà bí igi tí gbòǹgbò rẹ̀ jinlẹ̀ tó ń méso jáde.
13 Ọ̀rọ̀ burúkú tó ń jáde lẹ́nu ẹni ibi ló ń dẹkùn mú un,+Àmọ́ olódodo ń bọ́ lọ́wọ́ wàhálà.
14 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa ń fi ohun rere tẹ́ ẹ lọ́rùn,+Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì san èrè fún un.
15 Ọ̀nà òmùgọ̀ tọ́ ní ojú ara rẹ̀,+Àmọ́ ọlọ́gbọ́n máa ń gba ìmọ̀ràn.*+
16 Òmùgọ̀ máa ń fi ìbínú rẹ̀ hàn lójú ẹsẹ̀,*+Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń gbójú fo* àbùkù tí wọ́n fi kàn án.
17 Ẹni tó ń fòótọ́ jẹ́rìí máa ń sọ òtítọ́,*Àmọ́ ẹlẹ́rìí èké máa ń sọ ẹ̀tàn.
18 Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni,Àmọ́ ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.+
19 Ètè tó ń sọ òtítọ́ máa wà títí láé,+Àmọ́ ahọ́n tó ń parọ́ kò ní tọ́jọ́.+
20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tó ń gbèrò ibi,Àmọ́ àwọn tó ń mú kí àlàáfíà wà* máa ní ayọ̀.+
21 Kò sí jàǹbá tó máa ṣe olódodo,+Àmọ́ ọ̀pọ̀ àjálù ló máa dé bá àwọn ẹni burúkú.+
22 Ètè tó ń parọ́ jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+Àmọ́ àwọn tó ń fi òtítọ́ hùwà ń mú inú rẹ̀ dùn.
23 Aláròjinlẹ̀ máa ń fi ohun tó mọ̀ pa mọ́,Àmọ́ ọkàn òmùgọ̀ máa ń tú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ jáde.+
24 Ọwọ́ àwọn tó ń ṣíṣẹ́ kára yóò ṣàkóso,+Àmọ́ ọwọ́ tó dilẹ̀ yóò wà fún iṣẹ́ àfipáṣe.+
25 Àníyàn inú ọkàn máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì,*+Àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.+
26 Olódodo ń ṣàyẹ̀wò ibi ìjẹko rẹ̀,Àmọ́ ọ̀nà àwọn ẹni burúkú ń kó wọn ṣìnà.
27 Ọ̀lẹ kò lè sáré lé ẹran tó fẹ́ pa,+Àmọ́ iṣẹ́ àṣekára ni ìṣúra èèyàn.
28 Ipa ọ̀nà òdodo ń yọrí sí ìyè;+Kò sí ikú ní ipa ọ̀nà rẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “kò ní ọgbọ́n.”
^ Ní Héb., “lílúgọ deni fún ẹ̀jẹ̀.”
^ Ní Héb., “búrẹ́dì.”
^ Tàbí “ọkàn ẹran.”
^ Ní Héb., “jẹ́ ẹni tí ọkàn kù fún.”
^ Tàbí “àmọ̀ràn.”
^ Tàbí “lọ́jọ́ kan náà.”
^ Ní Héb., “ń bo.”
^ Ní Héb., “ohun tó jẹ́ òdodo.”
^ Ní Héb., “àwọn agbani-nímọ̀ràn àlàáfíà.”
^ Tàbí “banú jẹ́.”