Òwe 14:1-35
14 Ọlọ́gbọ́n obìnrin ń kọ́ ilé rẹ̀,+Àmọ́ òmùgọ̀ obìnrin á fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya tirẹ̀ lulẹ̀.
2 Ẹni tó ń rìn nínú ìdúróṣinṣin ń bẹ̀rù Jèhófà,Àmọ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́* ń tàbùkù sí I.
3 Pàṣán ìgbéraga wà ní ẹnu òmùgọ̀,Àmọ́ ètè àwọn ọlọ́gbọ́n yóò dáàbò bò wọ́n.
4 Tí kò bá sí ẹran ọ̀sìn,* ibùjẹ ẹran á mọ́ tónítóní,Àmọ́ agbára akọ màlúù máa ń mú kí ìkórè pọ̀.
5 Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ olóòótọ́ kì í parọ́,Àmọ́ ẹlẹ́rìí èké kò lè ṣe kó má parọ́.+
6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n, kò sì rí i,Àmọ́ ìmọ̀ máa ń wá sọ́dọ̀ àwọn olóye pẹ̀lú ìrọ̀rùn.+
7 Jìnnà sí òmùgọ̀ èèyàn,Torí o ò ní rí ìmọ̀ ní ẹnu rẹ̀.+
8 Ọgbọ́n ni aláròjinlẹ̀ fi ń lóye ibi tí ọ̀nà rẹ̀ máa já sí,Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń ṣì wọ́n lọ́nà.*+
9 Òmùgọ̀ ló ń da ẹ̀bi rẹ̀* sáwàdà,+Àmọ́ àwọn adúróṣinṣin máa ń fẹ́ láti pa dà wà níṣọ̀kan.*
10 Ọkàn èèyàn mọ ìbànújẹ́ rẹ̀,*Àjèjì kò sì lè pín nínú ayọ̀ rẹ̀.
11 Ilé àwọn ẹni burúkú máa pa run,+Àmọ́ àgọ́ àwọn adúróṣinṣin máa gbilẹ̀.
12 Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn,+Àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.+
13 Èèyàn lè máa rẹ́rìn-ín, síbẹ̀ kí ọkàn rẹ̀ máa jẹ̀rora,Ìdùnnú sì lè di ìbànújẹ́.
14 Aláìṣòótọ́ máa gba èrè àwọn ọ̀nà rẹ̀,+Àmọ́ èèyàn rere máa gba èrè ìwà rẹ̀.+
15 Aláìmọ̀kan* máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́,Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.+
16 Ọlọ́gbọ́n máa ń ṣọ́ra, ó sì ń yẹra fún ìwà burúkú,Àmọ́ òmùgọ̀ kì í kíyè sára,* ó sì máa ń dá ara rẹ̀ lójú jù.
17 Ẹni tó bá tètè ń bínú máa ń hùwà òmùgọ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá ń ro ọ̀rọ̀ wò* ni aráyé ń kórìíra.
18 Aláìmọ̀kan* yóò jogún ìwà òmùgọ̀,Àmọ́ a ó fi ìmọ̀ dé àwọn aláròjinlẹ̀ ládé.+
19 Àwọn èèyàn búburú yóò tẹrí ba níwájú àwọn ẹni rere,Àwọn èèyàn burúkú yóò sì tẹrí ba ní ẹnubodè àwọn olódodo.
20 Àwọn tó sún mọ́ tálákà pàápàá máa ń kórìíra rẹ̀,+Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá olówó ṣọ̀rẹ́.+
21 Ẹni tó bá ń fojú àbùkù wo ọmọnìkejì rẹ̀ ń dẹ́ṣẹ̀,Àmọ́ ẹni tó bá ń ṣàánú aláìní jẹ́ aláyọ̀.+
22 Àwọn tó ń gbèrò ibi máa ṣìnà.
Àmọ́ àwọn tó ti pinnu láti máa ṣe rere máa rí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́.+
23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè,Àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ń yọrí sí àìní.+
24 Adé àwọn ọlọ́gbọ́n ni ọrọ̀ wọn;Àmọ́ ìwà àwọn òmùgọ̀ jẹ́ kìkì ẹ̀gọ̀.+
25 Ẹlẹ́rìí tòótọ́ ń gba ẹ̀mí* là,Àmọ́ ẹlẹ́tàn kò lè ṣe kó má parọ́.
26 Ìbẹ̀rù Jèhófà máa ń fọkàn ẹni balẹ̀ pẹ̀sẹ̀,+Yóò sì jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.+
27 Ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ orísun ìyè,Kì í jẹ́ kéèyàn kó sínú ìdẹkùn ikú.
28 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni ògo ọba,+Àmọ́ alákòóso tí kò ní àwọn tó ń jọba lé lórí ti ṣubú.
29 Ẹni tí kì í tètè bínú ní ìjìnlẹ̀ òye,+Àmọ́ ẹni tí kò ní sùúrù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.+
30 Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun,*Àmọ́ owú dà bí àìsàn tó ń mú kí egungun jẹrà.+
31 Ẹni tó ń lu aláìní ní jìbìtì ń gan Ẹni tó dà a,+Àmọ́ ẹni tó ń ṣàánú tálákà ń yìn Ín lógo.+
32 Ìwà ibi ẹni burúkú ló máa gbé e ṣubú,Àmọ́ olódodo máa rí ààbò nítorí ìwà títọ́ rẹ̀.+
33 Inú ọkàn olóye ni ọgbọ́n fìdí kalẹ̀ sí,+Àmọ́ àárín àwọn òmùgọ̀ ló ti máa ń fi ara rẹ̀ hàn.
34 Òdodo máa ń gbé orílẹ̀-èdè lékè,+Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ máa ń kó ìtìjú bá orílẹ̀-èdè.
35 Inú ọba máa ń dùn sí ìránṣẹ́ tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye,+Àmọ́ inú rẹ̀ máa ń ru sí èyí tó ń hùwà ìtìjú.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “tí ọ̀nà rẹ̀ wọ́.”
^ Tàbí “màlúù.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ni wọ́n fi ń ṣi àwọn míì lọ́nà.”
^ Tàbí “ṣíṣe àtúnṣe.”
^ Tàbí “máa ń wá ire.”
^ Tàbí “ìkorò ọkàn rẹ̀.”
^ Tàbí “Aláìní ìrírí.”
^ Tàbí “máa ń bínú fùfù.”
^ Tàbí “aláròjinlẹ̀.”
^ Tàbí “aláìní ìrírí.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ní ìlera.”