Òwe 17:1-28
17 Òkèlè* gbígbẹ níbi tí àlàáfíà wà*+Sàn ju ilé àsè* rẹpẹtẹ tí ìjà wà.+
2 Ìránṣẹ́ tó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò di ọ̀gá lórí ọmọ tó ń hùwà ìtìjú,Yóò sì pín nínú ogún bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ.
3 Ìkòkò tí wọ́n fi ń yọ́ nǹkan mọ́ wà fún fàdákà, iná ìléru sì wà fún wúrà,+Àmọ́ Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò ọkàn.+
4 Ẹni burúkú máa ń fetí sí ọ̀rọ̀ tó ń dunni,Ẹlẹ́tàn sì ń fetí sí ahọ́n tó ń bani jẹ́.+
5 Ẹni tó bá ń fi aláìní ṣẹ̀sín ń gan Ẹni tó dà a,+Ẹni tó bá sì ń yọ̀ nítorí àjálù tó bá ẹlòmíì kò ní lọ láìjìyà.+
6 Àwọn ọmọ ọmọ ni adé arúgbó,Ògo àwọn ọmọkùnrin* sì ni bàbá* wọn.
7 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ́* kò yẹ òmùgọ̀.+
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ èké kò yẹ alákòóso!*+
8 Ẹ̀bùn dà bí òkúta iyebíye* lójú ẹni tó ni ín;+Ibi gbogbo tí ẹni náà bá yíjú sí ni yóò ti mú kó máa ṣàṣeyọrí.+
9 Ẹni tó bá ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini* ń wá ìfẹ́,+Àmọ́ ẹni tó bá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ṣáá ń tú ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.+
10 Ìbáwí tí a fún olóye máa ń ṣe é láǹfààní púpọ̀+Ju lílu òmùgọ̀ ní ọgọ́rùn-ún ìgbà.+
11 Kìkì ọ̀tẹ̀ ni ẹni búburú máa ń wá,Àmọ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ ìkà ni wọn yóò rán sí i láti fìyà jẹ ẹ́.+
12 Ó sàn kéèyàn pàdé bíárì tó ṣòfò ọmọJu kéèyàn pàdé ẹni tó jẹ́ òmùgọ̀ nínú ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀. +
13 Tí ẹnikẹ́ni bá ń fi búburú san rere,Ohun búburú kò ní kúrò ní ilé rẹ̀.+
14 Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dà bí ìgbà téèyàn ṣí ibú omi sílẹ̀;*Kí ìjà tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.+
15 Ẹni tó bá dá ẹni burúkú láre àti ẹni tó dá olódodo lẹ́bi+Àwọn méjèèjì jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú Jèhófà.
16 Àǹfààní wo ló jẹ́ fún òmùgọ̀ pé ó rí ọ̀nà láti ní ọgbọ́nNígbà tí kò ní làákàyè?*+
17 Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo,+Ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.+
18 Ẹni tí kò ní làákàyè* ló máa ń bọ ọwọ́, tí á sì tún gbà tọkàntọkànLáti ṣe onídùúró* níwájú ọmọnìkejì rẹ̀.+
19 Ẹni tó bá fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀.+
Ẹni tó bá mú kí àbáwọlé rẹ̀ ga sókè ń wá ìparun.+
20 Ẹni tí ọkàn rẹ̀ burú kò ní ṣàṣeyọrí,*+Ẹni tó bá sì ń sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yóò ṣubú sínú ìparun.
21 Ẹni tó bá bí òmùgọ̀ ọmọ yóò ní ẹ̀dùn ọkàn;Bàbá ọmọ tí kò nírònú kì í sì í láyọ̀.+
22 Ọkàn tó ń yọ̀ jẹ́ oògùn tó dára fún ara,*+Àmọ́ ẹ̀mí tí ìdààmú bá máa ń tánni lókun.*+
23 Èèyàn burúkú yóò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀*Láti yí ìdájọ́ po.+
24 Ọgbọ́n wà ní ọ̀gangan iwájú olóye,Àmọ́ ojú àwọn òmùgọ̀ ń rìn gbéregbère títí dé ìkángun ayé.+
25 Òmùgọ̀ ọmọ ń fa ìbànújẹ́ fún bàbá rẹ̀Ó sì ń fa ọgbẹ́ ọkàn* fún ìyá tó bí i.+
26 Kò dára láti fìyà jẹ* olódodo,Kò sì tọ́ láti na àwọn èèyàn pàtàkì.
27 Ẹni tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń sọ,+Ẹni tó sì ní òye kì í gbaná jẹ.*+
28 Kódà òmùgọ̀ tó bá dákẹ́, a ó kà á sí ọlọ́gbọ́n,Ẹni tó bá sì pa ètè rẹ̀ dé, a ó kà á sí olóye.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ẹbọ.”
^ Tàbí “tí kò sí ìyọlẹ́nu.”
^ Ní Héb., “Búrẹ́dì.”
^ Tàbí “ọmọ.”
^ Tàbí “òbí.”
^ Tàbí “èèyàn pàtàkì.”
^ Tàbí “rere.”
^ Tàbí “òkúta tó ń mú kéèyàn rójú rere.”
^ Ní Héb., “bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”
^ Tàbí “àgbájọ omi.” Ní Héb., “jẹ́ kí omi tú jáde.”
^ Ní Héb., “Nígbà tí kò ní ọkàn láti ní in.”
^ Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”
^ Tàbí “onígbọ̀wọ́.”
^ Ní Héb., “rí ire.”
^ Tàbí “tó ń woni sàn.”
^ Tàbí “ń mú kí egungun gbẹ.”
^ Ní Héb., “àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti oókan àyà.”
^ Ní Héb., “ìkorò.”
^ Tàbí “bu owó ìtanràn lé.”
^ Ní Héb., “máa ń tutù ní ẹ̀mí.”