Òwe 19:1-29

  • Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ (11)

  • Oníjà aya dà bí òrùlé tó ń jò (13)

  • Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti wá (14)

  • Bá ọmọ wí nígbà tí ìrètí ṣì wà (18)

  • Ọgbọ́n tó wà nínú kéèyàn máa gba ìmọ̀ràn (20)

19  Ó sàn kéèyàn jẹ́ aláìní àmọ́ kó máa rìn nínú ìwà títọ́+Ju kéèyàn jẹ́ òmùgọ̀ kó sì máa parọ́.+   Kò dára kí èèyàn* wà láìní ìmọ̀,+Ẹ̀ṣẹ̀ sì ni kéèyàn máa fi wàdùwàdù ṣe nǹkan.*   Ìwà òmùgọ̀ èèyàn ló ń lọ́ ọ̀nà rẹ̀ po,Tí ọkàn rẹ̀ fi ń bínú gidigidi sí Jèhófà.   Ọrọ̀ ń mú kéèyàn ní ọ̀rẹ́ púpọ̀,Àmọ́ ọ̀rẹ́ tálákà pàápàá yóò fi í sílẹ̀.+   Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,+Ẹni tí kò sì lè ṣe kó má parọ́ kò ní yè bọ́.+   Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ojú rere èèyàn pàtàkì,*Gbogbo èèyàn ló sì ń bá ẹni tó ń fúnni lẹ́bùn ṣọ̀rẹ́.   Gbogbo ọmọ ìyá tálákà máa ń kórìíra rẹ̀;+Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó pa á tì!+ Ó ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ wọn ṣáá, àmọ́ kò sẹ́ni tó dá a lóhùn.   Ẹni tó ní làákàyè* fẹ́ràn ara* rẹ̀.+ Ẹni tó fi òye ṣe ìṣúra yóò ṣàṣeyọrí.*+   Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,Ẹni tí kò sì lè ṣe kó má parọ́ yóò ṣègbé.+ 10  Kò yẹ kí òmùgọ̀ máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ;Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí ìránṣẹ́ máa ṣe olórí àwọn ìjòyè!+ 11  Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀,+Ẹwà ló sì jẹ́ fún un pé kó gbójú fo* àṣìṣe.*+ 12  Ìrunú ọba dà bí ìgbà tí kìnnìún* bá ń kùn,+Àmọ́ ojú rere rẹ̀ dà bí ìrì lára ewéko. 13  Òmùgọ̀ ọmọ ń fa àjálù bá bàbá rẹ̀,+Oníjà* aya sì dà bí òrùlé tó ń jò ṣáá.+ 14  Ọ̀dọ̀ àwọn baba ni a ti ń jogún ilé àti ọrọ̀,Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti ń wá.+ 15  Ìwà ọ̀lẹ máa ń fa oorun àsùnwọra,Ebi yóò sì pa ẹni* tó ń ṣe ìmẹ́lẹ́.+ 16  Ẹni tó ń pa àṣẹ mọ́ ń pa ẹ̀mí* rẹ̀ mọ́;+Ẹni tí kì í kíyè sí ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.+ 17  Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+ 18  Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ìrètí ṣì wà,+Kí o má bàa jẹ̀bi* ikú rẹ̀.+ 19  Onínúfùfù yóò jìyà ìwà rẹ̀;Tí o bá gbà á sílẹ̀, wàá tún ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra.+ 20  Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí,+Kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.+ 21  Ọ̀pọ̀ nǹkan ni èèyàn ń gbèrò nínú ọkàn rẹ̀,Àmọ́ ìmọ̀ràn* Jèhófà ni yóò borí.+ 22  Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ẹwà èèyàn;+Ó sì sàn kéèyàn jẹ́ aláìní ju kí ó jẹ́ òpùrọ́. 23  Ìbẹ̀rù Jèhófà ń yọrí sí ìyè;+Ẹni tó bá ní in yóò sun oorun àsùnwọra, láìsí aburú kankan.+ 24  Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú abọ́ oúnjẹ,Àmọ́ kò wulẹ̀ janpata láti gbé e pa dà sí ẹnu.+ 25  Gbá afiniṣẹ̀sín,+ kí aláìmọ̀kan lè ní àròjinlẹ̀,+Sì bá olóye wí, kí ìmọ̀ rẹ̀ lè pọ̀ sí i.+ 26  Ẹni tó ṣe àìdáa sí bàbá rẹ̀ tó sì lé ìyá rẹ̀ lọJẹ́ ọmọ tó ń fa ìtìjú àti àbùkù.+ 27  Ọmọ mi, tí o bá ṣíwọ́ fífi etí sí ìbáwí,Wàá yà kúrò ní ọ̀nà ìmọ̀. 28  Ẹlẹ́rìí tí kò ní láárí ń fi ìdájọ́ òdodo ṣẹ̀sín,+Ẹnu èèyàn burúkú sì ń gbé ibi mì.+ 29  Ìdájọ́ ń dúró de àwọn afiniṣẹ̀sín,+Ẹgba sì ń dúró de ẹ̀yìn àwọn òmùgọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “kí ẹsẹ̀ èèyàn yá.”
Tàbí “ẹni tó lawọ́.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “rí ire.”
Ní Héb., “ọkàn.”
Ní Héb., “mójú kúrò nínú.”
Tàbí “ìṣìnà.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “Ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “èrè.”
Tàbí “fẹ́.” Ní Héb., “gbé ọkàn rẹ sí.”
Tàbí “ìpinnu.”