Òwe 21:1-31
21 Ọkàn ọba dà bí odò ní ọwọ́ Jèhófà.+
Ibi tí Ó bá fẹ́ ló ń darí rẹ̀ sí.+
2 Gbogbo ọ̀nà èèyàn máa ń tọ́ lójú ara rẹ̀,+Àmọ́ Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn.*+
3 Kí èèyàn ṣe ohun tó dára tí ó sì tọ́Máa ń mú inú Jèhófà dùn ju ẹbọ lọ.+
4 Ojú ìgbéraga àti ọkàn gígaNi fìtílà tó ń darí àwọn ẹni burúkú, ẹ̀ṣẹ̀ sì ni.+
5 Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere,*+Àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.+
6 Láti fi ahọ́n èké kó ìṣúra jọDà bí ìkùukùu tó ń pòórá, ìdẹkùn ikú ni.*+
7 Ìwà ipá àwọn ẹni burúkú yóò gbá wọn dà nù,+Torí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.
8 Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,Àmọ́ iṣẹ́ aláìlẹ́bi máa ń tọ́.+
9 Ó sàn láti máa gbé ní igun òrùléJu kéèyàn máa bá aya tó jẹ́ oníjà* gbé inú ilé kan náà.+
10 Ohun tí kò dáa ló máa ń wu ẹni* burúkú;+Kì í ṣàánú ọmọnìkejì rẹ̀.+
11 Nígbà tí wọ́n bá fìyà jẹ afiniṣẹ̀sín, aláìmọ̀kan á kọ́gbọ́n,Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá sì rí ìjìnlẹ̀ òye, á ní ìmọ̀.*+
12 Ọlọ́run Olódodo máa ń kíyè sí ilé ẹni burúkú;Ó ń dojú àwọn ẹni burúkú dé kí wọ́n lè pa run.+
13 Ẹni tó bá di etí rẹ̀ sí igbe aláìníÒun fúnra rẹ̀ yóò pè, a kò sì ní dá a lóhùn.+
14 Ẹ̀bùn tí a fúnni ní ìkọ̀kọ̀ ń mú ìbínú rọlẹ̀,+Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a sì fúnni ní bòókẹ́lẹ́* ń mú ìbínú gbígbóná rọlẹ̀.
15 Inú olódodo máa ń dùn láti ṣe ohun tó bá ẹ̀tọ́ mu,+Àmọ́ ó ṣòro gan-an fún àwọn tó ń hùwà burúkú.
16 Ẹni tó bá fi ọ̀nà ìjìnlẹ̀ òye sílẹ̀Á sinmi pẹ̀lú àwọn tí ikú ti pa.*+
17 Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ fàájì* yóò di aláìní;+Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ wáìnì àti òróró kò ní lówó lọ́wọ́.
18 Ẹni burúkú ni ìràpadà fún olódodo,A ó sì mú oníbékebèke dípò adúróṣinṣin.+
19 Ó sàn láti máa gbé ní aginjùJu kéèyàn máa bá aya tó jẹ́ oníjà* àti oníkanra gbé.+
20 Ìṣúra tó ṣeyebíye àti òróró máa ń wà ní ilé ọlọ́gbọ́n,+Àmọ́ òmùgọ̀ èèyàn máa ń fi ohun tó ní ṣòfò.*+
21 Ẹni tó bá ń wá òdodo àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀Yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.+
22 Ọlọ́gbọ́n lè gun* ìlú àwọn alágbáraKí ó sì mú agbára tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé balẹ̀.+
23 Ẹni tó bá ń ṣọ́ ẹnu àti ahọ́n rẹ̀Ń pa ara* rẹ̀ mọ́ lọ́wọ́ wàhálà.+
24 Agbéraga tó ń fọ́nnu tó sì ń kọjá àyè rẹ̀Là ń pe ẹni tó ń fi wàdùwàdù ṣe nǹkan láìbìkítà.+
25 Ohun tó ń wu ọ̀lẹ ló máa pa á,Nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.+
26 Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ló ń ṣojúkòkòrò,Àmọ́ olódodo ń fúnni láìfawọ́ nǹkan kan sẹ́yìn.+
27 Ẹbọ ẹni burúkú jẹ́ ohun ìríra.+
Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kó mú un wá pẹ̀lú èrò ibi!*
28 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé,+Àmọ́ ẹ̀rí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ yóò fìdí múlẹ̀.*
29 Èèyàn burúkú máa ń lo ògbójú,+Àmọ́ adúróṣinṣin ni ọ̀nà rẹ̀ dájú.*+
30 Kò sí ọgbọ́n tàbí òye tàbí ìmọ̀ràn tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.+
31 Èèyàn lè ṣètò ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun,+Àmọ́ ti Jèhófà ni ìgbàlà.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “èrò ọkàn.”
^ Tàbí “àǹfààní.”
^ Tàbí kó jẹ́, “fún àwọn tó ń wá ikú.”
^ Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”
^ Tàbí “ọkàn ẹni.”
^ Tàbí “mọ ohun tó yẹ kó ṣe.”
^ Ní Héb., “ní àyà.”
^ Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”
^ Tàbí “ìgbádùn.”
^ Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”
^ Ní Héb., “gbé ohun tó ní mì.”
^ Tàbí “borí.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “pẹ̀lú ìwà tó ń tini lójú.”
^ Ní Héb., “ẹni tó ń fetí sílẹ̀ yóò máa sọ̀rọ̀ títí láé.”
^ Tàbí “ló ń mú kí ọ̀nà rẹ̀ dájú.”