Òwe 22:1-29
22 Orúkọ rere* ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀;+Kéèyàn níyì* sàn ju fàdákà àti wúrà.
2 Ohun tí ọlọ́rọ̀ àti aláìní fi jọra* ni pé:
Jèhófà ló dá àwọn méjèèjì.+
3 Ọlọ́gbọ́n* rí ewu, ó sì fara pa mọ́,Àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.*
4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù JèhófàNi ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.+
5 Ẹ̀gún àti pańpẹ́ wà ní ọ̀nà onímàgòmágó,Àmọ́ ẹni tí ẹ̀mí* rẹ̀ bá jọ lójú yóò jìnnà réré sí wọn.+
6 Tọ́ ọmọdé* ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀;+Kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.+
7 Ọlọ́rọ̀ ń ṣàkóso àwọn aláìní,Ẹni tó yá nǹkan sì ni ẹrú ẹni tó yá a ní nǹkan.+
8 Ẹni tó bá gbin àìṣòdodo yóò ká àjálù,+Ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò sì ṣègbé.+
9 Ọ̀làwọ́* yóò gba ìbùkún,Nítorí ó ń fún aláìní lára oúnjẹ rẹ̀.+
10 Lé afiniṣẹ̀sín lọ,Ìjà á tán nílẹ̀;Àríyànjiyàn* àti àbùkù á sì dópin.
11 Ẹni tó fẹ́ràn ọkàn tó mọ́, tó sì lọ́rọ̀ rere lẹ́nu,Yóò di ọ̀rẹ́ ọba.+
12 Ojú Jèhófà ń ṣọ́ ìmọ̀,Àmọ́ Ó ń dojú ọ̀rọ̀ oníbékebèke dé.+
13 Ọ̀lẹ ń sọ pé: “Kìnnìún wà níta!
Àárín gbàgede ìlú ló máa pa mí sí!”+
14 Kòtò jíjìn ni ẹnu obìnrin oníwàkiwà.*+
Ẹni tí Jèhófà dá lẹ́bi yóò já sínú rẹ̀.
15 Ọkàn ọmọdé* ni ìwà òmùgọ̀ dì sí,+Àmọ́ ọ̀pá ìbáwí yóò mú un jìnnà sí i.+
16 Ẹni tó ń lu aláìní ní jìbìtì láti túbọ̀ kó ọrọ̀ jọ+Àti ẹni tó ń fún ọlọ́rọ̀ lẹ́bùnYóò di aláìní.
17 Fetí sílẹ̀ kí o sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n,+Kí o lè fi ọkàn rẹ sí ìmọ̀ mi,+
18 Nítorí ó dára pé kí o pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,+Kí gbogbo wọn lè máa wà ní ètè rẹ nígbà gbogbo.+
19 Kí o lè gbẹ́kẹ̀ lé JèhófàNi mo ṣe ń fún ọ ní ìmọ̀ lónìí.
20 Ǹjẹ́ mi ò ti kọ̀wé sí ọ,Láti fún ọ ní ìmọ̀ràn àti ìmọ̀,
21 Láti kọ́ ọ ní ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òótọ́ tó sì ṣe é gbára lé,Kí o lè pa dà lọ jẹ́ iṣẹ́ tó péye fún ẹni tó rán ọ?
22 Má ja tálákà lólè torí pé kò ní lọ́wọ́,+Má sì fojú aláìní gbolẹ̀ ní ẹnubodè,+
23 Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò gba ẹjọ́ wọn rò+Yóò sì gba ẹ̀mí* àwọn tó lù wọ́n ní jìbìtì.
24 Má ṣe bá onínúfùfù kẹ́gbẹ́,Má sì bá ẹni tó máa ń tètè bínú da nǹkan pọ̀,
25 Kí o má bàa kọ́ àwọn ọ̀nà rẹ̀,Kí o sì kó ara* rẹ sínú ìdẹkùn.+
26 Má ṣe wà lára àwọn tó ń bọ ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ́,Tí wọ́n ń ṣe onídùúró fún ẹni tó ń yá owó.+
27 Tí o kò bá rí i san,Wọ́n á gba ibùsùn rẹ kúrò lábẹ́ rẹ!
28 Má ṣe sún ààlà àtọjọ́mọ́jọ́ sẹ́yìnÈyí tí àwọn baba ńlá rẹ pa.+
29 Ǹjẹ́ o ti rí ọkùnrin tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀?
Yóò dúró níwájú àwọn ọba;+Kò ní dúró níwájú àwọn èèyàn yẹpẹrẹ.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Ojú rere.”
^ Ní Héb., “Orúkọ.”
^ Ní Héb., “bára pàdé.”
^ Tàbí “Aláròjinlẹ̀.”
^ Tàbí “jìyà àbájáde rẹ̀.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọ̀dọ́.” Ní Héb., “ọmọdékùnrin.”
^ Ní Héb., “Ẹni tó ní ojú tó dára.”
^ Tàbí “Ẹjọ́.”
^ Tàbí “ọ̀dọ́.” Ní Héb., “ọmọdékùnrin.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”