Òwe 23:1-35

  • Máa lo làákàyè tí wọ́n bá ń ṣe ọ́ lálejò (2)

  • Má ṣe máa lé ọrọ̀ (4)

  • Ọrọ̀ lè fò lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ (5)

  • Má ṣe wà lára àwọn tó ń mutí lámujù (20)

  • Ọtí máa ń buni ṣán bí ejò (32)

23  Nígbà tí o bá jókòó láti bá ọba jẹun,Fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó wà níwájú rẹ;   Fi ọ̀bẹ sí ara rẹ lọ́fun*Tó bá jẹ́ pé oúnjẹ púpọ̀ lo máa ń jẹ.*   Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ aládùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú,Torí oúnjẹ ẹ̀tàn ni.   Má fi wàhálà pa ara rẹ torí kí o lè kó ọrọ̀ jọ.+ Fara balẹ̀ kí o sì lo òye.*   Nígbà tí o bá bojú wò ó, kò ní sí níbẹ̀,+Torí ó dájú pé ó máa hu ìyẹ́ bí ẹyẹ idì, á sì fò lọ sójú ọ̀run.+   Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tó ń ṣahun;*Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ aládùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú.   Nítorí ó dà bí ẹni tó ń ṣe àkọsílẹ̀.* Ó ń sọ fún ọ pé, “máa jẹ, máa mu,” àmọ́ kò dénú rẹ̀.*   Wàá pọ àwọn òkèlè tí o ti gbé mìÀwọn ọ̀rọ̀ ti o fi yìn ín á sì di àsọdànù.   Má ṣe sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀,+Nítorí kò ní ka ọgbọ́n tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ sí.+ 10  Má ṣe sún ààlà àtọjọ́mọ́jọ́ sẹ́yìn,+Má sì wọnú ilẹ̀ àwọn aláìníbaba. 11  Nítorí Olùgbèjà* wọn lágbára;Yóò pè ọ́ lẹ́jọ́ nítorí wọn.+ 12  Fi ọkàn sí ìbáwíKí o sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀. 13  Má fawọ́ ìbáwí sẹ́yìn fún ọmọdé.*+ Tí o bá fi ọ̀pá nà án, kò ní kú. 14  Fi ọ̀pá nà án,Kí o lè gbà á* lọ́wọ́ Isà Òkú.* 15  Ọmọ mi, tí ọkàn rẹ bá gbọ́n,Ọkàn tèmi náà á yọ̀.+ 16  Inú mi* á dùn dé ìsàlẹ̀ ikùnNígbà tí ètè rẹ bá sọ ohun tí ó tọ́. 17  Kí ọkàn rẹ má ṣe jowú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+Àmọ́ kí o máa bẹ̀rù Jèhófà láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,+ 18  Ìgbà náà ni ọjọ́ ọ̀la rẹ á dára+Ìrètí rẹ kò sì ní pa rẹ́. 19  Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,Darí ọkàn rẹ lọ́nà tí ó tọ́. 20  Má ṣe wà lára àwọn tó ń mu wáìnì lámujù,+Tàbí àwọn tó ń jẹ ẹran ní àjẹkì,+ 21  Nítorí ọ̀mùtí àti alájẹkì yóò di òtòṣì,+Ìtòògbé yóò sì sọni di alákìísà. 22  Fetí sí bàbá rẹ tó bí ọ lọ́mọ,Má sì pa ìyá rẹ tì torí pé ó ti darúgbó.+ 23  Ra* òtítọ́, má sì tà á láé,+Bákan náà, ra ọgbọ́n àti ìbáwí àti òye.+ 24  Bàbá olódodo yóò máa láyọ̀;Ẹni tó bá sì bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóò yọ̀. 25  Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò máa yọ̀,Inú ìyá tó bí ọ yóò sì máa dùn. 26  Ọmọ mi, fi ọkàn rẹ fún mi,Kí ojú rẹ sì fẹ́ràn àwọn ọ̀nà mi.+ 27  Nítorí pé kòtò jíjìn ni aṣẹ́wó,Kànga tóóró sì ni obìnrin oníṣekúṣe.*+ 28  Ó máa ń lúgọ deni bí ọlọ́ṣà;+Ó ń mú kí àwọn ọkùnrin aláìṣòótọ́ pọ̀ sí i. 29  Ta ló ni ìyà? Ta ló ni àìnírọ̀rùn? Ta ló ni ìjà? Ta ló ni àròyé? Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú tó ń ṣe bàìbàì?* 30  Àwọn tó ń pẹ́ nídìí wáìnì ni;+Àwọn tó ń wá àdàlù wáìnì kàn.* 31  Má ṣe wo àwọ̀ pupa wáìnìBó ṣe ń ta wíríwírí nínú ife, tó sì ń lọ tìnrín, 32  Torí níkẹyìn, á buni ṣán bí ejò,Á sì tu oró jáde bíi paramọ́lẹ̀. 33  Ojú rẹ yóò rí àwọn ohun àjèjì,Ọkàn rẹ yóò sì sọ àwọn ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.+ 34  Wàá dà bí ẹni tó dùbúlẹ̀ sí àárín òkun,Bí ẹni tó dùbúlẹ̀ sí orí òpó ọkọ̀ òkun. 35  Wàá sọ pé: “Wọ́n lù mí, àmọ́ mi ò mọ̀ ọ́n lára.* Wọ́n nà mí, àmọ́ mi ò mọ̀. Ìgbà wo ni màá jí?+ Ẹ fún mi lọ́tí sí i.”*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Kó ara rẹ níjàánu.”
Tàbí “pé ọkàn rẹ ń fẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan.”
Tàbí kó jẹ́, “Jáwọ́ nínú lílo òye tìrẹ.”
Tàbí “ẹni tó ń fojú burúkú wo èèyàn.”
Tàbí “tó ń ṣe ìṣírò nínú ọkàn rẹ̀.”
Ní Héb., “ọkàn rẹ̀ kò wà pẹ̀lú rẹ.”
Ní Héb., “Olùràpadà.”
Tàbí “ọ̀dọ́.” Ní Héb., “ọmọdékùnrin.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “kíndìnrín mi.”
Tàbí “Ní.”
Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.
Tàbí “tó tín-ín-rín.”
Tàbí “Àwọn tó ń kóra jọ láti wo bí àdàlù wáìnì ṣe ń rí lára.”
Tàbí “kò dùn mí.”
Tàbí “Màá wá a lẹ́ẹ̀kan sí i.”