Òwe 25:1-28
25 Àwọn òwe míì tí Sólómọ́nì pa,+ èyí tí àwọn ọkùnrin Hẹsikáyà+ ọba Júdà dà kọ* nìyí:
2 Ògo Ọlọ́run ni láti pa ọ̀rọ̀ mọ́ ní àṣírí,+Ògo àwọn ọba sì ni láti wádìí ọ̀rọ̀ kínníkínní.
3 Bí ọ̀run ṣe ga, tí ilẹ̀ sì jìn,Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn àwọn ọba jẹ́ ohun àwámáridìí.
4 Yọ́ ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà,Á sì mọ́ pátápátá.+
5 Mú ẹni burúkú kúrò níwájú ọba,Ìtẹ́ rẹ̀ yóò sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú òdodo.+
6 Má bọlá fún ara rẹ níwájú ọba,+Má sì jókòó ní àyè àwọn ẹni ńlá,+
7 Nítorí ó sàn kó sọ fún ọ pé, “Máa bọ̀ níbí,”Ju pé kó kàn ọ́ lábùkù níwájú àwọn èèyàn pàtàkì.+
8 Má fi ìkánjú gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́,Àbí kí lo máa ṣe tí ọmọnìkejì rẹ bá kàn ọ́ lábùkù?+
9 Ro ẹjọ́ rẹ pẹ̀lú ọmọnìkejì rẹ,+Àmọ́ má sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tí o gbọ́,*+
10 Kí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ má bàa kó ìtìjú bá ọ,Ọ̀rọ̀ burúkú* tí o tàn kálẹ̀ kò sì ní ṣeé kó pa dà.
11 Bí àwọn èso ápù oníwúrà tó wà nínú abọ́* fàdákàNi ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.+
12 Bíi yẹtí wúrà àti ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n fi wúrà tó dára ṣeNi ọlọ́gbọ́n tó ń báni wí jẹ́ ní etí ẹni tó ń gbọ́ràn.+
13 Bí ìtutù yìnyín ní ọjọ́ ìkórèNi òjíṣẹ́ olóòótọ́ jẹ́ fún àwọn tó rán an,Nítorí ó ń mára tu ọ̀gá rẹ̀.*+
14 Bí òjò tó ṣú, tó sì ń fẹ́ atẹ́gùn àmọ́ tí kò rọ̀Ni ọkùnrin tó ń fọ́nnu lórí ẹ̀bùn tí kò ní fúnni.*+
15 Sùúrù la fi ń yí aláṣẹ lọ́kàn pa dà,Ahọ́n pẹ̀lẹ́* sì lè fọ́ egungun.+
16 Tí o bá rí oyin, èyí tí o nílò nìkan ni kí o jẹ,Torí tí o bá jẹ ẹ́ ní àjẹjù, o lè bì í.+
17 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ṣe lemọ́lemọ́ ní ilé ọmọnìkejì rẹ,Kí ọ̀rọ̀ rẹ má bàa sú u, kó sì kórìíra rẹ.
18 Bíi kùmọ̀ ogun àti idà àti ọfà tó múNi ẹni tó ń jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ̀.+
19 Bí eyín tó ká tàbí ẹsẹ̀ tó ń gbò yèpéyèpéNi ìgbọ́kànlé téèyàn ní nínú ẹni tí kò ṣe é fọkàn tán* lásìkò wàhálà.
20 Bí ẹni tó bọ́ aṣọ lọ́jọ́ òtútùÀti bí ọtí kíkan tí wọ́n dà sórí sódà*Ni ẹni tó ń kọrin fún ọkàn tí ìbànújẹ́ bá.+
21 Tí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ,* fún un ní oúnjẹ jẹ;Tí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu,+
22 Torí ṣe ni wàá máa kó ẹyin iná jọ lé e lórí,*+Jèhófà yóò sì san èrè fún ọ.
23 Ẹ̀fúùfù láti àríwá ń mú kí òjò rọ̀,Ahọ́n tó ń ṣòfófó sì ń mú kí ojú fà ro.+
24 Ó sàn láti máa gbé ní igun òrùléJu kéèyàn máa bá aya tó jẹ́ oníjà* gbé inú ilé kan náà.+
25 Bí omi tútù lára ẹni* tí àárẹ̀ múNi ìròyìn rere láti ilẹ̀ tó jìnnà.+
26 Bí ìsun omi tó rú àti kànga tó ti bà jẹ́Ni olódodo tó gbà fún* ẹni burúkú.
27 Kò dára láti jẹ oyin ní àjẹjù,+Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ògo kankan nínú kéèyàn máa wá ògo ara rẹ̀.+
28 Bí ìlú tí a ya wọ̀, tí kò ní ògiri,Ni ẹni tí kò lè kápá ìbínú* rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “dà kọ, tí wọ́n sì kó jọ.”
^ Tàbí “àṣírí ẹlòmíì.”
^ Tàbí “Àhesọ ọ̀rọ̀ tó ń bani lórúkọ jẹ́.”
^ Tàbí “férémù.”
^ Tàbí “ó ń tu ọkàn ọ̀gá rẹ̀ lára.”
^ Ní Héb., “ẹ̀bùn èké.”
^ Tàbí “Ọ̀rọ̀ tútù.”
^ Tàbí kó jẹ́, “oníbékebèke.”
^ Tàbí “ákáláì.”
^ Ní Héb., “ẹni tó kórìíra rẹ.”
^ Ìyẹn, láti mú kí ọkàn ẹni náà rọ̀, kí inú rẹ̀ sì yọ́.
^ Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”
^ Ní Héb., “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “tó fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú.” Ní Héb., “ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ níwájú.”
^ Tàbí “ẹ̀mí.”