Òwe 3:1-35
3 Ọmọ mi, má gbàgbé ẹ̀kọ́* mi,Sì jẹ́ kí ọkàn rẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́,
2 Nítorí wọ́n á fi ọ̀pọ̀ ọjọ́Àti ẹ̀mí gígùn pẹ̀lú àlàáfíà kún un fún ọ.+
3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́* fi ọ́ sílẹ̀.+
So wọ́n mọ́ ọrùn rẹ;Kọ wọ́n sí wàláà ọkàn rẹ;+
4 Nígbà náà, wàá rí ojú rere àti òye tó jinlẹ̀ gan-anLójú Ọlọ́run àti èèyàn.+
5 Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+Má sì gbára lé òye tìrẹ.+
6 Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ,+Á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.+
7 Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ.+
Bẹ̀rù Jèhófà kí o sì yẹra fún ibi.
8 Yóò jẹ́ ìwòsàn fún ara* rẹÀti ìtura fún egungun rẹ.
9 Fi àwọn ohun ìní rẹ tó níye lórí bọlá fún Jèhófà,+Pẹ̀lú àkọ́so* gbogbo irè oko rẹ;*+
10 Nígbà náà, àwọn ilé ìkẹ́rùsí rẹ á kún fọ́fọ́,+Wáìnì tuntun á sì kún àwọn ẹkù* rẹ ní àkúnwọ́sílẹ̀.
11 Ọmọ mi, má ṣe kọ ìbáwí Jèhófà,+Má sì kórìíra ìtọ́sọ́nà rẹ̀,+
12 Torí pé àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí,+Bí bàbá ṣe máa ń fún ọmọ tí inú rẹ̀ dùn sí ní ìbáwí.+
13 Aláyọ̀ ni ẹni tó wá ọgbọ́n rí+Àti ẹni tó ní òye;
14 Kéèyàn ní in sàn ju kéèyàn ní fàdákà,Kéèyàn jèrè rẹ̀ sì sàn ju kéèyàn jèrè wúrà.+
15 Ó ṣeyebíye ju iyùn* lọ;Kò sí ohun míì tí o fẹ́ tó ṣeé fi wé e.
16 Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;Ọrọ̀ àti ògo sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.
17 Àwọn ọ̀nà rẹ̀ gbádùn mọ́ni,Àlàáfíà sì wà ní gbogbo ipa ọ̀nà rẹ̀.+
18 Igi ìyè ni fún àwọn tó dì í mú,Aláyọ̀ ni a ó sì máa pe àwọn tó dì í mú ṣinṣin.+
19 Ọgbọ́n ni Jèhófà fi dá ayé.+
Òye ni ó fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in.+
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni àwọn ibú omi fi pínyàTí ìkùukùu ojú sánmà sì ń mú kí ìrì sẹ̀.+
21 Ọmọ mi, máa fi wọ́n* sọ́kàn.
Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́;
22 Wọ́n á fún ọ* ní ìyèWọ́n á sì jẹ́ ọ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ;
23 Nígbà náà, wàá máa rìn láìséwu ní ọ̀nà rẹ,Ẹsẹ̀ rẹ kò sì ní kọ́* ohunkóhun.+
24 Nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, ẹ̀rù ò ní bà ọ́;+Wàá sùn, oorun rẹ á sì dùn mọ́ ọ.+
25 O ò ní bẹ̀rù àjálù òjijì+Tàbí ìjì tó ń bọ̀ lórí àwọn ẹni burúkú.+
26 Nítorí Jèhófà yóò jẹ́ ìgbọ́kànlé rẹ;+Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kó sí pańpẹ́.+
27 Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fún*+Tó bá wà níkàáwọ́ rẹ* láti ṣe é.+
28 Má sọ fún ọmọnìkejì rẹ pé, “Máa lọ ná, tó bá dọ̀la kí o pa dà wá, màá fún ọ,”Nígbà tí o lè fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
29 Má gbèrò ibi sí ọmọnìkejì rẹ+Nígbà tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ pé kò séwu.
30 Má ṣe bá ẹnì kankan jà láìnídìí+Nígbà tí kò ṣe aburú kankan sí ọ.+
31 Má ṣe jowú ẹni tó ń hùwà ipá+Má sì yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀,
32 Nítorí Jèhófà kórìíra oníbékebèke,+Ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.+
33 Ègún Jèhófà wà lórí ilé ẹni burúkú,+Àmọ́, ó ń bù kún ilé àwọn olódodo.+
34 Ó ń fi àwọn afiniṣẹ̀sín ṣe ẹlẹ́yà,+Àmọ́, ó ń ṣojú rere sí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+
35 Àwọn ọlọ́gbọ́n á jogún ọlá,Àmọ́, ẹ̀tẹ́ ni àwọn òmùgọ̀ fi ń ṣayọ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “òfin.”
^ Tàbí “òtítọ́.”
^ Ní Héb., “ìdodo.”
^ Tàbí “èyí tó dára jù lọ nínú.”
^ Tàbí “owó tó ń wọlé fún ọ.”
^ Tàbí “àwọn ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ó ṣe kedere pé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí àwọn ẹsẹ tó ṣáájú mẹ́nu bà ló ń tọ́ka sí.
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “gbá.”
^ Tàbí “Tí o bá lágbára.”
^ Tàbí “àwọn tí ó tọ́ sí.”