Ọbadáyà 1:1-21

  • Ọlọ́run yóò rẹ Édómù agbéraga wálẹ̀ (1-9)

  • Édómù hùwà ipá sí Jékọ́bù (10-14)

  • Ọjọ́ tí Jèhófà yóò gbéjà ko gbogbo orílẹ̀-èdè (15, 16)

  • Ilé Jékọ́bù yóò pa dà sí àyè rẹ̀ (17-21)

    • Jékọ́bù yóò pa Édómù run (18)

    • Ipò ọba yóò di ti Jèhófà (21)

 Ìran tí Ọbadáyà* rí: Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nípa Édómù nìyí:+ “A ti gbọ́ ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà,Aṣojú kan ti lọ jíṣẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé: ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká múra láti bá a jagun.’”+   “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;O ti tẹ́ pátápátá.+   Ìgbéraga* ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,+Ìwọ tó ń gbé ihò inú àpáta,Ìwọ tó ń gbé ibi gíga, tí o sì ń sọ nínú ọkàn rẹ pé,‘Ta ló lè rẹ̀ mí wálẹ̀?’   Bí o bá tiẹ̀ kọ́lé sí ibi gíga* bí ẹyẹ idì,Tàbí tí o kọ́ ìtẹ́ rẹ sáàárín àwọn ìràwọ̀,Màá rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ láti ibẹ̀,” ni Jèhófà wí.   “Bí àwọn olè bá wá bá ọ, àwọn ọlọ́ṣà ní òru,(Ṣe ni wọ́n á run ọ́!)* Ṣebí ohun tí wọ́n bá fẹ́ nìkan ni wọ́n á kó? Tó bá sì jẹ́ àwọn tó ń kó èso àjàrà jọ ló wá bá ọ,Ṣé wọn ò ní ṣẹ́ díẹ̀ kù fáwọn tó ń pèéṣẹ́?*+   Ẹ wo bí wọ́n ṣe wá Ísọ̀ kàn! Gbogbo ìṣúra tó fi pa mọ́ ni wọ́n ti wá jáde!   Wọ́n ti lé ọ títí dé ẹnubodè. Gbogbo àwọn tó bá ọ ṣàdéhùn* ti tàn ọ́ jẹ. Àwọn tí ẹ jọ wà ní àlàáfíà ti borí rẹ. Àwọn tí ẹ jọ ń jẹun* yóò dẹ àwọ̀n dè ọ́,Àmọ́ ìwọ kò ní mọ̀.   Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà wí,“Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n run kúrò ní Édómù+Èmi yóò sì pa òye run ní agbègbè olókè Ísọ̀.   Ẹ̀rù yóò ba àwọn jagunjagun rẹ,+ ìwọ Témánì,+Torí gbogbo ẹni tó wà ní agbègbè olókè Ísọ̀ ni yóò ṣègbé nítorí ìpakúpa.+ 10  Nítorí ìwà ìkà tí o hù sí Jékọ́bù ọmọ ìyá rẹ,+Ojú yóò tì ọ́,+Ìwọ yóò sì ṣègbé títí láé.+ 11  Ní ọjọ́ tí ìwọ ta kété sí ẹ̀gbẹ́ kan,Ní ọjọ́ tí àwọn àjèjì mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́rú,+Nígbà tí àwọn àjèjì gba ẹnubodè rẹ̀ wọlé, tí wọ́n sì ṣẹ́ kèké+ lórí Jerúsálẹ́mù,Ìwọ náà ṣe bíi tiwọn. 12  Kò yẹ kí o fi ọmọ ìyá rẹ ṣe yẹ̀yẹ́ ní ọjọ́ tí àjálù bá a,+Kò yẹ kí o yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà ní ọjọ́ tí wọ́n ń ṣègbé lọ,+Kò sì yẹ kí o máa fọ́nnu ní ọjọ́ wàhálà wọn. 13  Kò yẹ kí o wọ ìlú* àwọn èèyàn mi ní ọjọ́ àjálù wọn,+Kò yẹ kí o fi í ṣe yẹ̀yẹ́ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀,Kò sì yẹ kí o fọwọ́ kan ohun ìní rẹ̀ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀.+ 14  Kò yẹ kí o dúró sí oríta láti pa àwọn èèyàn rẹ̀ tó ń sá lọ,+Kò sì yẹ kí o fi àwọn èèyàn rẹ̀ tó yè bọ́ ní ọjọ́ wàhálà lé ọ̀tá lọ́wọ́.+ 15  Nítorí ọjọ́ tí Jèhófà fẹ́ bá gbogbo orílẹ̀-èdè jà ti sún mọ́lé.+ Ohun tí o ṣe ni wọn yóò ṣe sí ọ.+ Ìwà tí o hù sí àwọn èèyàn ni wọn yóò hù sí ọ. 16  Bí o ṣe mu wáìnì lórí òkè mímọ́ mi,Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa mu ìbínú mi nígbà gbogbo.+ Wọn yóò rọ́ ọ sí ọ̀fun, wọn yóò sì gbé e mì,Yóò sì dà bíi pé wọn kò gbé ayé rí. 17  Àmọ́ àwọn tó sá àsálà yóò wà lórí Òkè Síónì,+Yóò sì di mímọ́;+Ilé Jékọ́bù yóò sì gba àwọn nǹkan tó jẹ́ tiwọn.+ 18  Ilé Jékọ́bù yóò di iná,Ilé Jósẹ́fù yóò di ọwọ́ iná,Ilé Ísọ̀ yóò sì dà bí àgékù pòròpórò;Wọn yóò ti iná bọ̀ wọ́n, wọn yóò sì run wọ́n,Ẹnikẹ́ni kì yóò sì là á já ní ilé Ísọ̀,+Torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́. 19  Wọn yóò gba Négébù àti agbègbè olókè Ísọ̀,+Agbègbè Ṣẹ́fẹ́là àti ilẹ̀ àwọn Filísínì.+ Wọn yóò gba ilẹ̀ Éfúrémù àti ilẹ̀ Samáríà,+Bẹ́ńjámínì yóò sì gba Gílíádì. 20  Àwọn tó lọ sí ìgbèkùn látinú odi* yìí,+Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ni yóò gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì títí dé Sáréfátì.+ Àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù tó lọ sí ìgbèkùn ní Séfárádì ni yóò gba àwọn ìlú tó wà ní Négébù.+ 21  Àwọn olùgbàlà yóò sì lọ sórí Òkè Síónì Láti dá agbègbè olókè Ísọ̀ lẹ́jọ́,+Ipò ọba yóò sì di ti Jèhófà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Ìránṣẹ́ Jèhófà.”
Tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí kó jẹ́, “tiẹ̀ fò lọ sókè réré.”
Tàbí kó jẹ́, “Ohun mélòó ni wọ́n máa run?”
Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.
Tàbí “dá májẹ̀mú.”
Ní Héb., “jẹ búrẹ́dì.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “ògiri ààbò.”