Ìwé Kìíní Jòhánù 4:1-21

  • Ẹ dán àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí wò (1-6)

  • Ẹ mọ Ọlọ́run, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (7-21)

    • “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” (8, 16)

    • Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́ (18)

4  Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má gba gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí*+ gbọ́, àmọ́ kí ẹ dán àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí* wò kí ẹ lè mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá,+ torí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ló ti jáde lọ sínú ayé.+  Báyìí lẹ ṣe máa mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ kan tó ní ìmísí ti wá: Gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí tó bá fi hàn pé Jésù Kristi wá nínú ẹran ara jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+  Àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí tí kò bá fi hàn pé Jésù wá, kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ Bákan náà, ọ̀rọ̀ yìí ni aṣòdì sí Kristi mí sí, ẹni tí ẹ gbọ́ pé ó ń bọ̀,+ ó sì ti wà ní ayé báyìí.+  Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lẹ ti wá, ẹ sì ti ṣẹ́gun wọn,+ torí ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín+ tóbi ju ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ayé.+  Inú ayé ni wọ́n ti wá;+ ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ ohun tó wá látinú ayé, ayé sì ń fetí sí wọn.+  Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti wá. Ẹnikẹ́ni tó bá ti wá mọ Ọlọ́run ń fetí sí wa;+ ẹnikẹ́ni tí kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í fetí sí wa.+ Báyìí la ṣe ń fìyàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ní ìmísí àti ọ̀rọ̀ àṣìṣe tó ní ìmísí.+  Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa,+ torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá, gbogbo ẹni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ la ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run.+  Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, torí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.+  Bí a ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ wa nìyí, Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo+ wá sí ayé, ká lè ní ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.+ 10  Bí ìfẹ́ náà ṣe jẹ́ nìyí, kì í ṣe pé àwa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ kó lè jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+ 11  Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, tó bá jẹ́ pé bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa nìyí, àwa náà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa.+ 12  Kò sí ẹni tó rí Ọlọ́run rí.+ Tí a bá túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ ara wa, Ọlọ́run ò ní fi wá sílẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ á sì di pípé nínú wa.+ 13  Èyí la fi mọ̀ pé a wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, tí òun náà sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, torí ó ti fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀. 14  Bákan náà, àwa fúnra wa ti rí, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ wá kó lè jẹ́ olùgbàlà ayé.+ 15  Ẹnikẹ́ni tó bá gbà pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù,+ Ọlọ́run wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni yẹn, òun náà sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run.+ 16  A ti wá mọ̀, a sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa.+ Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,+ ẹni tó bá wà nínú ìfẹ́ ṣì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.+ 17  Báyìí la ṣe sọ ìfẹ́ di pípé nínú wa, ká lè sọ̀rọ̀ ní fàlàlà*+ ní ọjọ́ ìdájọ́, torí pé bí ẹni yẹn ṣe jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà jẹ́ nínú ayé yìí. 18  Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́,+ àmọ́ ìfẹ́ tó pé máa ń lé ìbẹ̀rù jáde,* torí ìbẹ̀rù máa ń ká wa lọ́wọ́ kò. Lóòótọ́, ẹni tó bá ń bẹ̀rù kò tíì di pípé nínú ìfẹ́.+ 19  A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.+ 20  Tí ẹnikẹ́ni bá sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,” síbẹ̀ tó ń kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni.+ Torí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ tó rí,+ kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.+ 21  Àṣẹ tí a gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀ nìyí, pé ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “àwọn ẹ̀mí náà.”
Ní Grk., “gbogbo ẹ̀mí.”
Tàbí “ètùtù; ohun tí a fi ń tuni lójú.”
Tàbí “ní ìgboyà.”
Tàbí “ju ìbẹ̀rù síta.”