Ìwé Kìíní Jòhánù 5:1-21
5 Gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi ni a ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ gbogbo ẹni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ ẹni tó jẹ́ ká bí ẹnì kan, máa nífẹ̀ẹ́ ẹni tí onítọ̀hún bí.
2 Ohun tí a fi mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run+ nìyí, tí a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí a sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.
3 Torí ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́;+ síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kò nira,+
4 nítorí gbogbo ẹni* tí a ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ń ṣẹ́gun ayé.+ Ohun tó sì ṣẹ́gun ayé ni ìgbàgbọ́ wa.+
5 Ta ló lè ṣẹ́gun ayé?+ Ṣebí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run ni?+
6 Jésù Kristi ni ẹni tó wá nípasẹ̀ omi àti ẹ̀jẹ̀, kò wá nípasẹ̀ omi nìkan,+ àmọ́ nípasẹ̀ omi àti nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀.+ Ẹ̀mí sì ń jẹ́rìí,+ torí pé ẹ̀mí ni òtítọ́.
7 Nítorí àwọn mẹ́ta ló ń jẹ́rìí:
8 ẹ̀mí,+ omi+ àti ẹ̀jẹ̀;+ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà níṣọ̀kan.
9 Tí a bá gba ẹ̀rí àwọn èèyàn, ẹ̀rí ti Ọlọ́run tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ. Torí ẹ̀rí tí Ọlọ́run fún wa nìyí, ẹ̀rí tó fún wa nípa Ọmọ rẹ̀.
10 Ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run ní ẹ̀rí náà nínú ara rẹ̀. Ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ti sọ ọ́ di òpùrọ́,+ torí kò ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀rí tí Ọlọ́run fún wa nípa Ọmọ rẹ̀.
11 Ẹ̀rí náà sì nìyí, pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ ìyè yìí sì wà nínú Ọmọ rẹ̀.+
12 Ẹni tó ní Ọmọ ní ìyè yìí; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọ́run kò ní ìyè yìí.+
13 Mo kọ àwọn nǹkan yìí sí ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ Ọlọ́run,+ kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+
14 Ohun tó dá wa lójú nípa rẹ̀ ni pé,*+ tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.+
15 Tí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ ohunkóhun tí a bá béèrè, a mọ̀ pé a máa rí àwọn ohun tí a béèrè gbà, torí pé a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.+
16 Tí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tó ń dẹ́ṣẹ̀ tí kò yẹ fún ikú, ó máa gbàdúrà, Ọlọ́run sì máa fún un ní ìyè,+ àní, fún àwọn tí kò dẹ́ṣẹ̀ tó yẹ fún ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó yẹ fún ikú.+ Irú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ni mi ò sọ fún un pé kó gbàdúrà nípa rẹ̀.
17 Gbogbo àìṣòdodo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,+ síbẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí kò yẹ fún ikú.
18 A mọ̀ pé gbogbo ẹni tí a ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà, àmọ́ ẹni tí a bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run* ń ṣọ́ ọ, ẹni burúkú náà ò sì lè rí i mú.*+
19 A mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti wá, àmọ́ gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.+
20 Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ti wá,+ ó sì ti jẹ́ ká ní òye* ká lè mọ ẹni tòótọ́ náà. A sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni tòótọ́ náà,+ nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. Èyí ni Ọlọ́run tòótọ́ náà àti ìyè àìnípẹ̀kun.+
21 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ máa yẹra fún àwọn òrìṣà.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “gbogbo nǹkan.”
^ Tàbí “Ohun tó jẹ́ ká máa bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà ni pé.”
^ Tàbí “dì í mú pinpin.”
^ Ìyẹn, Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.
^ Ní Grk., “agbára ìmòye; làákàyè.”