Kíróníkà Kìíní 12:1-40

  • Àwọn tó ń ti ìjọba Dáfídì lẹ́yìn (1-40)

12  Àwọn tó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Síkílágì+ nígbà tí kò lè rìn fàlàlà nítorí Sọ́ọ̀lù+ ọmọ Kíṣì nìyí, wọ́n wà lára àwọn jagunjagun tó lákíkanjú tó tì í lẹ́yìn lójú ogun.+  Ọfà* wà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì lè fi ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì+ ta òkúta+ tàbí kí wọ́n fi ta ọfà látinú ọrun. Arákùnrin Sọ́ọ̀lù ni wọ́n, láti Bẹ́ńjámínì.+  Áhíésérì àti Jóáṣì ni olórí, àwọn méjèèjì jẹ́ ọmọ Ṣémáà ará Gíbíà;+ Jésíélì àti Pélétì àwọn ọmọ Ásímáfẹ́tì,+ Bérákà, Jéhù ọmọ Ánátótì,  Iṣimáyà ará Gíbíónì,+ jagunjagun tó lákíkanjú láàárín àwọn ọgbọ̀n náà,+ òun sì ni olórí wọn; Jeremáyà, Jáhásíẹ́lì, Jóhánánì, Jósábádì ará Gédérà,  Élúsáì, Jérímótì, Bealáyà, Ṣemaráyà, Ṣẹfatáyà ọmọ Hárífù,  Ẹlikénà, Isiṣáyà, Ásárẹ́lì, Jóésà àti Jáṣóbéámù, àwọn ọmọ Kórà;+  Jóélà àti Sebadáyà àwọn ọmọ Jéróhámù ará Gédórì.  Àwọn kan lára àwọn ọmọ Gádì lọ dara pọ̀ mọ́ Dáfídì ní ibi ààbò tó wà ní aginjù;+ jagunjagun tó lákíkanjú ni wọ́n, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti kọ́ṣẹ́ ogun, wọ́n dúró wámúwámú, wọ́n mú apata ńlá àti aṣóró dání, ojú wọn dà bíi ti kìnnìún, ẹsẹ̀ wọn sì yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín lórí òkè.  Ésérì ni olórí, Ọbadáyà ìkejì, Élíábù ìkẹta, 10  Míṣímánà ìkẹrin, Jeremáyà ìkarùn-ún, 11  Átáì ìkẹfà, Élíélì ìkeje, 12  Jóhánánì ìkẹjọ, Élísábádì ìkẹsàn-án, 13  Jeremáyà ìkẹwàá, Makibánáì ìkọkànlá. 14  Àwọn ni àwọn ọmọ Gádì,+ àwọn olórí ọmọ ogun. Ẹni tó kéré jù lè kápá ọgọ́rùn-ún (100) ọmọ ogun, ẹni tó sì lágbára jù lè kápá ẹgbẹ̀rún (1,000).+ 15  Àwọn ọkùnrin yìí ló sọdá Jọ́dánì ní oṣù kìíní nígbà tí ó kún bo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tó ń gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ sápá ìlà oòrùn àti sápá ìwọ̀ oòrùn. 16  Àwọn kan lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì àti Júdà tún wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní ibi ààbò+ tó wà. 17  Ni Dáfídì bá jáde sí wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Tó bá jẹ́ pé àlàáfíà ni ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi kí ẹ lè ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi á ṣọ̀kan pẹ̀lú tiyín. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé kí ẹ lè fi mí lé ọ̀tá mi lọ́wọ́ nígbà tó jẹ́ pé mi ò ṣe ohun tí kò dáa, kí Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa rí sí i, kí ó sì ṣèdájọ́.”+ 18  Ìgbà náà ni ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé Ámásáì,*+ olórí ọgbọ̀n ọmọ ogun, ó ní: “Tìrẹ ni wá, Dáfídì, ọ̀dọ̀ rẹ sì ni a wà, ìwọ ọmọ Jésè.+ Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ, àlàáfíà fún ẹni tó ń ràn ọ́ lọ́wọ́,Nítorí Ọlọ́run rẹ ń ràn ọ́ lọ́wọ́.”+ Torí náà, Dáfídì gbà wọ́n, ó sì yàn wọ́n pé kí wọ́n wà lára àwọn olórí ọmọ ogun. 19  Àwọn kan lára ẹ̀yà Mánásè náà sá wá sọ́dọ̀ Dáfídì nígbà tó tẹ̀ lé àwọn Filísínì láti wá bá Sọ́ọ̀lù jà. Àmọ́ kò lè ran àwọn Filísínì lọ́wọ́, torí lẹ́yìn tí wọ́n gbàmọ̀ràn, àwọn alákòóso Filísínì+ ní kó pa dà, wọ́n ní: “Ó máa sá lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù olúwa rẹ̀, ẹ̀mí wa ló sì máa lọ sí i.”+ 20  Nígbà tó lọ sí Síkílágì,+ àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ látinú ẹ̀yà Mánásè ni: Ádínáhì, Jósábádì, Jédáélì, Máíkẹ́lì, Jósábádì, Élíhù àti Sílétáì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.+ 21  Wọ́n ran Dáfídì lọ́wọ́ láti gbéjà ko àwọn jàǹdùkú* nítorí gbogbo wọn jẹ́ alágbára, wọ́n nígboyà,+ wọ́n sì wá di olórí àwọn ọmọ ogun. 22  Ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn ń wá sọ́dọ̀ Dáfídì+ láti ràn án lọ́wọ́, títí ibẹ̀ fi di ibùdó tí ó tóbi bí ibùdó Ọlọ́run.+ 23  Iye àwọn olórí ọmọ ogun tó ti gbára dì tó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì+ láti fi í jọba ní ipò Sọ́ọ̀lù nìyí gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Jèhófà pa.+ 24  Àwọn èèyàn Júdà tó ń gbé apata ńlá àti aṣóró jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (6,800) ọmọ ogun tó ti gbára dì fún ogun. 25  Lára àwọn ọmọ Síméónì, àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ alágbára, tí wọ́n sì nígboyà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún (7,100). 26  Lára àwọn ọmọ Léfì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (4,600). 27  Jèhóádà+ ni aṣáájú àwọn ọmọ Áárónì,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (3,700) ló sì wà pẹ̀lú rẹ̀ 28  àti Sádókù,+ ọ̀dọ́kùnrin kan tó lágbára, tó sì nígboyà pẹ̀lú àwọn olórí méjìlélógún (22) láti agbo ilé bàbá rẹ̀. 29  Lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, àwọn arákùnrin Sọ́ọ̀lù, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000),+ tí èyí tó pọ̀ jù lára wọn sì ti ń ṣọ́ ilé Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀. 30  Lára àwọn ọmọ Éfúrémù, ọ̀kẹ́ kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (20,800) alágbára àti onígboyà ọkùnrin ló jẹ́ olókìkí ní agbo ilé bàbá wọn. 31  Lára ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) ni a yan orúkọ wọn pé kí wọ́n wá fi Dáfídì jọba. 32  Lára àwọn ọmọ Ísákà, àwọn tó mọ ohun tó yẹ ní àkókò tó yẹ, tí wọ́n sì mọ ohun tó yẹ kí Ísírẹ́lì ṣe, igba (200) lára àwọn olórí wọn ló wà níbẹ̀, gbogbo àwọn arákùnrin wọn sì wà lábẹ́ àṣẹ wọn. 33  Lára Sébúlúnì, ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (50,000) ọkùnrin ló wà tó lè ṣiṣẹ́ ogun, wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ pẹ̀lú ohun ìjà tí wọ́n fi ń jagun, gbogbo wọn dara pọ̀ mọ́ Dáfídì, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i délẹ̀.* 34  Lára Náfútálì, ẹgbẹ̀rún (1,000) àwọn olórí ló wà, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì (37,000) ló sì wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n gbé apata ńlá àti ọ̀kọ̀ dání. 35  Lára àwọn ọmọ Dánì, àwọn tó ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ fún ogun jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (28,600). 36  Lára Áṣérì, àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ogun láti máa jáde lọ́wọ̀ọ̀wọ́ fún ogun jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì (40,000). 37  Láti òdìkejì Jọ́dánì,+ lára àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọmọ ogun ló wà, tí wọ́n ní oríṣiríṣi àwọn ohun ìjà tí wọ́n fi ń jagun. 38  Gbogbo wọn jẹ́ ọkùnrin ogun, tí wọ́n jọ máa ń kóra jọ sojú ogun; gbogbo ọkàn ni wọ́n fi wá sí Hébúrónì láti fi Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, bákan náà, gbogbo ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló fohùn ṣọ̀kan pé àwọn máa* fi Dáfídì jọba.+ 39  Wọ́n fi ọjọ́ mẹ́ta wà níbẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu, nítorí àwọn arákùnrin wọn ti pèsè nǹkan sílẹ̀ dè wọ́n. 40  Bákan náà, àwọn tó wà nítòsí wọn, títí kan àwọn tó wà ní ilẹ̀ Ísákà, Sébúlúnì àti Náfútálì fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí, ìbaaka àti màlúù gbé oúnjẹ wá, ìyẹn àwọn ohun tí wọ́n fi ìyẹ̀fun ṣe, ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ àti ìṣù àjàrà gbígbẹ, wáìnì, òróró àti màlúù pẹ̀lú àgùntàn tó pọ̀ gan-an, torí pé ìdùnnú ṣubú layọ̀ ní Ísírẹ́lì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Ọrun.”
Ní Héb., “ẹ̀mí wọ Ámásáì láṣọ.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Tàbí “gbogbo àwọn tó dara pọ̀ mọ́ Dáfídì ni kì í ṣe ọlọ́kàn méjì.”
Ní Héb., “ni ọkàn wọn ṣọ̀kan láti.”