Kíróníkà Kìíní 13:1-14

  • Wọ́n gbé Àpótí wá láti Kiriati-jéárímù (1-14)

    • Ọlọ́run pa Úsà (9, 10)

13  Dáfídì fọ̀rọ̀ lọ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún pẹ̀lú gbogbo àwọn aṣáájú.+  Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì pé: “Tí ó bá dára lójú yín tí Jèhófà Ọlọ́run wa sì fọwọ́ sí i, ẹ jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin wa tó kù ní gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì àti sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú+ wọn pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko wọn, kí wọ́n lè wá dara pọ̀ mọ́ wa.  Kí a sì gbé Àpótí+ Ọlọ́run wa pa dà.” Nítorí wọn kò bójú tó o nígbà ayé Sọ́ọ̀lù.+  Gbogbo ìjọ náà fara mọ́ ọn pé àwọn á ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó tọ́ lójú gbogbo àwọn èèyàn náà.  Torí náà, Dáfídì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ láti odò* Íjíbítì títí dé Lebo-hámátì,*+ kí wọ́n lè gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù.+  Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì lọ sí Báálà,+ sí Kiriati-jéárímù ti Júdà, kí wọ́n lè gbé Àpótí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ wá láti ibẹ̀, ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù,+ ibi tí a ti ń ké pe orúkọ rẹ̀.  Àmọ́, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun,+ wọ́n gbé e wá láti ilé Ábínádábù. Úsà àti Áhíò sì ń darí kẹ̀kẹ́ náà.+  Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Ọlọ́run tòótọ́ tọkàntara pẹ̀lú orin, háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì+ àti síńbálì*+ pẹ̀lú kàkàkí.+  Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Kídónì, Úsà na ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá Àpótí náà mú, torí màlúù náà mú kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú dé. 10  Ni ìbínú Jèhófà bá ru sí Úsà, Ó pa á nítorí pé ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá Àpótí+ náà mú, torí náà, ó kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.+ 11  Àmọ́ inú bí Dáfídì* nítorí pé ìbínú Jèhófà ru sí Úsà; wọ́n sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà* títí di òní yìí. 12  Torí náà, ẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ ba Dáfídì ní ọjọ́ yẹn, ó sì sọ pé: “Ṣé ọ̀dọ̀ mi ló yẹ kí n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá?”+ 13  Dáfídì kò gbé Àpótí náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì, àmọ́ ó ní kí wọ́n gbé e lọ sí ilé Obedi-édómù ará Gátì. 14  Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sì wà ní agbo ilé Obedi-édómù, oṣù mẹ́ta ló fi wà ní ilé rẹ̀, Jèhófà sì ń bù kún agbo ilé Obedi-édómù àti gbogbo ohun tó ní.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “láti Ṣíhórì.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”
Tàbí “aro.”
Tàbí “inú Dáfídì bà jẹ́.”
Ó túmọ̀ sí “Ìbínú Ru sí Úsà.”