Kíróníkà Kìíní 15:1-29

  • Àwọn ọmọ Léfì gbé Àpótí lọ sí Jerúsálẹ́mù (1-29)

    • Míkálì pẹ̀gàn Dáfídì (29)

15  Dáfídì ń kọ́ àwọn ilé fún ara rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì, ó ṣètò ibì kan fún Àpótí Ọlọ́run tòótọ́, ó sì pa àgọ́ fún un.+  Ìgbà náà ni Dáfídì sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àfi àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ni Jèhófà yàn láti máa gbé Àpótí Jèhófà àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun nígbà gbogbo.”+  Lẹ́yìn náà, Dáfídì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ sí Jerúsálẹ́mù láti gbé Àpótí Jèhófà wá sí ibi tí ó ti ṣètò sílẹ̀ fún un.+  Dáfídì kó àtọmọdọ́mọ Áárónì+ àti ti Léfì+ jọ:  látinú àwọn ọmọ Kóhátì, Úríélì ni olórí àti ọgọ́fà (120) àwọn arákùnrin rẹ̀;  látinú àwọn ọmọ Mérárì, Ásáyà+ ni olórí àti igba ó lé ogun (220) àwọn arákùnrin rẹ̀;  látinú àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù, Jóẹ́lì+ ni olórí àti àádóje (130) àwọn arákùnrin rẹ̀;  látinú àwọn ọmọ Élísáfánì,+ Ṣemáyà ni olórí àti igba (200) àwọn arákùnrin rẹ̀;  látinú àwọn ọmọ Hébúrónì, Élíélì ni olórí àti ọgọ́rin (80) àwọn arákùnrin rẹ̀; 10  látinú àwọn ọmọ Úsíélì,+ Ámínádábù ni olórí àti àádọ́fà ó lé méjì (112) àwọn arákùnrin rẹ̀. 11  Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì pe àlùfáà Sádókù+ àti àlùfáà Ábíátárì+ àti àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn Úríélì, Ásáyà, Jóẹ́lì, Ṣemáyà, Élíélì àti Ámínádábù, 12  ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni olórí agbo ilé àwọn ọmọ Léfì. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín, kí ẹ sì gbé Àpótí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá sí ibi tí mo ti ṣètò sílẹ̀ fún un. 13  Nítorí ẹ̀yin kọ́ lẹ gbé e nígbà àkọ́kọ́+ ni ìbínú Jèhófà Ọlọ́run ṣe ru sí wa,+ torí pé a ò wádìí bó ṣe yẹ ká gbé e.”+ 14  Nítorí náà, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé Àpótí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá. 15  Nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ọ̀pá+ gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ lé èjìká wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Mósè pa látọ̀dọ̀ Jèhófà. 16  Dáfídì wá sọ fún àwọn olórí ọmọ Léfì pé kí wọ́n yan àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ akọrin láti máa fi ayọ̀ kọrin, kí wọ́n máa lo àwọn ohun ìkọrin, ìyẹn àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ pẹ̀lú síńbálì.*+ 17  Torí náà, àwọn ọmọ Léfì yan Hémánì+ ọmọ Jóẹ́lì, lára àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n yan Ásáfù+ ọmọ Berekáyà, lára àwọn ọmọ Mérárì tí wọ́n jẹ́ arákùnrin wọn, wọ́n yan Étánì+ ọmọ Kuṣáyà. 18  Àwọn arákùnrin wọn tó wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n jẹ́ àwùjọ kejì+ ni: Sekaráyà, Bẹ́nì, Jáásíẹ́lì, Ṣẹ́mírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíábù, Bẹnáyà, Maaseáyà, Matitáyà, Élíféléhù, Mikinéáyà pẹ̀lú Obedi-édómù àti Jéélì tí wọ́n jẹ́ aṣọ́bodè. 19  Hémánì,+ Ásáfù+ àti Étánì tí wọ́n jẹ́ akọrin ni wọ́n á máa fi síńbálì bàbà+ kọrin; 20  Sekaráyà, Ásíẹ́lì, Ṣẹ́mírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíábù, Maaseáyà àti Bẹnáyà ni wọ́n ń ta ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín tó ń dún bí Álámótì.*+ 21  Matitáyà,+ Élíféléhù, Mikinéáyà, Obedi-édómù, Jéélì àti Asasáyà ń ta háàpù tó ń dún bíi Ṣẹ́mínítì,*+ àwọn ni olùdarí. 22  Kenanáyà+ olórí àwọn ọmọ Léfì ló ń bójú tó gbígbé ẹrù, torí pé ọ̀jáfáfá ni, 23  Berekáyà àti Ẹlikénà ni aṣọ́bodè tó ń ṣọ́ Àpótí. 24  Àwọn àlùfáà, ìyẹn Ṣebanáyà, Jóṣáfátì, Nétánélì, Ámásáì, Sekaráyà, Bẹnáyà àti Élíésérì ń fun kàkàkí kíkankíkan níwájú Àpótí Ọlọ́run tòótọ́,+ Obedi-édómù àti Jeháyà sì ni aṣọ́bodè tó ń ṣọ́ Àpótí. 25  Nígbà náà, Dáfídì àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún jọ ń rìn lọ tayọ̀tayọ̀+ láti gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà wá láti ilé Obedi-édómù.+ 26  Torí pé Ọlọ́run tòótọ́ ran àwọn ọmọ Léfì tó ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà lọ́wọ́, wọ́n fi akọ ọmọ màlúù méje àti àgbò méje+ rúbọ. 27  Dáfídì wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí wọ́n fi aṣọ àtàtà ṣe, bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó gbé Àpótí náà ṣe múra, àwọn akọrin àti Kenanáyà olórí tó ń bójú tó gbígbé ẹ̀rù àti àwọn tó ń kọrin; Dáfídì sì tún wọ éfódì+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀* ṣe. 28  Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà bọ̀ pẹ̀lú igbe ayọ̀+ àti pẹ̀lú ìró ìwo àti kàkàkí+ pẹ̀lú síńbálì, wọ́n sì ń fi àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ kọrin sókè. 29  Àmọ́ nígbà tí àpótí májẹ̀mú Jèhófà wọ Ìlú Dáfídì,+ Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, bojú wolẹ̀ lójú fèrèsé,* ó rí Ọba Dáfídì tó ń jó sọ́tùn-ún sósì, tó sì ń ṣayẹyẹ; ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í pẹ̀gàn rẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aro.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “wíńdò.”