Kíróníkà Kìíní 18:1-17

  • Àwọn tí Dáfídì ṣẹ́gun (1-13)

  • Ìjọba Dáfídì (14-17)

18  Nígbà tó yá, Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Filísínì, ó borí wọn, Dáfídì sì gba Gátì+ àti àwọn àrọko* rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì.+  Lẹ́yìn náà, Dáfídì ṣẹ́gun Móábù,+ àwọn ọmọ Móábù wá di ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀*+ wá.  Dáfídì ṣẹ́gun Hadadésà+ ọba Sóbà+ nítòsí Hámátì,+ bí ó ṣe ń lọ fìdí àkóso rẹ̀ múlẹ̀ ní odò Yúfírétì.+  Dáfídì gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) agẹṣin àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn lọ́wọ́ rẹ̀.+ Dáfídì sì já iṣan ẹsẹ̀* gbogbo àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun, àmọ́ ó dá ọgọ́rùn-ún (100) lára àwọn ẹṣin náà sí.+  Nígbà tí àwọn ará Síríà tó wà ní Damásíkù wá ran Hadadésà ọba Sóbà lọ́wọ́, Dáfídì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn ará Síríà náà.+  Lẹ́yìn náà, Dáfídì fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Damásíkù ní Síríà, àwọn ará Síríà wá di ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá. Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+  Láfikún sí i, Dáfídì gba àwọn apata* wúrà tó wà lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà, ó sì kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù.  Dáfídì kó bàbà tó pọ̀ gan-an láti Tíbátì àti Kúnì, àwọn ìlú Hadadésà. Òun ni Sólómọ́nì fi ṣe Òkun bàbà+ àti àwọn òpó pẹ̀lú àwọn nǹkan èlò bàbà.+  Nígbà tí Tóù ọba Hámátì gbọ́ pé Dáfídì ti ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadésà+ ọba Sóbà,+ 10  lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán Hádórámù ọmọkùnrin rẹ̀ sí Ọba Dáfídì pé kí ó lọ béèrè àlàáfíà rẹ̀, kí ó sì bá a yọ̀ torí pé ó ti bá Hadadésà jà, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ (nítorí Hadadésà ti máa ń bá Tóù jà tẹ́lẹ̀), ó sì kó oríṣiríṣi ohun èlò wúrà, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò bàbà wá. 11  Ọba Dáfídì yà wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà+ pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tó kó lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí: láti Édómù àti Móábù, látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ àwọn Filísínì+ àti àwọn ọmọ Ámálékì.+ 12  Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà + pa ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lára àwọn ọmọ Édómù ní Àfonífojì Iyọ̀.+ 13  Ó fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Édómù, gbogbo àwọn ọmọ Édómù sì di ìránṣẹ́ Dáfídì.+ Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+ 14  Dáfídì ń jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ ó ń dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì ń ṣe òdodo sí gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+ 15  Jóábù ọmọ Seruáyà ni olórí àwọn ọmọ ogun,+ Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí, 16  Sádókù ọmọ Áhítúbù àti Áhímélékì ọmọ Ábíátárì ni àlùfáà, Ṣáfúṣà sì ni akọ̀wé. 17  Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà ni olórí àwọn Kérétì+ àti àwọn Pẹ́lẹ́tì.+ Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì ló sì wà ní ipò iwájú lẹ́yìn ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “pátì.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “gba Dáfídì là.”
Tàbí “apata ribiti.”
Tàbí “gba Dáfídì là.”